Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 27:1-23

27  Nígbà náà ni àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì+ ọmọkùnrin Héfà ọmọkùnrin Gílíádì ọmọkùnrin Mákírù ọmọkùnrin Mánásè,+ ti àwọn ìdílé Mánásè ọmọkùnrin Jósẹ́fù, sún mọ́ tòsí. Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀: Málà, Nóà àti Hógílà àti Mílíkà àti Tírísà.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dúró níwájú Mósè àti níwájú Élíásárì àlùfáà+ àti níwájú àwọn ìjòyè àti gbogbo àpéjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wí pé:  “Baba wa ti kú ní aginjù,+ síbẹ̀, òun kò sì sí láàárín àpéjọ náà, èyíinì ni, àwọn tí wọ́n to ara wọn gẹ̀ẹ̀rẹ̀ lòdì sí Jèhófà nínú àpéjọ Kórà,+ ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni ó ṣe kú;+ kò sì wá ní ọmọkùnrin kankan.  Èé ṣe tí a ó fi mú orúkọ baba wá kúrò ní àárín ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin?+ Fún wa ní ohun ìní ní àárín àwọn arakúnrin baba wa.”+  Látàrí ìyẹn, Mósè mú ọ̀ràn wọn wá síwájú Jèhófà.+  Nígbà náà ni Jèhófà sọ èyí fún Mósè pé:  “Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ń sọ ohun tí ó tọ́. Lọ́nàkọnà, kí o fún wọn ní ohun ìní ti ogún ní àárín àwọn arákùnrin baba wọn, kí o sì mú kí ogún baba wọn kọjá sọ́dọ̀ wọn.+  Kí o sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin èyíkéyìí kú láìní ọmọkùnrin kankan, nígbà náà, kí ẹ mú kí ogún rẹ̀ kọjá sọ́dọ̀ ọmọbìnrin rẹ̀.  Bí kò bá sì ní ọmọbìnrin, nígbà náà, kí ẹ fi ogún rẹ̀ fún àwọn arakùnrin rẹ̀. 10  Bí kò bá sì ní àwọn arákùnrin, nígbà náà, kí ẹ fi ogún rẹ̀ fún àwọn arakùnrin baba rẹ̀. 11  Bí baba rẹ̀ kò bá sì ní àwọn arákùnrin, nígbà náà, kí ẹ fi ogún rẹ̀ fún ẹbí+ rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọn jù lọ nínú ìdílé rẹ̀, kí ó sì gbà á. Kí ó sì jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ nípa ìpinnu ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.’” 12  Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Gòkè lọ sí òkè ńlá Ábárímù+ yìí, kí o sì rí ilẹ̀ náà tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dájúdájú.+ 13  Nígbà tí o bá ti rí i, nígbà náà ni a óò kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ,+ bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kó Áárónì arákùnrin rẹ jọ,+ 14  níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni mi ní aginjù Síínì nígbà aáwọ̀ àpéjọ+ náà, ní ìsopọ̀ pẹ̀lú sísọ mi di mímọ́+ níbi omi náà lójú wọn. Ìwọ̀nyí ni omi Mẹ́ríbà+ ní Kádéṣì+ ní aginjù Síínì.”+ 15  Nígbà náà ni Mósè bá Jèhófà sọ̀rọ̀, pé: 16  “Kí Jèhófà tí í ṣe Ọlọ́run àwọn ẹ̀mí+ gbogbo onírúurú ẹran ara+ yan ọkùnrin+ kan sípò lórí àpéjọ náà 17  ẹni tí yóò máa jáde lọ níwájú wọn, tí yóò sì máa wọlé níwájú wọn, tí yóò sì máa mú wọn jáde, tí yóò sì máa mú wọn wọlé,+ kí àpéjọ Jèhófà má bàa dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.”+ 18  Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì fún ara rẹ, ọkùnrin kan tí ẹ̀mí+ wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e;+ 19  kí o sì mú un dúró níwájú Élíásárì àlùfáà àti níwájú gbogbo àpéjọ, kí o sì fàṣẹ yàn án lójú wọn.+ 20  Kí o sì mú lára iyì rẹ sára rẹ̀,+ kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa fetí sí i.+ 21  Òun yóò sì máa dúró níwájú Élíásárì àlùfáà, kí ó sì máa wádìí+ nítorí rẹ̀ nípasẹ̀ ìdájọ́ Úrímù+ níwájú Jèhófà. Nípa àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ ni wọn yóò máa jáde lọ, nípa àṣẹ ìtọ́ni rẹ̀ sì ni wọn yóò máa wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀ àti gbogbo àpéjọ.” 22  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó mú Jóṣúà, ó sì mú un dúró níwájú Élíásárì+ àlùfáà àti níwájú gbogbo àpéjọ 23  ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì fàṣẹ yàn án,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà tí sọ nípasẹ̀ Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé