Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 2:1-34

2  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé:  “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó, olúkúlùkù ọkùnrin sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín+ rẹ̀ tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta, sẹ́gbẹ̀ẹ́ àmì ilé baba wọn. Kí wọ́n dó yí ká sí iwájú àgọ́ ìpàdé.  “Àwọn tí yóò sì dó sí ìlà-oòrùn síhà yíyọ oòrùn yóò jẹ́ ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Júdà sì ni Náṣónì+ ọmọkùnrin Ámínádábù.  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọ́n jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì  ó lé ẹgbẹ̀ta.+  Ẹ̀yà Ísákárì+ ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Ísákárì sì ni Nétánélì+ ọmọkùnrin Súárì.  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó.+  Àti ẹ̀yà Sébúlúnì; ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì sì ni Élíábù+ ọmọkùnrin Hélónì.  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá méjì dínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+  “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé egbèjì lélọ́gbọ̀n nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣí.+ 10  “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Rúbẹ́nì+ yóò jẹ́ síhà gúúsù nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì ni Élísúrì+ ọmọkùnrin Ṣédéúrì. 11  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 12  Ẹ̀yà Síméónì ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì sì ni Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọkùnrin Súríṣádáì. 13  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọ́n sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó dín ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin.+ 14  Àti ẹ̀yà Gádì; ìjòyè àwọn ọmọ Gádì sì ni Élíásáfù+ ọmọkùnrin Rúẹ́lì. 15  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ.+ 16  “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́ta-lé-légbèje nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, àwọn sì ni yóò ṣí ṣìkejì .+ 17  “Nígbà tí àgọ́ ìpàdé+ bá ní láti ṣí, ibùdó àwọn ọmọ Léfì+ yóò wà ní àárín àwọn ibùdó náà. “Gẹ́gẹ́ bí wọn yóò ṣe dó gan-an, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n ṣe ṣí,+ olúkúlùkù ní àyè rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìpín wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta. 18  “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Éfúráímù+ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn yóò jẹ́ síhà ìwọ̀-oòrùn, ìjòyè àwọn ọmọ Éfúráímù sì ni Élíṣámà+ ọmọkùnrin Ámíhúdù. 19  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 20  Ẹ̀yà Mánásè+ yóò sì wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè sì ni Gàmálíẹ́lì+ ọmọkùnrin Pédásúrì. 21  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba.+ 22  Àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì;+ ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì ni Ábídánì+ ọmọkùnrin Gídíónì. 23  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje.+ 24  “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Éfúráímù jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, àwọn sì ni yóò ṣí ṣẹ̀kẹta.+ 25  “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Dánì yóò jẹ́ síhà àríwá nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Dánì sì ni Áhíésérì+ ọmọkùnrin Ámíṣádáì. 26  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+ 27  Ẹ̀yà Áṣérì ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì sì ni Págíẹ́lì+ ọmọkùnrin Ókíránì. 28  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ.+ 29  Àti ẹ̀yà Náfútálì; ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì+ sì ni Áhírà+ ọmọkùnrin Énánì. 30  Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+ 31  “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjì lá. Àwọn ni yóò ṣí kẹ́yìn+—ní ìbámú pẹ̀lú ìpín wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta.” 32  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn; gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ ní ibùdó nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjì dínlógún dín àádọ́ta.+ 33  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò forúkọ sílẹ̀+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 34  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+ Ọ̀nà tí wọ́n gbà dó nìyẹn ní ìpín+ wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta, ọ̀nà tí wọ́n sì gbà ṣí nìyẹn,+ olúkúlùkù nínú àwọn ìdílé rẹ̀ nípa ilé àwọn baba rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé