Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 25:1-18

25  Wàyí o, Ísírẹ́lì ń gbé ní Ṣítímù.+ Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.+  Àwọn obìnrin náà sì wá ń pe àwọn ènìyàn náà sí ẹbọ àwọn ọlọ́run wọn,+ àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ, wọ́n sì ń tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run wọn.+  Bí Ísírẹ́lì ṣe so ara rẹ̀ mọ́ Báálì Péórù+ nìyẹn; ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí ru sí Ísírẹ́lì.+  Nítorí náà, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Mú gbogbo àwọn olórí nínú àwọn ènìyàn náà, kí o sì gbé wọn síta síwájú Jèhófà+ síhà oòrùn, kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà lè yí padà kúrò lọ́dọ̀ Ísírẹ́lì.”  Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn onídàájọ́ Ísírẹ́lì+ pé: “Kí olúkúlùkù yín pa+ àwọn ọkùnrin tirẹ̀ tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Báálì Péórù.”  Ṣùgbọ́n, wò ó! ọkùnrin+ kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá, ó sì ń mú obìnrin+ Mídíánì kan bọ̀ lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ lójú Mósè àti lójú gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí wọ́n ti ń sunkún ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.  Nígbà tí Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà tajú kán rí i, ní kíá, ó dìde kúrò ní àárín àpéjọ, ó sì mú aṣóró kan ní ọwọ́ rẹ̀.  Nígbà náà ni ó tẹ̀ lé ọkùnrin Ísírẹ́lì náà wọnú àgọ́ olórùlé bìrìkìtì náà, ó sì gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ, ọkùnrin Ísírẹ́lì náà àti obìnrin náà ní ẹ̀yà ara ìbímọ rẹ̀. Látàrí ìyẹn, òjòjò àrànkálẹ̀ náà dáwọ́ dúró lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Àwọn tí ó sì kú nínú òjòjò àrànkálẹ̀ náà jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbàajì .+ 10  Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 11  “Fíníhásì+ ọmọkùnrin Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà ti yí ìrunú+ mi padà kúrò lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa bí òun kò ṣe fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn,+ tó bẹ́ẹ̀ tí èmi kò fi pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run pátápátá nínú fífi dandan tí mo fi dandan lé ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.+ 12  Nítorí ìdí yẹn sọ pé, ‘Kíyè sí i, èmi yóò fún un ní májẹ̀mú àlàáfíà mi. 13  Yóò sì jẹ́ májẹ̀mú iṣẹ́ àlùfáà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún òun àti ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,+ nítorí òtítọ́ náà pé kò fàyè gba bíbá Ọlọ́run+ rẹ̀ díje, tí ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+ 14  Ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ọkùnrin ọmọ Ísírẹ́lì tí a kọlù lọ́nà tí ó yọrí sí ikú ẹni tí ó jẹ́ pé a kọlù lọ́nà tí ó yọrí sí ikú pẹ̀lú ọmọbìnrin Mídíánì náà ni Símírì ọmọkùnrin Sálù, ìjòyè+ ti ìdí ilé baba àwọn ọmọ Síméónì. 15  Orúkọ obìnrin ọmọ Mídíánì tí a kọlù lọ́nà tí ó yọrí sí ikú sì ni Kọ́síbì ọmọbìnrin Súúrì;+ òun jẹ́ olórí ọ̀kan nínú àwọn agbo ìdílé ti ìdí ilé baba Mídíánì.+ 16  Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 17  “Jẹ́ kí fífòòró àwọn ọmọ Mídíánì ṣẹlẹ̀, kí ẹ sì kọlù wọ́n,+ 18  nítorí pé wọ́n ń fòòró yín pẹ̀lú àwọn ìṣe àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn tí wọ́n ṣe lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí+ sí yín nínú àlámọ̀rí Péórù+ àti nínú àlámọ̀rí Kọ́síbì+ ọmọbìnrin ìjòyè Mídíánì, arábìnrin wọn ẹni tí a kọlù+ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú ní ọjọ́ òjòjò àrànkálẹ̀ lórí àlámọ̀rí Péórù.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé