Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 19:1-22

19  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé:  “Èyí ni ìlànà àgbékalẹ̀ tí í ṣe ti òfin tí Jèhófà pa láṣẹ, pé, ‘Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n mú abo màlúù pupa tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá tí kò ní àbùkù+ kankan tí a kò sì tíì gbé àjàgà kankan rù rí wá fún ọ.+  Kí ẹ sì fi í fún Élíásárì àlùfáà, kí ó sì mú un jáde lọ sí òde ibùdó, kí a sì pa á níwájú rẹ̀.  Nígbà náà ni kí Élíásárì àlùfáà fi ìka rẹ̀ mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí ó sì wọ́n nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ ní tààràtà sí iwájú àgọ́ ìpàdé ní ìgbà méje.+  Kí a sì sun abo màlúù náà ní ojú rẹ̀. Awọ rẹ̀ àti ẹran rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́bọ́tọ rẹ̀ ni a ó sun.+  Kí àlùfáà sì mú igi kédárì+ àti hísópù+ àti òwú+ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò ti kòkòrò kókọ́sì, kí ó sì sọ ọ́ sí àárín abo màlúù tí a ń sun.  Kí àlùfáà sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, lẹ́yìn ìgbà náà, ó lè wá sínú ibùdó; ṣùgbọ́n kí àlùfáà náà jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.  “‘Ẹni náà tí ó sì sun ún yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀ nínú omi,+ kí ó sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.  “‘Kí ọkùnrin kan tí ó mọ́ sì kó eérú+ abo màlúù náà jọpọ̀, kí ó sì kó wọn sí òde ibùdó ní ibì kan tí ó mọ́; kí wọ́n sì wà fún àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ó pa mọ́ fún omi ìwẹ̀nùmọ́.+ Ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10  Kí ẹni tí ó bá sì kó eérú abo màlúù náà jọ fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+ “‘Kí ó sì ṣiṣẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 11  Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú ọkàn+ ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí kí ó jẹ́ aláìmọ́ pẹ̀lú fún ọjọ́ méje.+ 12  Kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ fi í wẹ ara rẹ̀ mọ́ gaara ní ọjọ́ kẹta,+ ní ọjọ́ keje yóò sì mọ́. Ṣùgbọ́n bí òun kì yóò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ gaara ní ọjọ́ kẹta, nígbà náà, ní ọjọ́ keje kì yóò mọ́. 13  Gbogbo ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú, ọkàn ènìyàn yòówù tí ó bá kú, tí kì yóò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ gaara, ti sọ àgọ́ ìjọsìn+ Jèhófà di ẹlẹ́gbin, ọkàn yẹn ni kí a sì ké kúrò ní Ísírẹ́lì.+ Nítorí tí a kò tíì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́+ sára rẹ̀, ó ń bá a lọ ní jíjẹ́ aláìmọ́. Àìmọ́ rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀.+ 14  “‘Èyí ni òfin náà bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan kú nínú àgọ́: Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wá sínú àgọ́ náà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú àgọ́ náà, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 15  Gbogbo ohun èlò+ tí ó wà ní ṣíṣí tí kò sì ní ọmọrí tí a fi dé e pa lórí jẹ́ aláìmọ́. 16  Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wà ní pápá gbalasa, tí ó sì fọwọ́ kan ẹni tí a fi idà+ pa tàbí òkú tàbí egungun+ ènìyàn tàbí ibi ìsìnkú yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 17  Kí wọ́n sì bù nínú ekuru èjíjó ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìmọ́ náà, kí a sì bu omi tí ń ṣàn sí i nínú ohun èlò kan. 18  Nígbà náà ni kí ọkùnrin kan tí ó mọ́+ mú hísópù,+ kí ó sì tẹ̀ ẹ́ bọ inú omi náà, kí ó sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára àgọ́ náà àti gbogbo ohun èlò àti àwọn ọkàn tí ó bá wà níbẹ̀ àti sára ẹni náà tí ó fọwọ́ kan egungun náà tàbí ẹni tí a pa tàbí òkú tàbí ibi ìsìnkú. 19  Kí ẹni tí ó mọ́ náà sì wọ́n ọn ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ sára aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje, kí ó sì wẹ̀ ẹ́ mọ́ gaara kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ní ọjọ́ keje;+ kí ó sì fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ nínú omi, yóò sì mọ́ ní alẹ́. 20  “‘Ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ tí kì yóò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ gaara, tóò, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò+ láàárín ìjọ, nítorí ibùjọsìn Jèhófà ni ó ti sọ di ẹlẹ́gbin. Omi ìwẹ̀nùmọ́ ni a kò wọ́n sára rẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́. 21  “‘ Kí ó sì wà bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin fún wọn, pé kí ẹni tí ń wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ ṣẹ̀rẹ̀ṣẹ̀rẹ̀ fọ ẹ̀wù+ rẹ̀, àti ẹni tí ó fọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ pẹ̀lú. Òun yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. 22  Ohunkóhun tí aláìmọ́ náà bá sì fọwọ́ kàn yóò jẹ́ aláìmọ́,+ ọkàn tí ó bá sì fọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé