Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 3:1-51

3  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn ìran Áárónì àti Mósè ní ọjọ́ tí Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní Òkè Ńlá Sínáì.+  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Áárónì: Nádábù àkọ́bí àti Ábíhù,+ Élíásárì+ àti Ítámárì.+  Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà tí a fòróró yàn, tí a ti fi agbára kún ọwọ́ wọn láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.+  Bí ó ti wù kí ó rí, Nádábù àti Ábíhù kú níwájú Jèhófà nígbà tí wọ́n rúbọ iná+ aláìbá-ìlànà-mu níwájú Jèhófà ní aginjù Sínáì; wọn kò sì wá ní ọmọ kankan. Ṣùgbọ́n Élíásárì+ àti Ítámárì+ ń bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà pa pọ̀ pẹ̀lú Áárónì baba wọn.  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Mú ẹ̀yà Léfì+ sún mọ́ tòsí, kí o sì mú wọn dúró níwájú Áárónì àlùfáà, wọn yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́+ fún un.  Kí wọ́n sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mọ́ sí i àti iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn sí gbogbo àpéjọ níwájú àgọ́ ìpàdé ní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn àgọ́ náà.  Kí wọ́n sì bójú tó gbogbo nǹkan èlò+ àgọ́ ìpàdé, àní iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn àgọ́ náà.+  Kí o sì fi àwọn ọmọ Léfì fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Wọ́n jẹ́ àwọn ẹni tí a fi fúnni, tí a fi fún un láti inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 10  Kí o sì yan Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sípò, kí wọ́n sì bójú tó iṣẹ́ àlùfáà wọn;+ àjèjì èyíkéyìí tí ó bá sì sún mọ́ tòsí ni kí a fi ikú pa.”+ 11  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 12  “Ní tèmi, wò ó! èmi mú àwọn ọmọ Léfì láàárín àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì dípò gbogbo àkọ́bí+ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì; àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi. 13  Nítorí olúkúlùkù àkọ́bí jẹ́ tèmi.+ Ọjọ́ tí mo kọlu olúkúlùkù àkọ́bí ní ilẹ̀ Íjíbítì+ ni mo sọ olúkúlùkù àkọ́bí ní Ísírẹ́lì di mímọ́ fún ara mi láti orí ènìyàn títí dórí ẹranko.+ Tèmi ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́. Èmi ni Jèhófà.” 14  Jèhófà sì tún bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì,+ pé: 15  “Forúkọ àwọn ọmọ Léfì sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn nípa ìdílé wọn. Olúkúlùkù ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè ni kí o forúkọ rẹ̀ sílẹ̀.”+ 16  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí forúkọ wọn sílẹ̀ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún un. 17  Ìwọ̀nyí sì wá ni àwọn ọmọkùnrin Léfì+ nípa orúkọ wọn: Gẹ́ṣónì àti Kóhátì àti Mérárì.+ 18  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọkùnrin Gẹ́ṣónì nípa ìdílé wọn: Líbínì àti Ṣíméì.+ 19  Àwọn ọmọkùnrin Kóhátì+ nípa ìdílé wọn sì ni Ámúrámù àti Ísárì,+ Hébúrónì àti Úsíélì. 20  Àwọn ọmọkùnrin Mérárì+ nípa ìdílé wọn sì ni Máhílì+ àti Múṣì.+ Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Léfì ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn. 21  Ti Gẹ́ṣónì ni ìdílé àwọn ọmọ Líbínì+ àti ìdílé àwọn ọmọ Ṣíméì.+ Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì. 22  Àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn jẹ́ nípa iye gbogbo ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè.+ Àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn jẹ́ ẹgbàárin ó dín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 23  Ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì wà lẹ́yìn àgọ́ ìjọsìn.+ Wọ́n dó sí ìwọ̀-oòrùn. 24  Ìjòyè ti ìdí ilé baba fún àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì sì ni Élíásáfù ọmọkùnrin Láélì. 25  Iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe àwọn ọmọkùnrin Gẹ́ṣónì+ ní àgọ́ ìpàdé sì ni àgọ́ ìjọsìn àti àgọ́,+ ìbòrí+ rẹ̀ àti àtabojú+ ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26  àti àwọn àsokọ́+ àgbàlá àti àtabojú+ ẹnu ọ̀nà àgbàlá tí ó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àti àwọn okùn+ àgọ́ rẹ̀, fún gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. 27  Ti Kóhátì sì ni ìdílé àwọn ọmọ Ámúrámù àti ìdílé àwọn ọmọ Ísárì àti ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì àti ìdílé àwọn ọmọ Úsíélì. Ìwọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì.+ 28  Lára iye gbogbo àwọn ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógójì, tí wọ́n ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ibi mímọ́.+ 29  Ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì dó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ ìjọsìn sí gúúsù.+ 30  Ìjòyè ti ìdí ilé baba fún àwọn ìdílé ọmọ Kóhátì sì ni Élísáfánì ọmọkùnrin Úsíélì.+ 31  Iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ wọn sì ni Àpótí+ náà àti tábìlì+ àti ọ̀pá fìtílà+ àti àwọn pẹpẹ+ àti àwọn nǹkan èlò+ ibi mímọ́, èyí tí wọn yóò fi ṣe ìránṣẹ́ àti àtabojú+ náà, àti gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. 32  Ìjòyè fún àwọn ìjòyè ọmọ Léfì sì ni Élíásárì+ ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà, ẹni tí ó ni iṣẹ́ àbójútó àwọn tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ibi mímọ́. 33  Ti Mérárì ni ìdílé àwọn ọmọ Máhílì+ àti ìdílé àwọn ọmọ Múṣì.+ Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Mérárì.+ 34  Àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn ní ìbámu pẹ̀lú iye gbogbo àwọn ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé igba.+ 35  Ìjòyè ti ìdí ilé baba fún àwọn ìdílé Mérárì sì ni Súríélì ọmọkùnrin Ábíháílì. Wọ́n dó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ ìjọsìn síhà àríwá.+ 36  Iṣẹ́ àbójútó tí ó jẹ́ dandan fún àwọn ọmọ Mérárì sì jẹ́ lórí férémù+ àgọ́ ìjọsìn àti àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀ àti àwọn ọwọ̀n+ rẹ̀ àti àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti gbogbo nǹkan èlò+ rẹ̀ àti gbogbo iṣẹ́ ìsìn rẹ̀,+ 37  àti àwọn ọwọ̀n+ àgbàlá yíká-yíká àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀+ wọn àti ìkànlẹ̀ àgọ́ wọn àti okùn àgọ́ wọn. 38  Àwọn tí wọ́n sì dó síwájú àgọ́ ìjọsìn síhà ìlà-oòrùn, níwájú àgọ́ ìpàdé síhà yíyọ oòrùn, ni Mósè àti Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, àwọn tí ń bójú tó iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ibùjọsìn,+ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àjèjì èyíkéyìí tí ó bá sì sún mọ́ tòsí ni a ó fi ikú pa.+ 39  Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì, àwọn tí Mósè àti Áárónì forúkọ wọn sílẹ̀ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípa ìdílé wọn, gbogbo àwọn ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè, jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàá. 40  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Forúkọ gbogbo àwọn àkọ́bí tí ó jẹ́ ọkùnrin sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni oṣù kan sókè,+ kí o sì ka iye orúkọ wọn. 41  Kí o sì mú àwọn ọmọ Léfì fún mi—èmi ni Jèhófà—dípò gbogbo àkọ́bí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí lára àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”+ 42  Mósè sì tẹ̀ síwájú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un, láti forúkọ gbogbo àkọ́bí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀. 43  Gbogbo àwọn àkọ́bí tí ó jẹ́ ọkùnrin nípa iye àwọn orúkọ láti ẹni oṣù kan sókè nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì wá jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlá ó lé ọ̀rìnlérúgba ó dín méje. 44  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 45  “Mú àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ẹran agbéléjẹ̀ àwọn ọmọ Léfì dípò àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn; àwọn ọmọ Léfì yóò sì di tèmi.+ Èmi ni Jèhófà. 46  Àti gẹ́gẹ́ bí iye owó ìràpadà+ ti àádọ́rin-lérúgba ó lé mẹ́ta láti inú àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọ́n fi lé sí àwọn ọmọ Léfì,+ 47  ìwọ yóò gba ṣékélì márùn-ún fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.+ Ṣékélì ibi mímọ́ ni ìwọ yóò fi gbà á. Ṣékélì kan jẹ́ ogún òṣùwọ̀n gérà.+ 48  Ìwọ yóò sì fi owó náà fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye owó ìràpadà àwọn tí ó lé lórí wọn.” 49  Nítorí náà, Mósè gba owó tí ó jẹ́ iye owó ìtúnràpadà lọ́wọ́ àwọn tí ó lé lórí iye owó ìràpadà àwọn ọmọ Léfì. 50  Ọwọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ó ti gba owó náà, egbèje ó dín márùndínlógójì ṣékélì, ní ṣékélì ibi mímọ́. 51  Lẹ́yìn náà, Mósè fi owó náà tí ó jẹ́ iye owó ìràpadà fún Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé