Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 32:1-42

32  Wàyí o, àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Gádì+ wá ní ohun ọ̀sìn tí ó pọ̀ níye, tí ó pọ̀ gidigidi, ní ti tòótọ́. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ilẹ̀ Jásérì+ àti ilẹ̀ Gílíádì, sì wò ó! ibẹ̀ jẹ́ ibì kan fún ohun ọ̀sìn.  Fún ìdí yìí, àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti fún àwọn ìjòyè àpéjọ pé:  “Átárótì+ àti Díbónì+ àti Jásérì àti Nímírà+ àti Hẹ́ṣíbónì+ àti Éléálè+ àti Sébámù àti Nébò+ àti Béónì,+  ilẹ̀ tí Jèhófà ṣẹ́gun+ níwájú àpéjọ Ísírẹ́lì, jẹ́ ilẹ̀ fún ohun ọ̀sìn, àwọn ìránṣẹ́ rẹ sì ní ohun ọ̀sìn.”+  Wọ́n sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Bí a bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí a fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ láti fi ṣe ohun ìní. Má ṣe mú kí a sọdá Jọ́dánì.”+  Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì pé: “Àwọn arákùnrin yín yóò ha lọ sí ogun nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín yóò máa gbé níhìn-ín?+  Èé sì ti ṣe tí ẹ fi ní láti sọ ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì domi ní sísọda sí ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fi fún wọn dájúdájú?  Bí àwọn baba yín ti ṣe+ nìyẹn nígbà tí mo rán wọn láti Kadeṣi-báníà+ láti lọ wo ilẹ̀ náà.  Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Éṣíkólì,+ tí wọ́n sì rí ilẹ̀ náà, nígbà náà ni wọ́n sọ ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì domi, kí wọ́n má bàa lọ sí ilẹ̀ tí Jèhófà yóò fi fún wọn dájúdájú.+ 10  Nítorí náà, ìbínú Jèhófà ru ní ọjọ́ náà tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi búra,+ pé, 11  ‘Àwọn ọkùnrin náà tí ó gòkè wá láti Íjíbítì láti ẹni ogún ọdún sókè+ kì yóò rí ilẹ̀ tí mo búra fún Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù,+ nítorí pé wọn kò tọ̀ mí lẹ́yìn ní kíkún, 12  àyàfi Kálébù+ ọmọkùnrin Jéfúnè ọmọ Kénásì àti Jóṣúà+ ọmọkùnrin Núnì, nítorí pé wọ́n tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún.’ 13  Nítorí náà, ìbínú Jèhófà ru sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí wọ́n rìn káàkiri ní aginjù fún ogójì ọdún,+ títí gbogbo ìran náà tí ń ṣe ibi ní ojú Jèhófà fi wá sí òpin wọn.+ 14  Sì kíyè sí i, ẹ ti dìde ní ipò àwọn baba yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ìran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kí ẹ lè tún fi kún ìbínú jíjófòfò Jèhófà+ sí Ísírẹ́lì. 15  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ yí padà kúrò ní títọ̀ ọ́ lẹ́yìn,+ dájúdájú, òun pẹ̀lú yóò tún jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ dúró pẹ́ ní aginjù,+ ẹ̀yin ì bá sì ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun sí gbogbo àwọn ènìyàn yìí.”+ 16  Lẹ́yìn náà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí pé: “Jẹ́ kí a kọ́ àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe síhìn-ín fún ohun ọ̀sìn wa àti àwọn ìlú ńlá fún àwọn ọmọ wa kéékèèké. 17  Ṣùgbọ́n àwa funra wa yóò lọ pẹ̀lú ìgbáradì ní títẹ́gun+ níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí di ìgbàkigbà tí a bá mú wọn wá sí àyè wọn, nígbà tí àwọn ọmọ wa kéékèèké yóò máa gbé nínú àwọn ìlú ńlá tí ó ní odi kúrò ní ojú àwọn olùgbé ilẹ̀ náà. 18  Àwa kì yóò padà sí ilé wa títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi pèsè ilẹ̀ ìní fún ara wọn, ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ogún tirẹ̀.+ 19  Nítorí a kì yóò gba ogún pẹ̀lú wọn láti ìhà Jọ́dánì àti ní ìkọjá rẹ̀, nítorí pé ogún tiwa ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní ìhà Jọ́dánì níhà yíyọ oòrùn.”+ 20  Látàrí èyí, Mósè wí fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣe ohun yìí, bí ẹ̀yin yóò bá gbára dì níwájú Jèhófà fún ogun+ náà, 21  bí gbogbo àwọn tí wọ́n gbára dì nínú yín yóò bá sì ré Jọ́dánì kọjá níwájú Jèhófà ní ti tòótọ́, títí yóò fi lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ kúrò níwájú rẹ̀,+ 22  tí a sì tẹ ilẹ̀ náà lórí ba níwájú Jèhófà+ ní ti tòótọ́, tí ẹ sì padà lẹ́yìn ìgbà náà,+ ẹ̀yin pẹ̀lú yóò fi ara yín hàn pé ẹ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi sí Jèhófà àti sí Ísírẹ́lì ní tòótọ́; ilẹ̀ yìí yóò sì di tiyín láti fi ṣe ohun ìní níwájú Jèhófà.+ 23  Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣe báyìí, dájúdájú, ẹ̀yin pẹ̀lú yóò dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà.+ Bí ọ̀ran bá rí bẹ́ẹ̀ kí ẹ mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ yín yóò lé yín bá.+ 24  Ẹ kọ́ àwọn ìlú ńlá fún ara yín fún àwọn ọmọ yín kéékèèké àti ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe fún agbo ẹran yín, ohun tí ó ti jáde ní ẹnu yín sì ni kí ẹ ṣe.”+ 25  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sọ èyí fún Mósè: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí olúwa mi ti pa láṣẹ.+ 26  Àwọn ọmọ wa kéékèèké, àwọn aya wa, àwọn ohun ọ̀sìn wa àti gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ wa yóò máa wà níbẹ̀ nínú àwọn ìlú ńlá Gílíádì,+ 27  ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ rẹ yóò ré kọjá, olúkúlùkù ní ìgbáradì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ níwájú Jèhófà fún ogun náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí olúwa mi ti sọ.” 28  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè pa àṣẹ nípa wọn fún Élíásárì àlùfáà àti fún Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì àti fún àwọn olórí àwọn baba ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 29  Nítorí náà, Mósè wí fún wọn pé: “Bí àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì bá ré Jọ́dánì kọjá pẹ̀lú yín, olúkúlùkù ní ìgbáradì fún ogun,+ níwájú Jèhófà, tí a sì tẹ ilẹ̀ náà lórí ba níwájú yín ní ti tòótọ́, nígbà náà, kí ẹ fún wọn ní ilẹ̀ Gílíádì láti fi ṣe ohun ìní.+ 30  Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ré kọjá pẹ̀lú yín ní ìgbáradì, nígbà náà, kí a mú wọn tẹ̀ dó láàárín yín ní ilẹ̀ Kénáánì.”+ 31  Àwọn ọmọ Gádì àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì dáhùn, pé: “Ohun tí Jèhófà ti sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ni bí àwa yóò ti ṣe.+ 32  Àwa fúnra wa yóò ré kọjá ní ìgbáradì níwájú Jèhófà lọ sí ilẹ̀ Kénáánì,+ ohun ìní ti ogún wa yóò sì wà pẹ̀lú wa ní ìhà ìhín Jọ́dánì.”+ 33  Látàrí èyí, Mósè fún wọn, èyíinì ni, àwọn ọmọ Gádì+ àti àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ ọmọkùnrin Jósẹ́fù ní ìjọba Síhónì+ ọba àwọn Ámórì àti ìjọba Ógù+ ọba Báṣánì, ilẹ̀ tí ó jẹ ti àwọn ìlú ńlá rẹ̀ ní àwọn ìpínlẹ̀ náà, àti àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ náà yíká-yíká. 34  Àwọn ọmọ Gádì sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ Díbónì+ àti Átárótì+ àti Áróérì,+ 35  àti Atiroti-ṣófánì àti Jásérì+ àti Jógíbéhà,+ 36  àti Bẹti-nímírà+ àti Bẹti-háránì,+ àwọn ìlú ńlá tí ó ní odi,+ àti àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta+ ṣe. 37  Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì kọ́ Hẹ́ṣíbónì+ àti Éléálè+ àti Kíríátáímù,+ 38  àti Nébò+ àti Baali-méónì+—orúkọ wọn ni a yí padà—àti Síbúmà; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi orúkọ ara wọn pe orúkọ àwọn ìlú ńlá náà tí wọ́n kọ́. 39  Àwọn ọmọ Mákírù+ ọmọkùnrin Mánásè sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí Gílíádì, wọ́n sì gbà á, wọ́n sì lé àwọn Ámórì tí wọ́n wà nínú rẹ̀ lọ. 40  Nítorí náà, Mósè fi Gílíádì fún Mákírù ọmọkùnrin Mánásè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú rẹ̀.+ 41  Jáírì ọmọkùnrin Mánásè sì lọ, ó sì gba àwọn abúlé àgọ́ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pè wọ́n ní Hafotu-jáírì.+ 42  Nóbà sì lọ, ó sì gba Kénátì+ àti àwọn àrọko rẹ̀; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi Nóbà orúkọ ara rẹ̀ pè é.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé