Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 26:1-65

26  Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn òjòjò àrànkálẹ̀+ náà, pé Jèhófà ń bá a lọ láti sọ èyí fún Mósè àti Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà pé:  “Ẹ ka iye gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni ogún ọdún sókè, ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba wọn, gbogbo àwọn tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ísírẹ́lì.”+  Mósè àti Élíásárì+ àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù+ lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò,+ pé:  “[Ẹ ka iye wọn] láti ẹni ogún ọdún sókè, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.”+ Wàyí o, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ni:  Rúbẹ́nì, àkọ́bí+ Ísírẹ́lì; àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì: Ti Hánókù+ ìdílé àwọn ọmọ Hánókù; ti Pálù+ ìdílé àwọn ọmọ Pálù;  ti Hésírónì+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì, ti Kámì+ ìdílé àwọn ọmọ Kámì.  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn tí a sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹgbàajì  ó dín àádọ́rin.+  Ọmọkùnrin Pálù sì ni Élíábù.  Àti àwọn ọmọkùnrin Élíábù: Némúẹ́lì àti Dátánì àti Ábírámù. Dátánì+ àti Ábírámù+ yìí jẹ́ àwọn tí a fi ọlá àṣẹ pè nínú àpéjọ, tí wọ́n bá Mósè àti Áárónì jì jàkadì nínú àpéjọ Kórà,+ nígbà tí wọ́n bá Jèhófà jì jàkadì. 10  Nígbà náà ni ilẹ̀ la ẹnu rẹ̀ tí ó sì gbé wọn mì.+ Ní ti Kórà, ó kú nígbà ikú àpéjọ náà nígbà tí iná jó àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin run.+ Wọ́n sì wá jẹ́ àpẹẹrẹ.+ 11  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Kórà kò kú.+ 12  Àwọn ọmọkùnrin Síméónì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Némúẹ́lì+ ìdílé àwọn ọmọ Némúẹ́lì; ti Jámínì+ ìdílé àwọn ọmọ Jámínì; ti Jákínì+ ìdílé àwọn ọmọ Jákínì; 13  ti Síírà ìdílé àwọn ọmọ Síírà; ti Ṣọ́ọ̀lù+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù. 14  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Síméónì: ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbọ̀kànlá.+ 15  Àwọn ọmọkùnrin Gádì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Séfónì ìdílé àwọn ọmọ Séfónì; ti Hágì ìdílé àwọn ọmọ Hágì; ti Ṣúnì ìdílé àwọn ọmọ Ṣúnì; 16  ti Ósínì ìdílé àwọn ọmọ Ósínì; ti Érì ìdílé àwọn ọmọ Érì; 17  ti Áródù ìdílé àwọn ọmọ Áródù; ti Árélì+ ìdílé àwọn ọmọ Árélì. 18  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọkùnrin Gádì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 19  Àwọn ọmọkùnrin Júdà+ ni Éérì+ àti Ónánì.+ Àmọ́ ṣá o, Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+ 20  Àwọn ọmọkùnrin Júdà sì wá jẹ́, nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣélà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà; ti Pérésì+ ìdílé àwọn ọmọ Pérésì; ti Síírà+ ìdílé àwọn ọmọ Síírà. 21  Àwọn ọmọkùnrin Pérésì sì wá jẹ́: Ti Hésírónì+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; ti Hámúlù+ ìdílé àwọn ọmọ Hámúlù. 22  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Júdà,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá méjì dínlógójì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 23  Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Tólà+ ìdílé àwọn Tólà; ti Púfà ìdílé àwọn Púnì; 24  ti Jáṣúbù ìdílé àwọn ọmọ Jáṣúbù; ti Ṣímúrónì+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣímúrónì. 25  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Ísákárì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá méjì lélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún.+ 26  Àwọn ọmọkùnrin Sébúlúnì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Sérédì ìdílé àwọn ọmọ Sérédì; ti Élónì ìdílé àwọn ọmọ Élónì; ti Jálíẹ́lì+ ìdílé àwọn ọmọ Jálíẹ́lì. 27  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Sébúlúnì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 28  Àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù+ nípa àwọn ìdílé wọn ni Mánásè+ àti Éfúráímù. 29  Àwọn ọmọkùnrin Mánásè+ ni: Ti Mákírù+ ìdílé àwọn ọmọ Mákírù. Mákírù sì bí Gílíádì. Ti Gílíádì+ ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì. 30  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Gílíádì: Ti Yésérì+ ìdílé àwọn ọmọ Yésérì; ti Hélékì ìdílé àwọn ọmọ Hélékì; 31  ti Ásíríélì ìdílé àwọn ọmọ Ásíríélì; ti Ṣékémù ìdílé àwọn ọmọ Ṣékémù; 32  ti Ṣẹ́mídà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà; ti Héfà+ ìdílé àwọn ọmọ Héfà. 33  Wàyí o, Sélóféhádì ọmọkùnrin Héfà kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin,+ orúkọ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì sì ni Málà àti Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà.+ 34  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Mánásè, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+ 35  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣútélà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣútélà; ti Békérì ìdílé àwọn ọmọ Békérì; ti Táhánì+ ìdílé àwọn ọmọ Táhánì. 36  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Ṣútélà: Ti Éránì ìdílé àwọn ọmọ Éránì. 37  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù nípa àwọn ìdílé wọn.+ 38  Àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Bélà+ ìdílé àwọn ọmọ Bélà; ti Áṣíbélì+ ìdílé àwọn ọmọ Áṣíbélì; ti Áhírámù ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù; 39  ti Ṣẹ́fúfámù ìdílé àwọn ọmọ Súfámù; ti Húfámù+ ìdílé àwọn ọmọ Húfámù. 40  Àwọn ọmọkùnrin Bélà wá jẹ́ Áádì àti Náámánì:+ Ti Áádì ìdílé àwọn ọmọ Áádì; ti Náámánì ìdílé àwọn ọmọ Náámánì. 41  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì+ nípa àwọn ìdílé wọn, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ.+ 42  Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Dánì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣúhámù ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Dánì+ nípa àwọn ìdílé wọn. 43  Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn, jẹ́ ẹgbàá méjì lélọ́gbọ̀n ó lé irínwó.+ 44  Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Ímúnà+ ìdílé àwọn ọmọ Ímúnà; ti Íṣífì+ ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì; ti Bẹráyà ìdílé àwọn ọmọ Bẹráyà; 45  ti àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà: Ti Hébà ìdílé àwọn ọmọ Hébà; ti Málíkíélì+ ìdílé àwọn ọmọ Málíkíélì. 46  Orúkọ ọmọbìnrin Áṣérì sì ni Sérà.+ 47  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+ 48  Àwọn ọmọkùnrin Náfútálì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Jáséélì+ ìdílé àwọn ọmọ Jáséélì; ti Gúnì+ ìdílé àwọn ọmọ Gúnì; 49  ti Jésérì+ ìdílé àwọn ọmọ Jésérì; ti Ṣílẹ́mù+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣílẹ́mù. 50  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Náfútálì+ nípa àwọn ìdílé wọn, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé egbèje.+ 51  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ó lé ọgbọ̀n.+ 52  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 53  “Kí a pín ilẹ̀ náà fún àwọn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ogún nípa iye orúkọ.+ 54  Ní ìbámu pẹ̀lú pípọ̀ iye ni kí o bù sí ogún ẹni, ní ìbámu pẹ̀lú ìkéréníye sì ni kí o dín ogún ẹni kù.+ Kí a fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ogún ní ìwọ̀n àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀. 55  Kì kì nípasẹ̀ kèké+ ni kí a pín ilẹ̀ náà. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọ́n gba ogún. 56  Nípasẹ̀ ìpinnu kèké ni kí a pín ogún ẹni láàárín àwọn tí ó pọ̀ àti àwọn tí ó kéré.” 57  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Gẹ́ṣónì+ ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì; ti Kóhátì+ ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì; ti Mérárì+ ìdílé àwọn ọmọ Mérárì. 58  Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Léfì: ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Máhílì,+ ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kórà.+ Kóhátì+ sì bí Ámúrámù.+ 59  Orúkọ aya Ámúrámù sì ni Jókébédì,+ ọmọbìnrin Léfì, ẹni tí aya rẹ̀ bí fún Léfì ní Íjíbítì. Nígbà tí ó ṣe, ó bí Áárónì àti Mósè àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámúrámù.+ 60  Lẹ́yìn náà, a bí Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì+ fún Áárónì. 61  Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú nítorí mímú tí wọ́n mú iná aláìbá-ìlànà-mu wá síwájú Jèhófà.+ 62  Àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún, gbogbo ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè.+ Nítorí a kò forúkọ wọn sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé a kò ní fún wọn ní ogún kankan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 63  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí Mósè àti Élíásárì àlùfáà forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+ 64  Ṣùgbọ́n nínú àwọn wọ̀nyí kò sí ọkùnrin kan lára àwọn tí Mósè àti Áárónì àlùfáà forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aginjù Sínáì.+ 65  Nítorí pé, Jèhófà ti sọ nípa wọn pé: “Láìkùnà, wọn yóò kú ní aginjù.”+ Nítorí náà, ọkùnrin kan ṣoṣo kò ṣẹ́ kù lára wọn bí kò ṣe Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé