Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 18:1-32

18  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Áárónì sọ̀rọ̀ pé: “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ilé baba rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò máa dáhùn fún ìṣìnà lòdì sí ibùjọsìn,+ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ ni yóò sì máa dáhùn fún ìṣìnà lòdì sí iṣẹ́ àlùfáà+ yín.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, kí o sì mú àwọn arákùnrin rẹ ti ẹ̀yà Léfì, agbo ìdílé baba rẹ, sún mọ́ tòsí pẹ̀lú rẹ, kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọn sì lè ṣe ìránṣẹ́ fún ọ,+ fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ, níwájú àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí.+  Kí wọ́n sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mọ́ sí ọ àti iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn sí gbogbo àgọ́+ náà pátá. Kì kì pé wọn kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ àti pẹpẹ kí wọ́n má bàa kú,+ yálà àwọn tàbí ẹ̀yin.  Kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ ọ, kí wọ́n sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mọ́ sí àgọ́ ìpàdé ní ti gbogbo iṣẹ́ ìsìn àgọ́, àjèjì kankan kò sì gbọ́dọ̀ sún mọ́ yín.+  Kí ẹ sì pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe yín mọ́ sí ibi mímọ́+ àti iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe yín sí pẹpẹ,+ kí ìkannú+ kankan má ṣe tún ṣẹlẹ̀ mọ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Àti èmi, wò ó! mo ti mú àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọ Léfì, nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún yín,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a fi fún Jèhófà láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé.+  Kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ sì fi ìṣọ́ ṣọ́ iṣẹ́ àlùfáà yín ní ti gbogbo ohun tí ó kan pẹpẹ àti ní ti ohun tí ó wà ní inú aṣọ ìkélé;+ kí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ìsìn.+ Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìsìn ẹ̀bùn ni èmi yóò fi iṣẹ́ àlùfáà yín fún yín, àjèjì tí ó bá sì ń sún mọ́ tòsí ni kí a fi ikú pa.”+  Jèhófà sì bá Áárónì sọ̀rọ̀ síwájú sí i pé: “Ní ti èmi, wò ó! mo ti fi àbójútó ọrẹ tí a fún mi sí ìkáwọ́ rẹ.+ Nínú gbogbo ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo ti fi wọ́n fún ọ àti fún àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a yọ̀ǹda fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  Kí èyí di tìrẹ láti inú àwọn ohun mímọ́ jù lọ, láti inú ọrẹ ẹbọ àfinásun, gbogbo ọrẹ ẹbọ wọn pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti gbogbo ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ wọn àti gbogbo ọrẹ ẹbọ ẹ̀bi+ wọn, èyí tí wọn yóò dá padà fún mi. Ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún ọ àti fún àwọn ọmọ rẹ. 10  Inú ibi mímọ́ jù lọ ni kí o ti jẹ ẹ́.+ Kí olúkúlùkù akọ jẹ ẹ́.+ Kí ó di ohun mímọ́ fún ọ.+ 11  Èyí sì jẹ́ tìrẹ: ọrẹ+ láti inú ẹ̀bùn wọn pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọrẹ ẹbọ fífì+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo ti fi wọ́n fún ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ,+ gẹ́gẹ́ bí ohun tí a yọ̀ǹda fún àkókò tí ó lọ kánrin. Gbogbo ẹni tí ó mọ́ nínú ilé rẹ lè jẹ ẹ́.+ 12  “Gbogbo èyí tí ó dára jù lọ lára òróró àti gbogbo èyí tí ó dára jù lọ lára wáìnì tuntun àti ọkà, àkọ́so+ wọn, èyí tí wọn yóò fi fún Jèhófà, mo ti fi wọ́n fún ọ.+ 13  Àwọn àkọ́pọ́n èso ohun gbogbo tí ó wà lórí ilẹ̀ wọn, èyí tí wọn yóò mú wá fún Jèhófà, yóò di tìrẹ.+ Gbogbo ẹni tí ó mọ́ nínú ilé rẹ lè jẹ ẹ́. 14  “Kí olúkúlùkù ohun tí a yà sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì di tìrẹ.+ 15  “Ohun gbogbo tí ó bá ṣí ilé ọlẹ̀,+ nínú gbogbo onírúurú ẹran ara, èyí tí wọn yóò mú wá fún Jèhófà, nínú ènìyàn àti nínú ẹranko, kí wọ́n di tìrẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, láìkùnà, kí o tún àkọ́bí ti aráyé+ rà padà; kí o sì tún àkọ́bí ti ẹranko aláìmọ́ rà padà.+ 16  Kí o sì fi iye owó ìtúnràpadà rẹ̀ láti ẹni oṣù kan sókè tún un rà padà, gẹ́gẹ́ bí iye tí a dá lé e, ṣékélì fàdákà márùn-ún gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́.+ Ó jẹ́ ogún òṣùwọ̀n gérà.+ 17  Kì kì akọ màlúù tí ó jẹ́ àkọ́bí tàbí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó jẹ́ àkọ́bí tàbí àkọ́bí ewúrẹ́ ni kí o má ṣe tún rà padà.+ Wọ́n jẹ́ ohun mímọ́. Ẹ̀jẹ̀+ wọn ni kí o wọ́n sórí pẹpẹ, ọ̀rá wọn ni kí o sì mú rú èéfín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun fún òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ 18  Kí ẹran wọn sì di tìrẹ. Gẹ́gẹ́ bí igẹ̀ ọrẹ ẹbọ fífì àti gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ̀ ọ̀tún, kí ó di tìrẹ.+ 19  Gbogbo ọrẹ+ mímọ́, tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà, ni mo ti fi fún ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a yọ̀ǹda fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Ó jẹ́ májẹ̀mú iyọ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin níwájú Jèhófà fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ.”+ 20  Jèhófà sì ń bá a lọ láti wí fún Áárónì pé: “Ìwọ kì yóò ní ogún nínú ilẹ̀ wọn, kò sì sí ìpín kankan tí yóò di tìrẹ láàárín wọn.+ Èmi ni ìpín rẹ àti ogún rẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 21  “Àti fún àwọn ọmọ Léfì, wò ó! mo ti fún wọn ní gbogbo ìdá mẹ́wàá+ ní Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún ní ìdápadà fún iṣẹ́ ìsìn wọn tí wọ́n ń ṣe, iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé. 22  Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má sì ṣe sún mọ́ àgọ́ ìpàdé mọ́ láti fa ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ara wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kú.+ 23  Kí àwọn ọmọ Léfì fúnra wọn sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìpàdé, àwọn sì ni kí ó dáhùn fún ìṣìnà+ wọn. Ó jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìran-ìran yín pé wọn kì yóò ní ogún láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 24  Nítorí ìdá mẹ́wàá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí wọn yóò fi ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ, ni mo ti fi fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí ogún. Ìdí nìyẹn tí mo fi wí fún wọn pé, ‘Wọn kì yóò ní ogún láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+ 25  Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 26  “Kí o sì bá àwọn ọmọ Léfì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ó máa gba ìdá mẹ́wàá láti ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, èyí tí mo ti fi fún yín láti ọwọ́ wọn fún ogún yín,+ láti inú rẹ̀, kí ẹ sì máa ṣe ìtọrẹ ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá+ náà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Jèhófà. 27  Kí a sì ṣírò rẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ yín, bí ọkà ilẹ̀ ìpakà+ àti bí ọ̀pọ̀ yanturu àmújáde ibi ìfúntí wáìnì tàbí ti òróró. 28  Lọ́nà yìí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú yóò máa fi ọrẹ ṣe ìtọrẹ fún Jèhófà láti inú gbogbo ìdá mẹ́wàá yín tí ẹ̀yin yóò máa gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti inú wọn ni kí ẹ sì ti fún Áárónì àlùfáà ní ọrẹ fún Jèhófà. 29  Láti inú gbogbo ẹ̀bùn tí a bá fún yín, ẹ̀yin yóò ṣe ìtọrẹ gbogbo onírúurú ọrẹ fún Jèhófà, lára èyí tí ó dára jù lọ nínú rẹ̀,+ gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ó jẹ́ mímọ́ láti inú wọn.’ 30  “Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá ṣe ìtọrẹ èyí tí ó dára jù lọ lára wọn,+ dájúdájú, nígbà náà a óò ṣírò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àmújáde ilẹ̀ ìpakà àti gẹ́gẹ́ bí àmújáde ibi ìfúntí wáìnì tàbí ti òróró. 31  Kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi gbogbo, ẹ̀yin àti agbo ilé yín, nítorí pé ó jẹ́ owó ọ̀yà yín ní ìdápadà fún iṣẹ́ ìsìn yín nínú àgọ́ ìpàdé.+ 32  Kí ẹ má sì fa ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ara yín nítorí rẹ̀ nígbà tí ẹ bá ṣe ìtọrẹ èyí tí ó dára jù lọ láti inú wọn, kí ẹ má sì sọ àwọn ohun mímọ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìmọ́, kí ẹ má bàa kú.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé