Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 28:1-31

28  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Kí ẹ kíyè sí mímú ọrẹ ẹbọ mi wá fún mi, oúnjẹ+ mi, fún àwọn ọrẹ ẹbọ mi àfinásun gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni sí mi,+ ní àwọn àkókò wọn tí a yàn kalẹ̀.’+  “Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ọrẹ ẹbọ àfinásun tí ẹ óò mú wá fún Jèhófà: akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì  ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+  Akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rúbọ ní òwúrọ̀, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì  ni ìwọ yóò sì fi rúbọ láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́+ méjèèjì ,  pa pọ̀ pẹ̀lú ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà+ ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà+ tí a fi ìlàrin òṣùwọ̀n hínì òróró tí a fún rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́;+  ọrẹ ẹbọ sísun+ ìgbà gbogbo náà, tí a fi rúbọ ní Òkè Ńlá Sínáì gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni, ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà,+  pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀, ìlàrin òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan.+ Da ọrẹ ẹbọ ohun mímu ti ọtí tí ń pani+ náà jáde ní ibi mímọ́ sí Jèhófà.  Ìwọ yóò sì fi akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kejì  rúbọ láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì . Pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ọkà kan náà gẹ́gẹ́ bí ti òwúrọ̀ àti pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀ kan náà ni kí ìwọ fi í rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+  “‘Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọjọ́ sábáàtì+ yóò jẹ́ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì  ọlọ́dún kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá àti ìdá mẹ́wàá méjì  ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀, 10  gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun ti sábáàtì ní sábáàtì rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 11  “‘Àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù yín, ẹ óò mú ẹgbọrọ akọ màlúù méjì  àti àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ara wọn dá ṣáṣá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà, 12  àti ìdá mẹ́wàá mẹ́ta ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà+ tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti ìdá mẹ́wàá méjì  ìyẹ̀fun kíkúnná gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún àgbò,+ 13  àti ìdá mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná ní bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun, òórùn amáratuni,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà. 14  Àti gẹ́gẹ́ bí àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu wọn, kí ìdajì + òṣùwọ̀n hínì wáìnì lọ fún akọ màlúù kan àti ìdá mẹ́ta+ òṣùwọ̀n hínì fún àgbò àti ìlàrin+ òṣùwọ̀n hínì fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kan. Èyí ni ọrẹ ẹbọ sísun oṣooṣù ní oṣù rẹ̀ fún àwọn oṣù inú ọdún.+ 15  Bákan náà, ọmọ ewúrẹ́+ kan ni kí a fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ sí Jèhófà ní àfikún sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 16  “‘Ìrékọjá+ Jèhófà yóò sì jẹ́ ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà. 17  Àjọyọ̀ yóò sì wà ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù yìí. Ọjọ́ méje ni a ó fi jẹ àkàrà aláìwú.+ 18  Àpéjọpọ̀+ mímọ́ yóò wà ní ọjọ́ kìíní. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+ 19  Kí ẹ sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù méjì  àti àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ọrẹ ẹbọ sísun+ sí Jèhófà. Kí wọ́n jẹ́ àwọn tí ara wọ́n dá ṣáṣá+ lójú yín. 20  Ẹ ó sì fi ìdá mẹ́wàá mẹ́ta rúbọ fún akọ màlúù kan àti ìdá mẹ́wàá méjì + rúbọ fún àgbò gẹ́gẹ́ bí àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. 21  Ìwọ yóò fi ìdá mẹ́wàá+ rúbọ ní bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje náà; 22  àti ewúrẹ́ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín.+ 23  Yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun òwúrọ̀, èyí tí ó wà fún ọrẹ ẹbọ sísun+ ìgbà gbogbo,+ ẹ̀yin yóò fi ìwọ̀nyí rúbọ. 24  Lọ́nà kan náà bí ìwọ̀nyí ni ẹ̀yin yóò máa fi rúbọ lójoojúmọ́ fún ọjọ́ méjèèje gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ Pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo ni kí a fi rúbọ, àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀. 25  Àti ní ọjọ́ keje kí ẹ ṣe àpéjọpọ̀+ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+ 26  “‘ Àti ní ọjọ́ àkọ́pọ́n àwọn èso,+ nígbà tí ẹ bá ń mú ọrẹ ẹbọ ọkà tuntun wá fún Jèhófà, ní àsè àwọn ọ̀sẹ̀+ yín ni kí ẹ ṣe àpéjọpọ̀ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+ 27  Kí ẹ sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù méjì , àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun fún òórùn amáratuni sí Jèhófà;+ 28  àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà wọn ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ìdá mẹ́wàá mẹ́ta fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan, ìdá mẹ́wàá méjì + fún àgbò, 29  ìdá mẹ́wàá+ ní bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjèèje náà; 30  ọmọ ewúrẹ́ kan láti ṣe ètùtù fún yín.+ 31  Yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ ni ẹ̀yin yóò fi wọ́n rúbọ.+ Kí wọ́n jẹ́ àwọn tí ara wọ́n dá ṣáṣá lójú yín,+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé