Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 23:1-30

23  Nígbà náà ni Báláámù wí fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ+ méje fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí.”  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Bálákì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Báláámù ti wí. Lẹ́yìn ìyẹn, Bálákì àti Báláámù fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+  Báláámù sì ń bá a lọ láti wí fún Bálákì pé: “Dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ, sì jẹ́ kí n lọ. Bóyá Jèhófà yóò kàn sí mi, kí ó sì pàdé mi.+ Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ohun yòówù ti òun yóò fi hàn mí, ni èmi yóò sọ fún ọ dájúdájú.” Nítorí náà, ó lọ sí òkè kékeré dídán borokoto kan.  Nígbà tí Ọlọ́run kàn sí Báláámù,+ nígbà náà ni ó wí fún Un pé: “Mo gbé pẹpẹ méje náà kalẹ̀ ní ẹsẹẹsẹ, mo sì tẹ̀ síwájú láti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Báláámù,+ ó sì wí pé: “Padà tọ Bálákì lọ, èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò sọ.”+  Nítorí náà, ó padà tọ̀ ọ́ lọ, sì wò ó! òun àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Móábù dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀.  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe+ rẹ̀, ó sì wí pé: “Láti Árámù+ ni Bálákì ọba Móábù ti gbìyànjú láti mú mi wá, Láti àwọn òkè ńlá ìlà-oòrùn: ‘Wá, bá mi gégùn-ún fún Jékọ́bù. Bẹ́ẹ̀ ni, wá, dá Ísírẹ́lì lẹ́bi.’+  Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú bú?+ Báwo sì ni mo ṣe lè dá àwọn tí Jèhófà kò dá lẹ́bi ní ẹ̀bi?+  Nítorí láti orí àwọn àpáta ni mo ti rí wọn, Láti àwọn òkè kéékèèké ni mo sì ti rí wọn. Wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ní àdádó gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan,+ Wọn kò sì ka ara wọn mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+ 10  Ta ni ó ti ka iye àwọn egunrín ekuru Jékọ́bù,+ Ta sì ni ó ti ka ìdá mẹ́rin Ísírẹ́lì? Jẹ́ kí ọkàn mi kú ikú àwọn ẹni adúróṣánṣán,+ Sì  jẹ́ kí òpin mi rí gẹ́gẹ́ bí tiwọn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”+ 11  Látàrí èyí, Bálákì wí fún Báláámù pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe sí mi? Kí o lè fi àwọn ọ̀tá mi bú ni mo ṣe mú ọ wá, sì kíyè sí i ìwọ tí súre fún wọn dé góńgó.”+ 12  Ẹ̀wẹ̀, ó dáhùn, ó sì wí pé: “Kì  í ha ṣe ohun yòówù tí Jèhófà bá fi sí mi ní ẹnu ni èmi yóò kíyè sí láti sọ bí?”+ 13  Nígbà náà ni Bálákì wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, bá mi ká lọ sí ibòmíràn láti ibi tí ìwọ ti lè rí wọn. Kì kì ìkángun wọn ni ìwọ yóò rí,+ ìwọ kì yóò sì rí gbogbo wọn. Kí o sì bá mi fi wọ́n bú láti ibẹ̀.”+ 14  Nítorí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, sí orí Písígà,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+ 15  Lẹ́yìn ìyẹn, ó wí fún Bálákì pé: “Dúró níhìn-ín lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, ní ti èmi, sì jẹ́ kí n kàn sí i níbẹ̀ yẹn.” 16  Lẹ́yìn náà, Jèhófà kàn sí Báláámù, ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu rẹ̀, ó sì wí pé:+ “Padà tọ Bálákì+ lọ, èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò sọ.” 17  Nítorí náà, ó tọ̀ ọ́ lọ, sì wò ó! ó dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀, àti àwọn ọmọ aládé Móábù pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà náà ni Bálákì sọ fún un pé: “Kí ni ohun tí Jèhófà sọ?” 18  Látàrí èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì wí pé:+ “Dìde, Bálákì, sì fetí sílẹ̀. Fi etí sí mi, ìwọ ọmọkùnrin Sípórì.+ 19  Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́,+ Tàbí ọmọ aráyé tí yóò fi kábàámọ̀.+ Òun fúnra rẹ̀ ha ti sọ ọ́ tí kì yóò sì ṣe é, Ó ha sì ti sọ̀rọ̀ tí kì yóò sì mú un ṣẹ?+ 20  Wò ó! A ti mú mi láti súre, Ó sì ti súre,+ èmi kì yóò sì yí i padà.+ 21  Òun kò rí agbára abàmì+ èyíkéyìí lòdì sí Jékọ́bù, Òun kò sì rí ìdààmú kankan kí ó dé bá Ísírẹ́lì. Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+ Ìhó ìyìn ọba sì wà ní àárín rẹ̀. 22  Ọlọ́run ń mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì.+ Ipa ọ̀nà yíyára bí ti akọ màlúù ìgbẹ́ ni tirẹ̀.+ 23  Nítorí kò sí ìsàsí kankan sí Jékọ́bù,+ Tàbí ìwoṣẹ́ èyíkéyìí sí Ísírẹ́lì.+ Ní àkókò yìí, a lè sọ ní ti Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe!’+ 24  Kíyè sí i, àwọn ènìyàn kan yóò dìde bí kìnnìún, Bí kìnnìún ni yóò sì gbé ara rẹ̀ sókè.+ Kì  yóò dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran ọdẹ, Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa ni yóò sì mu.”+ 25  Látàrí èyí, Bálákì wí fún Báláámù pé: “Bí ó bá jẹ́ pé, ní ọwọ́ kan, ìwọ kò lè fi í bú rárá, nígbà náà, ní ọwọ́ kejì , kí ìwọ má ṣe súre fún un rárá.” 26  Ẹ̀wẹ̀, Báláámù dáhùn, ó sì sọ fún Bálákì pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ, pé, ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà yóò sọ ni ohun tí èmi yóò ṣe’?”+ 27  Nígbà náà ni Bálákì wí fún Báláámù pé: “Wá, jọ̀wọ́. Jẹ́ kí n ṣì tún mú ọ lọ sí ibòmíràn. Bóyá yóò tọ̀nà ní ojú Ọlọ́run tòótọ́ kí o lè bá mi fi í bú dájúdájú láti ibẹ̀.”+ 28  Pẹ̀lú ìyẹn, Bálákì mú Báláámù lọ sí orí Péórù, tí ó dojú kọ ìhà Jéṣímónì.+ 29  Nígbà náà ni Báláámù+ wí fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ méje fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí.”+ 30  Nítorí náà, Bálákì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Báláámù ti wí, ó sì tẹ̀ síwájú láti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé