Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 21:1-35

21  Wàyí o, ọmọ Kénáánì ọba Árádì,+ tí ń gbé Négébù,+ wá gbọ́ pé Ísírẹ́lì ti gba ọ̀nà Átárímù wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Ísírẹ́lì jà, ó sì kó lára wọn lọ bí òǹdè.  Nítorí náà, Ísírẹ́lì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà, ó sì wí pé:+ “Láìkùnà, bí ìwọ yóò bá fi àwọn ènìyàn yìí lé mi lọ́wọ́, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò ya àwọn ìlú ńlá wọn sọ́tọ̀ fún ìparun.”+  Nítorí náà, Jèhófà fetí sí ohùn Ísírẹ́lì, ó sì fi àwọn ọmọ Kénáánì fún un; wọ́n sì ya àwọn àti àwọn ìlú ńlá wọn sọ́tọ̀ fún ìparun. Nítorí náà, wọ́n pe orúkọ ibẹ̀ ní Hóómà.+  Nígbà tí wọ́n ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀ rìn láti Òkè Ńlá Hóórì+ gba ti Òkun Pupa láti lọ yí ká ilẹ̀ Édómù,+ ọkàn àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣàárẹ̀ nítorí ọ̀nà náà.  Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a nìṣó ní sísọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run+ àti Mósè+ pé: “Èé ṣe tí ẹ fi mú wa gòkè wá láti Íjíbítì láti kú ní aginjù?+ Nítorí kò sí oúnjẹ, kò sì sí omi,+ ọkàn wa sì ti fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra oúnjẹ játijàti+ yìí.”  Nítorí náà, Jèhófà rán àwọn ejò olóró+ sáàárín àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní bíbu àwọn ènìyàn náà ṣán, tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì fi kú.+  Níkẹyìn, àwọn ènìyàn náà tọ Mósè wá, wọ́n sì wí pé: “A ti ṣẹ̀,+ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ sí Jèhófà àti sí ọ. Bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà kí ó lè mú àwọn ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.”+ Mósè sì lọ ń bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn náà.+  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Ṣe ejò oníná kan fún ara rẹ, kí o sì fi í sára òpó àmì àfiyèsí. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí ejò bá bu ẹnikẹ́ni ṣán, nígbà náà, òun ní láti wò ó, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ máa wà láàyè nìṣó.”+  Ní kíá, Mósè ṣe ejò bàbà kan,+ ó sì fi í sára òpó+ àmì àfiyèsí náà; ó sì ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́ pé bí ejò bá ti bu ènìyàn kan ṣán, tí ó sì tẹjú mọ́+ ejò bàbà náà, nígbà náà, òun a máa wà láàyè nìṣó.+ 10  Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣí, wọ́n sì dó sí Óbótì.+ 11  Nígbà náà ni wọ́n ṣí kúrò ní Óbótì, wọ́n sì dó sí Iye-ábárímù,+ ní aginjù tí ó wà níhà iwájú Móábù, níhà yíyọ oòrùn. 12  Láti ibẹ̀ wọ́n ṣí, wọ́n sì dó sẹ́bàá àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Séréédì.+ 13  Láti ibẹ̀ wọ́n ṣí, wọ́n sì dó sí ẹkùn ilẹ̀ Áánónì,+ tí ó wà ní aginjù tí ó nasẹ̀ wá láti ojú ààlà àwọn Ámórì; nítorí Áánónì ni ààlà Móábù, láàárín Móábù àti àwọn Ámórì. 14  Ìdí nìyẹn tí a fi sọ nínú ìwé Àwọn Ogun Jèhófà pé: “Fáhébù tí ó wà ní Súfà àti àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì, 15  àti ẹnu àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, èyí tí ó tẹ ara rẹ̀ síhà ìjókòó Árì,+ tí ó sì fara ti ojú ààlà Móábù.” 16  Lẹ́yìn náà, láti ibẹ̀ wọ́n tẹ̀ síwájú sí Bíà.+ Èyí ni kànga náà tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Mósè pé: “Kó àwọn ènìyàn náà jọ, kí n sì fún wọn ní omi.”+ 17  Àkókò yẹn ni Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin+ yìí pé: “Sun jáde, ìwọ kànga! Dáhùn padà sí i, ẹ̀yin ènìyàn! 18  Kànga kan, àwọn ọmọ aládé ni ó gbẹ́ ẹ. Ọ̀tọ̀kùlú àwọn ènìyàn ni ó wà á, Pẹ̀lú ọ̀pá+ àṣẹ, pẹ̀lú àwọn ọ̀pá tiwọn.” Lẹ́yìn náà, láti aginjù, wọ́n tẹ̀ síwájú sí Mátánà. 19  Àti láti Mátánà, wọ́n tẹ̀ síwájú sí Náhálíélì, àti láti Náhálíélì lọ sí Bámótì.+ 20  Àti láti Bámótì, wọ́n tẹ̀ síwájú sí àfonífojì náà tí ó wà ní pápá Móábù,+ ní orí Písígà,+ ó sì yọ jáde síhà ojú Jéṣímónì.+ 21  Wàyí o, Ísírẹ́lì rán àwọn ońṣẹ́ sí Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, wí pé: 22  “Jẹ́ kí n gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa kì yóò yà sínú pápá tàbí sínú ọgbà àjàrà. Àwa kì yóò mu nínú omi kànga kankan. Ojú ọ̀nà ọba ni àwa yóò gbà títí a ó gba la ìpínlẹ̀ rẹ kọjá.”+ 23  Síhónì kò sì yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gba ìpínlẹ̀ rẹ̀ kọjá,+ ṣùgbọ́n Síhónì kó gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, wọ́n sì jáde lọ láti pàdé Ísírẹ́lì ní aginjù, ó sì wá sí Jáhásì,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Ísírẹ́lì jà. 24  Látàrí ìyẹn, Ísírẹ́lì fi ojú idà+ kọlù ú, ó sì gba ilẹ̀+ rẹ̀ láti Áánónì+ lọ dé Jábókù,+ nítòsí àwọn ọmọ Ámónì; nítorí pé Jásérì+ ni ojú ààlà àwọn ọmọ Ámónì.+ 25  Báyìí ni Ísírẹ́lì ṣe gba gbogbo àwọn ìlú ńlá wọ̀nyí, Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé nínú gbogbo ìlú ńlá àwọn Ámórì,+ ní Hẹ́ṣíbónì+ àti gbogbo àwọn àrọko rẹ̀. 26  Nítorí Hẹ́ṣíbónì ni ìlú ńlá Síhónì.+ Òun ni ọba àwọn Ámórì,+ òun sì ni ẹni tí ó bá ọba Móábù jà tẹ́lẹ̀ rí tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Áánónì.+ 27  Ìdí nìyẹn tí àwọn akéwì ìfiniṣẹlẹ́yà fi máa ń wí pé: “Wá sí Hẹ́ṣíbónì. Jẹ́ kí a kọ́ ìlú ńlá Síhónì, kí ó sì jẹ́ èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in. 28  Nítorí iná ti jáde wá láti Hẹ́ṣíbónì,+ ọwọ́ iná láti ìlú Síhónì. Ó ti jó Árì+ ti Móábù run, olúwa àwọn ibi gíga ti Áánónì. 29  Ègbé ni fún ọ, Móábù! Dájúdájú, ẹ ó ṣègbé, ẹ̀yin ènìyàn Kémóṣì!+ Dájúdájú, òun yóò fi àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó sá lọ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ nínú oko òǹdè fún Síhónì, ọba àwọn Ámórì. 30  Nítorí náà, jẹ́ kí a tafà sí wọn. Dájúdájú, Hẹ́ṣíbónì yóò ṣègbé títí dé Díbónì,+ Àti àwọn obìnrin títí dé Nófà, àwọn ọkùnrin títí dé Médébà.”+ 31  Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ilẹ̀ àwọn Ámórì.+ 32  Nígbà náà ni Mósè rán àwọn kan lọ ṣe amí Jásérì.+ Nítorí náà, wọ́n gba àwọn àrọko rẹ̀, wọ́n sì lé àwọn Ámórì tí wọ́n wà níbẹ̀ kúrò.+ 33  Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n yí padà, wọ́n sì gòkè lọ láti gba ọ̀nà Báṣánì.+ Látàrí èyí, Ógù+ ọba Báṣánì jáde wá láti pàdé wọn, òun àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, fún ìjà ogun ní Édíréì.+ 34  Wàyí o, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Má fòyà rẹ̀,+ nítorí èmi yóò fi òun àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ilẹ̀+ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́ dájúdájú; kí o sì ṣe sí i gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì, ẹni tí ń gbé ní Hẹ́ṣíbónì+ tẹ́lẹ̀ rí.” 35  Nítorí náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlu òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, títí kò fi sí olùlàájá kankan tí ó ṣẹ́ kù fún un;+ wọ́n sì gba ilẹ̀ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé