Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 16:1-50

16  Kórà+ ọmọkùnrin Ísárì,+ ọmọkùnrin Kóhátì,+ ọmọkùnrin Léfì,+ sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde, pa pọ̀ pẹ̀lú Dátánì+ àti Ábírámù+ àwọn ọmọkùnrin Élíábù,+ àti Ónì ọmọkùnrin Péléétì, àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì.+  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde níwájú Mósè, àwọn àti àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìjòyè àpéjọ, àwọn tí a ń fi ọlá àṣẹ pè nínú ìpàdé, àwọn ọkùnrin olókìkí.  Nítorí náà, wọ́n pe ara wọn jọpọ̀ lòdì sí+ Mósè àti Áárónì, wọ́n sì wí fún wọn pé: “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, nítorí pé gbogbo àpéjọ ni ó jẹ́ mímọ́+ ní àtòkèdélẹ̀ wọn, Jèhófà sì wà ní àárín wọn.+ Kí wá ni ìdí tí ẹ fi gbé ara yín sókè lórí ìjọ Jèhófà?”+  Nígbà tí Mósè gbọ́, ní kíá, ó dojú bolẹ̀.  Nígbà náà ni ó bá Kórà àti gbogbo àpéjọ rẹ̀ pátá sọ̀rọ̀, pé: “Ní òwúrọ̀, Jèhófà yóò sọ ẹni tí ó jẹ́ tirẹ̀+ di mímọ̀ àti ẹni tí ó jẹ́ mímọ́+ àti ẹni tí ó gbọ́dọ̀ sún mọ́ ọn,+ ẹni yòówù tí ó bá sì yàn+ ni yóò sún mọ́ ọn.  Ẹ ṣe èyí: Ẹ mú àwọn ìkóná+ fún ara yín, Kórà àti gbogbo àpéjọ rẹ̀ pátá,+  kí ẹ sì fi iná sínú wọn, kí ẹ sì fi tùràrí sórí wọn níwájú Jèhófà lọ́la, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin náà tí Jèhófà yóò yàn,+ òun ni ẹni mímọ́. “Ó tó gẹ́ẹ́ yín, ẹ̀yin ọmọ Léfì!”+  Mósè sì ń bá a lọ láti wí fún Kórà pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Léfì.  Ohun kékeré bẹ́ẹ̀ ha ni lójú yín pé Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti yà yín sọ́tọ̀+ kúrò nínú àpéjọ Ísírẹ́lì láti mú yín wá síwájú ara rẹ̀ láti máa bá iṣẹ́ ìsìn àgọ́ ìjọsìn Jèhófà lọ àti láti máa dúró níwájú àpéjọ láti ṣe ìránṣẹ́ fún wọn,+ 10  tí ó sì mú ìwọ àti gbogbo àwọn arákùnrin rẹ ọmọ Léfì pẹ̀lú rẹ sún mọ́ tòsí? Nítorí náà, ẹ̀yin yóò ha tún gbìyànjú láti gba iṣẹ́ àlùfáà síkàáwọ́?+ 11  Nítorí ìdí yẹn, ìwọ àti gbogbo àpéjọ rẹ tí ń kóra jọpọ̀ ti dojú ìjà kọ Jèhófà.+ Ní ti Áárónì, kí ni ó jẹ́ tí ẹ̀yin fi ní láti kùn sí i?”+ 12  Lẹ́yìn náà, Mósè ránṣẹ́ pe Dátánì àti Ábírámù+ àwọn ọmọkùnrin Élíábù, ṣùgbọ́n wọ́n wí pé: “Àwa kì yóò gòkè wá!+ 13  Ohun kékeré tó bẹ́ẹ̀ ha ni pé o ti mú wa gòkè wá láti inú ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin láti fi ikú pa wá ní aginjù,+ pé o tún gbìyànjú láti ṣe bí ọmọ aládé lórí wa dé góńgó?+ 14  Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìwọ kò tíì mú wa wá sí ilẹ̀ èyíkéyìí tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin,+ tí o lè fi fún wa ní ogún ti pápá àti ọgbà àjàrà. Ṣé ojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni o fẹ́ yọ jáde ni? Àwa kì yóò gòkè wá!” 15  Látàrí èyí, Mósè bínú gidigidi, ó sì wí fún Jèhófà pé: “Má ṣe bojú wo ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn. Èmi kò gba akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan lọ́wọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò pa ọ̀kan nínú wọn lára.”+ 16  Nígbà náà ni Mósè wí fún Kórà+ pé: “Ìwọ àti gbogbo àpéjọ rẹ, ẹ pésẹ̀ síwájú Jèhófà,+ ìwọ àti àwọn àti Áárónì, lọ́la. 17  Kí olúkúlùkù sì mú ìkóná rẹ̀, kí ẹ sì fi tùràrí sórí wọn, kí olúkúlùkù sì mú ìkóná rẹ̀ wá síwájú Jèhófà, àádọ́ta-lérúgba ìkóná, àti ìwọ àti Áárónì olúkúlùkù pẹ̀lú ìkóná rẹ̀.” 18  Nítorí náà, olúkúlùkù mú ìkóná rẹ̀, wọ́n sì fi iná sí wọn, wọ́n sì fi tùràrí sórí wọn, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé pa pọ̀ pẹ̀lú Mósè àti Áárónì. 19  Nígbà tí Kórà kó gbogbo àpéjọ+ náà jọ lòdì sí wọn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, nígbà náà ni ògo Jèhófà fara han gbogbo àpéjọ náà.+ 20  Jèhófà bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀ wàyí, pé: 21  “Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀+ kúrò ní àárín àpéjọ yìí, kí èmi lè pa wọ́n run+ pátápátá ní ìṣẹ́jú akàn.” 22  Látàrí èyí, wọ́n dojú bolẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Ọlọ́run, Ọlọ́run àwọn ẹ̀mí gbogbo onírúurú ẹran ara,+ ọkùnrin kan ṣoṣo yóò ha ṣẹ̀ tí ìkannú rẹ yóò sì ru sí gbogbo àpéjọ pátá?”+ 23  Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 24  “Bá àpéjọ sọ̀rọ̀, pé, ‘Ẹ kúrò ní àyíká ibùgbé Kórà, Dátánì àti Ábírámù!’”+ 25  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè dìde, ó sì tọ Dátánì àti Ábírámù lọ, àwọn àgbà ọkùnrin+ Ísírẹ́lì sì bá a lọ. 26  Nígbà náà ni ó bá àpéjọ sọ̀rọ̀, pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kúrò níwájú àgọ́ àwọn ọkùnrin burúkú wọ̀nyí, kí ẹ má sì fara kan ohunkóhun tí ó jẹ́ tiwọn,+ kí a má bàa gbá yín lọ nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” 27  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n kúrò níwájú ibùgbé Kórà, Dátánì àti Ábírámù, láti ìhà gbogbo, Dátánì àti Ábírámù sì jáde wá, wọ́n mú ìdúró wọn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn,+ pa pọ̀ pẹ̀lú aya wọn, àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ wọn kéékèèké. 28  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Nípa èyí ni ẹ̀yin yóò fi mọ̀ pé Jèhófà ni ó rán mi láti ṣe gbogbo iṣẹ́ wọ̀nyí,+ pé kì í ṣe láti inú ọkàn-àyà+ ara mi: 29  Bí ó bá jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ikú gbogbo aráyé ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò fi kú àti pẹ̀lú ìyà gbogbo aráyé ni a ó fi mú ìyà wá sórí wọn,+ nígbà náà, kì í ṣe Jèhófà ni ó rán mi.+ 30  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ ohun kan tí a dá tí Jèhófà yóò dá,+ tí ilẹ̀ yóò sì la ẹnu rẹ̀ tí yóò sì gbé wọn mì+ àti ohun gbogbo tí ó jẹ́ tiwọn, dájúdájú, tí wọn yóò sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù+ láàyè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti hùwà àìlọ́wọ̀+ sí Jèhófà.” 31  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó ti parí sísọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ sí pínyà.+ 32  Ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì àti agbo ilé wọn àti gbogbo ìran ènìyàn tí ó jẹ́ ti Kórà àti gbogbo àwọn ẹrù.+ 33  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù láàyè, àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tiwọn, ilẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ tí wọ́n fi ṣègbé kúrò láàárín ìjọ.+ 34  Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó yí wọn ká sì sá lọ nítorí ìlọgun wọn, nítorí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Àwa ń fòyà pé ilẹ̀ lè gbé wa mì!”+ 35  Iná sì jáde wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin tí ń sun tùràrí+ run. 36  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 37  “Sọ fún Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà pé kí ó mú àwọn ìkóná+ láti àárín àgbáàràgbá iná náà, ‘Kí o sì tú iná náà ká sọ́hùn-ún; nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́, 38  àní ìkóná àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó ṣẹ̀ sí ọkàn+ ara wọn. Kí wọ́n sì fi wọ́n ṣe àwọn àwo irin fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun àfibo pẹpẹ,+ nítorí pé wọ́n mú wọn wá síwájú Jèhófà, tí wọ́n fi di mímọ́; kí wọ́n sì wà bí àmì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+ 39  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Élíásárì àlùfáà mú àwọn ìkóná+ bàbà náà, èyí tí àwọn tí ó jóná mú wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n rọ ohun àfibo pẹpẹ, 40  gẹ́gẹ́ bí ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ọkùnrin àjèjì + kankan tí kì í ṣe ọmọ Áárónì má ṣe sún mọ́ tòsí láti mú èéfín tùràrí rú níwájú Jèhófà,+ kí ẹnì kankan má bàa sì dà bí Kórà àti àpéjọ+ rẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti bá a sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Mósè. 41  Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e gan-an, gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì,+ pé: “Ẹ̀yin, ẹ ti fi ikú pa àwọn ènìyàn Jèhófà.” 42  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àpéjọ náà ti péjọ pọ̀ lòdì sí Mósè àti Áárónì, wọ́n wá yíjú síhà àgọ́ ìpàdé; sì wò ó! àwọsánmà bò ó, ògo Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn.+ 43  Mósè àti Áárónì sì tẹ̀ síwájú láti lọ síwájú àgọ́ ìpàdé.+ 44  Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 45  “Ẹ dìde kúrò ní àárín àpéjọ yìí, kí èmi lè pa wọ́n run pátápátá ní ìṣẹ́jú akàn.”+ Látàrí èyí, wọ́n dojú bolẹ̀.+ 46  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè wí fún Áárónì pé: “Mú ìkóná kí o sì fi iná láti orí pẹpẹ sínú rẹ̀,+ kí o sì fi tùràrí sí i, kí o sì lọ sọ́dọ̀ àpéjọ náà ní wéréwéré, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn,+ nítorí pé ìkannú náà ti jáde lọ láti ojú Jèhófà.+ Ìyọnu àjàkálẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀!” 47  Lójú-ẹsẹ̀, Áárónì mú un, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti sọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ sáàárín ìjọ; sì wò ó! ìyọnu àjàkálẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn náà. Nítorí náà, ó fi tùràrí sí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ètùtù fún àwọn ènìyàn náà. 48  Ó sì ń bá a nìṣó ní dídúró láàárín àwọn òkú àti àwọn alààyè.+ Òjòjò àrànkálẹ̀ náà ni a dá dúró ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.+ 49  Àwọn tí ó sì kú nínú òjòjò àrànkálẹ̀ náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin, yàtọ̀ sí àwọn tí ó ti kú ní tìtorí Kórà. 50  Nígbà tí Áárónì padà sọ́dọ̀ Mósè nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, òjòjò àrànkálẹ̀ náà ni a ti dá dúró.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé