Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 30:1-16

30  Lẹ́yìn náà, Mósè bá àwọn olórí+ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé: “Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà pa láṣẹ:  Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan jẹ́ ẹ̀jẹ́+ fún Jèhófà tàbí tí ó ṣe ìbúra+ kan láti fi ẹ̀jẹ́ ìtakété+ de ọkàn ara rẹ̀, kí ó má ṣẹ̀ sí ọ̀rọ̀+ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó jáde ní ẹnu rẹ̀ ni kí ó ṣe.+  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé obìnrin kan jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà+ tàbí tí ó fi ẹ̀jẹ́ ìtakété de ara rẹ̀ ní ilé baba rẹ̀ ní ìgbà èwe rẹ̀,  tí baba rẹ̀ ní ti tòótọ́ sì gbọ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí ẹ̀jẹ́ ìtakété+ rẹ̀ tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀, tí baba rẹ̀ sì dákẹ́ sí i, kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ dúró pẹ̀lú, gbogbo ẹ̀jẹ́ ìtakété tí ó fi de ọkàn ara rẹ̀ yóò sì dúró.  Ṣùgbọ́n bí baba rẹ̀ bá ti kà á léèwọ̀ ní ọjọ́ tí ó gbọ́ gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí àwọn ẹ̀jẹ́ ìtakété rẹ̀ tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀, kì yóò dúró, ṣùgbọ́n Jèhófà yóò dárí jì  í, nítorí pé baba rẹ̀ kà á léèwọ̀ fún un.+  “Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ba lọ jẹ́ ẹni tí ó lọ́kọ, tí ẹ̀jẹ́ rẹ̀ sì wà lórí rẹ̀+ tàbí ìlérí aláìnírònú láti ètè rẹ̀ tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀,  tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ ọ ní ti tòótọ́, tí ó sì dákẹ́ sí i ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ, kí àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ̀ dúró pẹ̀lú tàbí kí àwọn ẹ̀jẹ́ ìtakété rẹ̀ tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀ kí ó dúró.+  Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kà á léèwọ̀ fún un+ ní ọjọ́ tí ó gbọ́ ọ, òun pẹ̀lú ti wọ́gi lé ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tí ó wà lórí rẹ̀ tàbí ìlérí aláìnírònú ti ètè rẹ̀ tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀, Jèhófà yóò sì dárí jì  í.+  “Nínú ọ̀ràn ẹ̀jẹ́ opó kan tàbí obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀, ohun gbogbo tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀ yóò wà bẹ́ẹ̀ sí i. 10  “Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó bá jẹ́ inú ilé ọkọ rẹ̀ ni ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ tàbí tí ó ti fi ẹ̀jẹ́ ìtakété+ de ọkàn ara rẹ̀ nípasẹ̀ ìbúra, 11  tí ọkọ rẹ̀ sì gbọ́ ọ, tí ó sì dákẹ́ sí i, òun kò kà á léèwọ̀ fún un; kí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ sì dúrò tàbí kí ẹ̀jẹ́ ìtakété èyíkéyìí tí ó ti fi de ọkàn ara rẹ̀ kí ó dúró. 12  Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá wọ́gi lé wọn pátápátá ní ọjọ́ tí ó gbọ́ gbólóhùn ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí ó ti ètè rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ ìtakété ti ọkàn rẹ̀, wọn kì yóò dúró.+ Ọkọ rẹ̀ ti wọ́gi lé wọn, Jèhófà yóò sì dárí jì  í.+ 13  Ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí tàbí ìbúra ẹ̀jẹ́ ìtakété èyíkéyìí láti ṣẹ́ ọkàn+ níṣẹ̀ẹ́, kí ọkọ rẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ tàbí kí ọkọ rẹ̀ wọ́gi lé e. 14  Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá dákẹ́ pátápátá sí i láti ọjọ́ dé ọjọ́, òun pẹ̀lú ti fìdí gbogbo ẹ̀jẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ tàbí gbogbo ẹ̀jẹ́ ìtakété rẹ̀ tí ó wà lórí rẹ̀.+ Ó ti fìdí wọn múlẹ̀ nítorí pé ó dákẹ́ sí i ní ọjọ́ tí ó gbọ́ wọn. 15  Bí ó bá sì wọ́gi lé wọn pátápátá lẹ́yìn tí ó gbọ́ wọn, òun pẹ̀lú yóò ru ìṣìnà+ obìnrin náà ní ti tòótọ́. 16  “Ìwọ̀nyí ni àwọn ìlànà tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ní ti àárín ọkọ àti aya+ rẹ̀, ní ti àárín baba àti ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìgbà èwe rẹ̀ ní ilé baba+ rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé