Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 31:1-54

31  Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ lẹ́yìn náà, pé:  “Gbẹ̀san+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára àwọn ọmọ Mídíánì.+ Lẹ́yìn ìgbà náà, a óò kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”+  Nítorí náà, Mósè bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀, pé: “Ẹ mú kí àwọn ọkùnrin nínú yín gbára dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun, kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ láti gbéjà ko Mídíánì láti mú ẹ̀san Jèhófà ṣẹ ní kíkún lórí Mídíánì.+  Ẹgbẹ̀rún kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì ni kí ẹ rán lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà.”  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, láti inú ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ Ísírẹ́lì, ẹgbẹ̀rún ni a yàn nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, ẹgbẹ̀rún méjì lá ni a mú gbára dì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ náà.  Lẹ́yìn náà, Mósè rán wọn jáde, ẹgbẹ̀rún nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà, àwọn àti Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì àlùfáà sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà, àwọn nǹkan èlò mímọ́ àti àwọn kàkàkí+ fún fífun ipè sì wà ní ọwọ́ rẹ̀.  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sì bá Mídíánì jagun, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pa olúkúlùkù ọkùnrin.+  Wọ́n sì pa àwọn ọba Mídíánì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn tí a pa, èyíinì ni, Éfì àti Rékémù àti Súúrì àti Húrì àti Rébà, àwọn ọba Mídíánì márùn-ún;+ wọ́n sì fi idà pa Báláámù+ ọmọkùnrin Béórì.  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn obìnrin Mídíánì àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ ní òǹdè;+ gbogbo ẹran agbéléjẹ̀ wọn àti gbogbo ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn ni wọ́n sì piyẹ́. 10  Gbogbo àwọn ìlú ńlá wọn nínú èyí tí wọ́n tẹ̀ dó sí àti gbogbo ibùdó wọn tí a mọ ògiri yí ká ni wọ́n sì fi iná sun.+ 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kó gbogbo ohun ìfiṣèjẹ+ àti gbogbo ẹrù àkótogunbọ̀ tí ó jẹ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀. 12  Wọ́n sì kó àwọn òǹdè àti ẹrù àkótogunbọ̀ àti ohun ìfiṣèjẹ náà wá sọ́dọ̀ Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti sọ́dọ̀ àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, sí ibùdó, sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù,+ tí wọ́n wà lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò. 13  Nígbà náà ni Mósè àti Élíásárì àlùfáà àti gbogbo àwọn ìjòyè àpéjọ jáde lọ pàdé wọn ní òde ibùdó. 14  Ìkannú Mósè sì ru sí àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò nínú àwọn agbóguntini+ náà, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí wọ́n ń wọlé bọ̀ láti àkànṣe ìrìn àjò ológun náà. 15  Nítorí náà, Mósè wí fún wọn pé: “Ẹ̀yín ha ti pa gbogbo obìnrin mọ́ láàyè?+ 16  Wò ó! Àwọn ni ẹni tí ó ṣiṣẹ́, nípa ọ̀rọ̀ Báláámù, láti sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà àìṣòótọ́+ sí Jèhófà lórí àlámọ̀rí Péórù,+ tí òjòjò àrànkálẹ̀ fi wá sórí àpéjọ Jèhófà.+ 17  Nísinsìnyí, ẹ pa gbogbo akọ lára àwọn ọmọ kéékèèké, kí ẹ sì pa gbogbo obìnrin tí ó ti ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin nípa sísùn ti ọkùnrin.+ 18  Gbogbo àwọn ọmọ kéékèèké lára àwọn obìnrin náà tí kò tíì mọ̀ nípa sísùn ti akọ+ sì ni kí ẹ pa mọ́ láàyè fún ara yín. 19  Ní ti ẹ̀yin fúnra yín, ẹ dó sí òde ibùdó fún ọjọ́ méje. Gbogbo ẹni tí ó ti pa ọkàn+ kan àti gbogbo ẹni tí ó ti fọwọ́ kan ẹnì kan tí a pa,+ kí ẹ wẹ ara yín mọ́ gaara+ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje, ẹ̀yin àti àwọn òǹdè yín. 20  Gbogbo ẹ̀wù àti gbogbo ohun èlò awọ ara àti ohun gbogbo tí a fi irun ewúrẹ́ ṣe àti gbogbo ohun èlò igi ni kí ẹ sì wẹ̀ mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀+ fún ara yín.” 21  Nígbà náà ni Élíásárì àlùfáà wí fún àwọn ọkùnrin ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí wọ́n lọ sínú ìjà ogun náà pé: “Èyí ni ìlànà àgbékalẹ̀ tí í ṣe ti òfin tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè, 22  ‘Kì kì wúrà àti fàdákà, bàbà, irin, tánganran àti òjé, 23  ohun gbogbo tí a fi iná sun,+ ni kí ẹ fi la iná kọjá, kí ó sì mọ́. Kì kì pé a ní láti fi omi ìwẹ̀nùmọ́+ wẹ̀ ẹ́ mọ́ gaara. Ohun gbogbo tí a kò sì fi iná sun ni kí ẹ fi la omi+ kọjá. 24  Kí ẹ sì fọ àwọn ẹ̀wù yín ní ọjọ́ keje, kí ẹ sì mọ́, lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ lè wá sínú ibùdó.’”+ 25  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ èyí fún Mósè pé: 26  “Ka iye ẹrù àkótogunbọ̀, àwọn òǹdè tí wọ́n jẹ́ ìran ènìyàn àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀, ìwọ àti Élíásárì àlùfáà àti àwọn olórí àwọn baba àpéjọ. 27  Kí o sì pín ẹrù àkótogunbọ̀ náà sí méjì láàárín àwọn tí wọ́n kópa nínú ìjà ogun náà, tí wọ́n jáde lọ nínú àkànṣe ìrìn àjò náà àti gbogbo ìyókù àpéjọ.+ 28  Gẹ́gẹ́ bí owó orí+ fún Jèhófà, kí o sì mú láti inú àwọn ọkùnrin ogun tí wọ́n jáde lọ nínú àkànṣe ìrìn àjò náà ọkàn kan lára ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, lára ìran ènìyàn àti lára ọ̀wọ́ ẹran àti lára àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti lára agbo ẹran. 29  Láti inú ààbọ̀ wọn ni kí ẹ ti mú un, kí o sì fi í fún Élíásárì àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà.+ 30  Láti inú ààbọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kí o sì ti mú ọ̀kan nínú àádọ́ta, lára ìran ènìyàn, lára ọ̀wọ́ ẹran, lára àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti lára agbo ẹran, lára gbogbo onírúurú ẹran agbéléjẹ̀, kí o sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn olùpa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà mọ́.” 31  Mósè àti Élíásárì àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 32  Ẹrù àkótogunbọ̀ náà, ìyókù ohun tí a piyẹ́ tí àwọn ènìyàn tí ó lọ sí àkànṣe ìrìn àjò náà ti kó gẹ́gẹ́ bí ohun ìpiyẹ́, sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ agbo ẹran, 33  àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta àti ẹgbàáfà ọ̀wọ́ ẹran, 34  àti ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 35  Ní ti ọkàn+ ẹ̀dá ènìyàn láti inú àwọn obìnrin tí kò tíì mọ̀ nípa sísùn ti ọkùnrin,+ gbogbo ọkàn náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàáfà. 36  Ààbọ̀ tí ó sì jẹ́ ìpín àwọn tí wọ́n jáde lọ nínú àkànṣe ìrìn àjò náà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dégbèjì -dín-láàádọ́rùn-ún agbo ẹran ní iye. 37  Owó orí+ fún Jèhófà láti inú agbo ẹran náà sì jẹ́ ọ̀rìn-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún. 38  Ẹgbàá méjì dínlógún sì ni ó wà láti inú ọ̀wọ́ ẹran, owó orí lórí wọn fún Jèhófà sì jẹ́ méjì -lé-láàádọ́rin. 39  Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, owó orí lórí wọn fún Jèhófà sì jẹ́ mọ́kàn-lé-lọ́gọ́ta. 40  Ọkàn tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún, owó orí lórí wọn fún Jèhófà sì jẹ́ ọkàn méjì lélọ́gbọ̀n. 41  Nígbà náà ni Mósè fún Élíásárì àlùfáà+ ní owó orí náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+ 42  Láti inú ààbọ̀ tí ó sì jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí Mósè pín láti inú èyí tí ó jẹ́ ti àwọn ọkùnrin náà tí ó ja ogun: 43  Wàyí o, ààbọ̀ àpéjọ láti ara agbo ẹran jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dégbèjì -dín-láàádọ́rùn-ún, 44  àti lára ọ̀wọ́ ẹran, ẹgbàá méjì dínlógún, 45  àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta, 46  àti ọkàn ẹ̀dá ènìyàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún. 47  Nígbà náà ni Mósè mú láti inú ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì èyí tí a óò mú kúrò nínú àádọ́ta, lára ìran ènìyàn àti lára àwọn ẹran agbéléjẹ̀, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn olùpa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ àgọ́ ìjọsìn Jèhófà mọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 48  Àwọn ọkùnrin tí a yàn sípò tí wọ́n jẹ́ ara àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún,+ sì tẹ̀ síwájú láti tọ Mósè wá, 49  wọ́n sì wí fún Mósè pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ti ka iye àwọn ọkùnrin ogun tí ó wà lábẹ́ àbójútó wa, kò sì sí ọ̀kan nínú wa tí a ròyìn pé ó sọnù.+ 50  Nítorí náà, jẹ́ kí olúkúlùkù wa mú ohun tí ó ti rí wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ+ Jèhófà, àwọn ohun èlò wúrà, ẹ̀gbà ọrùn ẹsẹ̀, àti àwọn júfù, òrùka àmì àṣẹ,+ yẹtí, àti àwọn ohun tí obìnrin fi ń ṣe ọ̀ṣọ́,+ kí a lè ṣe ètùtù fún ọkàn wa níwájú Jèhófà.” 51  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà ní ọwọ́ wọn,+ gbogbo ohun tí a fi ń ṣe ọ̀ṣọ́. 52  Gbogbo wúrà ọrẹ tí wọ́n fi ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rìn-lé-lẹ́gbàáàjọ ó lé àádọ́ta ṣékélì, láti ọwọ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti àwọn olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún. 53  Olúkúlùkù àwọn ọkùnrin ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti piyẹ́ fún ara rẹ̀.+ 54  Nítorí náà, Mósè àti Élíásárì àlùfáà gba wúrà náà ní ọwọ́ àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún, wọ́n sì mú un wá sínú àgọ́ ìpàdé gẹ́gẹ́ bí ìrántí+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú Jèhófà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé