Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 22:1-41

22  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí, wọ́n sì dó sí àwọn aṣálẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù+ ní òdì-kejì Jọ́dánì láti Jẹ́ríkò.  Bálákì+ ọmọkùnrin Sípórì sì wá rí gbogbo ohun tí Ísírẹ́lì ti ṣe sí àwọn Ámórì.  Jìnnìjì nnì sì bá Móábù gidigidi nítorí àwọn ènìyàn náà, nítorí pé wọ́n pọ̀; Móábù sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Móábù sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn àgbà ọkùnrin Mídíánì+ pé: “Nísinsìnyí, ìjọ yìí yóò lá gbogbo àwọn àyíká wa bí akọ màlúù ti ń lá èéhù tútù yọ̀yọ̀ inú pápá.” Bálákì+ ọmọkùnrin Sípórì sì ni ọba Móábù ní àkókò yẹn gan-an.  Wàyí o, ó rán àwọn ońṣẹ́ sí Báláámù+ ọmọkùnrin Béórì ní Pétórì,+ èyí tí ó wà lẹ́bàá Odò+ ilẹ̀ àwọn ọmọ ènìyàn rẹ̀, pé kí wọ́n lọ pè é, pé: “Wò ó! Àwọn ènìyàn kan ti jáde wá láti Íjíbítì. Wò ó! Wọ́n bo ilẹ̀ títí lọ dé ibi tí ènìyàn lè rí i dé,+ iwájú mi gan-an sì ni wọ́n ń gbé.  Wá nísinsìnyí, jọ̀wọ́; bá mi gégùn-ún+ fún àwọn ènìyàn yìí, nítorí wọ́n jẹ́ alágbára ńlá jù mí lọ. Bóyá èmi yóò lè kọlù wọ́n, kí n sì lé wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ náà; nítorí mo mọ̀ dáadáa pé ẹni tí o bá bù kún jẹ́ alábùkún, ẹni tí o bá sì gégùn-ún fún jẹ́ ẹni ègún.”+  Nítorí náà, àwọn àgbà ọkùnrin Móábù àti àwọn àgbà ọkùnrin Mídíánì rin ìrìn àjò pẹ̀lú owó ìwoṣẹ́+ ní ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Báláámù,+ wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Bálákì fún un.  Látàrí ìyẹn, ó wí fún wọn pé: “Ẹ wọ̀ síhìn-ín ní òru òní, dájúdájú, èmi yóò sì mú ọ̀rọ̀ padà fún yín gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà yóò ti sọ fún mi.”+ Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ọmọ aládé Móábù sì dúró sọ́dọ̀ Báláámù.  Nígbà náà ni Ọlọ́run tọ Báláámù wá, ó sì wí pé:+ “Àwọn wo ni ọkùnrin wọ̀nyí tí ó wà pẹ̀lú rẹ?” 10  Nítorí náà, Báláámù wí fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Bálákì+ ọmọkùnrin Sípórì, ọba Móábù, ránṣẹ́ sí mi, pé, 11  ‘Wò ó! Àwọn ènìyàn tí ń jáde bọ̀ láti Íjíbítì, wọ́n sì bo ilẹ̀ títí lọ dé ibi tí ojú lè rí i dé.+ Nísinsìnyí wá, bá mi fi wọ́n bú.+ Bóyá èmi yóò lè bá wọn jà, kí n sì lé wọn jáde ní ti tòótọ́.’” 12  Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún Báláámù pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ bá wọn lọ. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gégùn-ún fún àwọn ènìyàn náà,+ nítorí pé alábùkún ni wọ́n.”+ 13  Lẹ́yìn ìyẹn, Báláámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì wí fún àwọn ọmọ aládé Bálákì pé: “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín, nítorí pé Jèhófà kọ̀ láti jẹ́ kí n bá yín lọ.” 14  Nítorí náà, àwọn ọmọ aládé Móábù dìde, wọ́n sì tọ Bálákì wá, wọ́n sì wí pé: “Báláámù kọ̀ láti bá wa wá.”+ 15  Bí ó ti wù kí ó rí, Bálákì tún rán àwọn ọmọ aládé mìíràn ní iye tí ó pọ̀, tí ó sì tún ní ọlá ju ti ìṣáájú. 16  Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tọ Báláámù wá, wọ́n sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Bálákì ọmọkùnrin Sípórì wí, ‘Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí a dá ọ dúró láti wá sọ́dọ̀ mi. 17  Nítorí láìkùnà, èmi yóò bọlá fún ọ lọ́pọ̀lọpọ̀,+ ohun gbogbo tí ìwọ yóò wí fún mi ni èmi yóò ṣe.+ Nítorí náà, wá, jọ̀wọ́. Bá mi fi àwọn ènìyàn yìí bú.’” 18  Ṣùgbọ́n Báláámù dáhùn, ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ Bálákì pé: “Bí Bálákì yóò bá fún mi ní ilé rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kì yóò lè ré àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà Ọlọ́run mi kọjá, láti lọ ṣe ohun kékeré tàbí ńlá.+ 19  Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ tún dúró síhìn-ín ní òru òní kí n lè mọ ohun tí Jèhófà yóò tún wí fún mi.”+ 20  Nígbà náà ni Ọlọ́run tọ Báláámù wá ní òru, ó sì wí fún un pé: “Bí ó bá jẹ́ láti pè ọ́ ni àwọn ọkùnrin náà ṣe wá, dìde, bá wọn lọ. Ṣùgbọ́n kìkì ọ̀rọ̀ tí èmi yóò wí fún ọ ni ohun tí ìwọ yóò sọ.”+ 21  Lẹ́yìn ìyẹn, Báláámù dìde ní òwúrọ̀, ó sì di abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì bá àwọn ọmọ aládé Móábù lọ.+ 22  Ìbínú Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ru nítorí pé ó ń lọ; áńgẹ́lì Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti dúró ní ojú ọ̀nà láti dènà rẹ̀.+ Ó sì ń gun abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23  Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì wá rí áńgẹ́lì Jèhófà tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀;+ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì gbìyànjú láti yà kúrò ní ojú ọ̀nà kí ó lè lọ sínú pápá, ṣùgbọ́n Báláámù bẹ̀rẹ̀ sí lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà láti darí rẹ̀ padà sójú ọ̀nà. 24  Áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró pa sí ọ̀nà tóóró láàárín àwọn ọgbà àjàrà náà, pẹ̀lú ògiri òkúta ní ìhà ìhín àti ògiri òkúta ní ìhà ọ̀hún. 25  Abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì ń bá a nìṣó ní rírí áńgẹ́lì Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún ara rẹ̀ mọ́ ògiri náà tó bẹ́ẹ̀ tí ó sì fún ẹsẹ̀ Báláámù mọ́ ògiri; ó sì túbọ̀ ń lù ú. 26  Áńgẹ́lì Jèhófà tún kọjá wàyí, ó sì dúró ní ibi tóóró kan, níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì. 27  Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá rí áńgẹ́lì Jèhófà wàyí, ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ Báláámù; tó bẹ́ẹ̀ tí ìbínú Báláámù fi ru,+ ó sì ń bá a nìṣó ní fífi ọ̀pá rẹ̀ lu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. 28  Níkẹyìn, Jèhófà la ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ náà, ó sì wí fún Báláámù pé: “Kí ni mo fi ṣe ọ́ tí o fi lù mí ní ìgbà mẹ́ta yìí?”+ 29  Látàrí èyí, Báláámù wí fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pé: “Ó jẹ́ nítorí tí ìwọ ti hùwà sí mi lọ́nà ìsánjú. Ì bá ṣe pé idà wà ní ọwọ́ mi ni, èmi ì bá ti pa ọ́ nísinsìnyí!”+ 30  Nígbà náà ni abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wí fún Báláámù pé: “Èmi ha kọ́ ni abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ tí o ti ń gùn ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ títí di òní yìí? Ṣé mo ti máa ń ṣe báyìí sí ọ rí?”+ Ó dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́!” 31  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti la ojú+ Báláámù, tí ó fi rí áńgẹ́lì Jèhófà tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà rẹ̀ tí ó fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀. Ní kíá, ó tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó sì wólẹ̀ ní dídojúbolẹ̀. 32  Nígbà náà ni áńgẹ́lì Jèhófà wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi lu abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ ní ìgbà mẹ́ta yìí? Wò ó! Èmi—èmi ti jáde wá láti ṣe ìdènà, nítorí pé ọ̀nà rẹ ti wà ní ìforígbárí pẹ̀lú ohun tí mo fẹ́.+ 33  Abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì wá rí mi, ó sì gbìyànjú láti yà kúrò níwájú mi ní ìgbà mẹ́ta yìí.+ Ká ní kò ti yà kúrò níwájú mi! Àní ìwọ ni èmi ì bá ti pa nísinsìnyí,+ ṣùgbọ́n òun ni èmi ì bá ti pa mọ́ láàyè.” 34  Látàrí èyí, Báláámù wí fún áńgẹ́lì Jèhófà pé: “Èmi ti ṣẹ̀,+ nítorí èmi kò mọ̀ pé ìwọ ni ó dúró ní ojú ọ̀nà láti pàdé mi. Wàyí o, bí ó bá burú ní ojú rẹ, jẹ́ kí n padà.” 35  Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì Jèhófà wí fún Báláámù pé: “Máa bá àwọn ọkùnrin náà lọ;+ má sì sọ nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí èmi yóò bá ọ sọ.”+ Báláámù sì tẹ̀ síwájú ní bíbá àwọn ọmọ aládé Bálákì lọ. 36  Nígbà tí Bálákì wá gbọ́ pé Báláámù ti dé, ní kíá, ó jáde lọ láti pàdé rẹ̀ ní ìlú ńlá Móábù, èyí tí ó wà ní bèbè Áánónì, èyí tí ó wà ní ìkángun ìpínlẹ̀ náà.+ 37  Nígbà náà ni Bálákì wí fún Báláámù pé: “Èmi kò ha ti ránṣẹ́ pé kí wọ́n pè ọ́ wá ní ti tòótọ́? Èé ṣe tí o kò fi wá sọ́dọ̀ mi? Èmi kò ha lè bọlá fún ọ ní ti gidi àti ní tòótọ́ bí?”+ 38  Látàrí èyí, Báláámù wí fún Bálákì pé: “Kíyè sí i mo ti wá sọ́dọ̀ rẹ wàyí. Yóò ha ṣeé ṣe fún mi rára láti sọ ohun kan bí?+ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run yóò fi sí ẹnu mi ni ohun tí èmi yóò sọ.”+ 39  Nítorí náà, Báláámù bá Bálákì lọ, wọ́n sì wá sí Kiriati-húsótì. 40  Bálákì sì tẹ̀ síwájú láti fi màlúù àti àgùntàn rúbọ,+ ó sì fi lára rẹ̀ ránṣẹ́ sí Báláámù àti sí àwọn ọmọ aládé tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀. 41  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní òwúrọ̀ pé, Bálákì lọ mú Báláámù, ó sì mú un gòkè lọ sí Bamoti-báálì,+ kí ó lè rí gbogbo àwọn ènìyàn náà láti ibẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé