Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 20:1-29

20  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo àpéjọ náà pátá, sì bẹ̀rẹ̀ sí dé sí aginjù Síínì+ ní oṣù kìíní, àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Kádéṣì.+ Ibẹ̀ ni Míríámù+ kú sí, ibẹ̀ sì ni a sin ín sí.  Wàyí o, kò wá sí omi kankan fún àpéjọ+ náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pe ara wọn jọpọ̀ lòdì sí Mósè àti Áárónì.+  Àwọn ènìyàn náà sì ń bá Mósè ṣe aáwọ̀,+ wọ́n sì ń wí pé: “Àwa ì bá kúkú ti gbẹ́mìí mì nígbà tí àwọn arákùnrin wa gbẹ́mìí mì níwájú Jèhófà!+  Èé sì ti ṣe tí ẹ fi mú ìjọ Jèhófà wá sí aginjù yìí kí àwa àti àwọn ẹranko arẹrù wa lè kú níbẹ̀?+  Èé sì ti ṣe tí ẹ fi kó wa gòkè láti Íjíbítì wá láti mú wa wá sí ibi búburú yìí?+ Kì  í ṣe ibi irúgbìn àti àwọn ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà àti pómégíránétì,+ kò sì sí omi láti mu.”  Nígbà náà ni Mósè àti Áárónì ti iwájú ìjọ wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì dojú bolẹ̀,+ ògo Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn wọ́n.+  Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Mú ọ̀pá+ náà, kí o sì pe àpéjọ náà jọ, ìwọ àti Áárónì arákùnrin rẹ, kí ẹ sì bá àpáta gàǹgà sọ̀rọ̀ lójú wọn kí ó lè pèsè omi rẹ̀ ní tòótọ́; kí o sì mú omi jáde fún wọn láti inú àpáta gàǹgà náà, kí o sì fún àpéjọ àti ẹranko arẹrù wọn ní ohun mímu.”+  Nítorí náà, Mósè mú ọ̀pá náà kúrò níwájú Jèhófà,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún un. 10  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè àti Áárónì pe ìjọ náà jọ síwájú àpáta gàǹgà náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ gbọ́, nísinsìnyí, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀!+ Ṣé láti inú àpáta gàǹgà yìí ni kí a ti mú omi jáde fún yín?”+ 11  Pẹ̀lú ìyẹn, Mósè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì fi ọ̀pá rẹ̀ lu àpáta gàǹgà náà lẹ́ẹ̀mejì ; omi púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá, àpéjọ àti àwọn ẹranko arẹrù wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí mu.+ 12  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè àti Áárónì pé: “Nítorí tí ẹ kò fi ìgbàgbọ́ hàn nínú mi láti sọ mí di mímọ́+ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí náà, ẹ kì yóò mú ìjọ yìí wá sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn dájúdájú.”+ 13  Ìwọ̀nyí ni omi Mẹ́ríbà,+ nítorí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá Jèhófà ṣe aáwọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi sọ ọ́ di mímọ́ láàárín wọn. 14  Lẹ́yìn náà, Mósè rán àwọn ońṣẹ́ láti Kádéṣì sí ọba Édómù+ pé: “Èyí ni ohun tí arákùnrin rẹ Ísírẹ́lì+ wí, ‘Ìwọ fúnra rẹ mọ gbogbo ìnira tí ó ti dé bá wa lójijì  dunjú.+ 15  Àwọn baba wa sì tẹ̀ síwájú láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì,+ a sì ń gbé ní Íjíbítì fún ọ̀pọ̀ ọjọ́;+ àwọn ará Íjíbítì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìpalára fún wa àti fún àwọn baba wa.+ 16  Níkẹyìn, a ké jáde sí Jèhófà,+ ó sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rán áńgẹ́lì+ kan, ó sì mú wa jáde kúrò ní Íjíbítì; àwa sì rèé ní Kádéṣì, ìlú ńlá kan tí ó wà ní ìkángun ìpínlẹ̀ rẹ. 17  Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a gba ilẹ̀ rẹ kọjá.+ Àwa kì yóò la inú pápá kọjá tàbí ọgbà àjàrà, àwa kì yóò sì mu nínú omi kànga. Ojú ọ̀nà ọba ni àwa yóò gbà. Àwa kì yóò yà sí ọ̀tùn tàbí sí òsì,+ títí a ó fi la ìpínlẹ̀ rẹ kọjá.’” 18  Bí ó ti wù kí ó rí, Édómù wí fún un pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ gba ọ̀dọ̀ mi kọjá, kí n má bàa jáde wá pàdé rẹ ti èmi ti idà.” 19  Ẹ̀wẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún un pé: “Òpópó ni àwa yóò gbà gòkè lọ; bí èmi àti ohun ọ̀sìn mi bá sì mu omi rẹ, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò fún ọ ní iye owó rẹ̀.+ Kò sí nǹkan kan tí mo fẹ́ ju pé kí n fi ẹsẹ̀ mi rìn kọjá.”+ 20  Síbẹ̀, ó wí pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ kọjá.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, Édómù+ jáde wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn púpọ̀ gan-an àti ọwọ́ líle. 21  Bẹ́ẹ̀ ni Édómù kọ̀ láti yọ̀ǹda fún Ísírẹ́lì láti gba ìpínlẹ̀ rẹ̀ kọjá.+ Nítorí náà, Ísírẹ́lì yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.+ 22  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbogbo àpéjọ pátá, sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí kúrò ní Kádéṣì,+ wọ́n sì wá sí Òkè Ńlá Hóórì.+ 23  Nígbà náà ni Jèhófà sọ èyí fún Mósè àti Áárónì ní Òkè Ńlá Hóórì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ààlà ilẹ̀ Édómù pé: 24  “A óò kó Áárónì jọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀,+ nítorí kì yóò wọ ilẹ̀ tí èmi yóò fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dájúdájú, nítorí ìdí náà pé ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni mi nípa omi Mẹ́ríbà.+ 25  Mú Áárónì àti Élíásárì ọmọkùnrin rẹ̀, kí o sì mú wọn gòkè wá sí Òkè Ńlá Hóórì. 26  Kí o sì bọ́ ẹ̀wù+ Áárónì kúrò lára rẹ̀, kí o sì fi wọ́n wọ Élíásárì+ ọmọkùnrin rẹ̀; Áárónì ni a ó sì kó jọ, yóò sì kú níbẹ̀.”+ 27  Nítorí náà, Mósè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ; lójú gbogbo àpéjọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gun Òkè Ńlá Hóórì. 28  Nígbà náà ni Mósè bọ́ ẹ̀wù Áárónì kúrò lára rẹ̀, ó sì fi wọ́n wọ Élíásárì ọmọkùnrin rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí Áárónì kú níbẹ̀ ní orí òkè ńlá náà.+ Mósè àti Élíásárì sì sọ̀ kalẹ̀ wá láti orí òkè ńlá náà. 29  Gbogbo àpéjọ sì wá rí i pé Áárónì ti gbẹ́mìí mì, gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ ní sísunkún fún Áárónì ní ọgbọ̀n ọjọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé