Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 15:1-41

15  Jèhófà sì bá Mósè sọ̀rọ̀ síwájú sí i, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ bá wọ ilẹ̀ ibi gbígbé yín tí èmi yóò fi fún yín,+  tí ẹ sì rú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà,+ ọrẹ ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ láti san àkànṣe ẹ̀jẹ́ tàbí àfínnúfíndọ̀ṣe+ tàbí nígbà àwọn àjọyọ̀+ yín abágbàyí, kí ẹ bàa lè mú òórùn amáratuni jáde sí Jèhófà,+ lára ọ̀wọ́ ẹran tàbí lára agbo ẹran;  kí ẹni tí ń mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá sì tún mú ọrẹ ẹbọ ọkà oníyẹ̀fun kíkúnná+ wá fún Jèhófà, ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà, tí a fi ìlàrin òṣùwọ̀n hínì òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.  Kí o sì fi wáìnì rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu,+ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì, pa pọ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun tàbí fún ẹbọ akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan.  Tàbí fún àgbò, kí o rú ọrẹ ẹbọ ọkà ìdá méjì nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná, tí a fi òróró ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.  Kí o sì mú wáìnì wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu, ìdá mẹ́ta òṣùwọ̀n hínì, gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni sí Jèhófà.  “‘Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé akọ láti inú ọ̀wọ́ ẹran ni o fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun+ tàbí ẹbọ láti san àkànṣe ẹ̀jẹ́+ tàbí àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà,+  kí ẹni náà tún mú wá pa pọ̀ pẹ̀lú akọ láti inú ọ̀wọ́ ẹran náà, ọrẹ ẹbọ ọkà+ ìdá mẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná, tí a fi ìdajì òṣùwọ̀n hínì òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. 10  Kí o sì mú wáìnì wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu,+ ìdajì òṣùwọ̀n hínì, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà.+ 11  Báyìí ni kí a ṣe é fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan tàbí fún àgbò kọ̀ọ̀kan tàbí fún orí kan lára àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí lára àwọn ewúrẹ́. 12  Iye yòówù tí ì báà jẹ́ tí ẹ fi rúbọ, báyìí ni kí ẹ ṣe fún ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iye wọn. 13  Kí olúkúlùkù ọmọ ìbílẹ̀ fi ìwọ̀nyí rúbọ ní ọ̀nà yìí ní mímú ọrẹ ẹbọ àfinásun wá, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà. 14  “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín tàbí ẹnì kan tí ó wà ní àárín yín ní ìran-ìran yín, kí ó sì rú ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí ó ṣe.+ 15  Ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ara ìjọ àti àwọn àtìpó tí ń ṣe àtìpó yóò ní ìlànà àgbékalẹ̀ kan.+ Yóò jẹ́ ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ìran-ìran yín. Kí àwọn àtìpó jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú yín níwájú Jèhófà.+ 16  Òfin kan àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ kan ni kí ó wà fún yín àti fún àtìpó tí ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín.’”+ 17  Jèhófà sì ń bá a lọ láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 18  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí èmi yóò mú yín lọ,+ 19  kí ó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé nígbà tí ẹ bá jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ ilẹ̀ náà,+ kí ẹ mú ọrẹ wá fún Jèhófà. 20  Kí ẹ ṣe ìtọrẹ àkọ́so+ ẹ̀wẹ́ ọkà yín gẹ́gẹ́ bí àwọn àkàrà onírìísí òrùka. Bí ọrẹ ti ilẹ̀ ìpakà ni ọ̀nà tí ẹ ó gbà fi í ṣe ìtọrẹ. 21  Kí ẹ fún Jèhófà lára àkọ́so ẹ̀wẹ́ ọkà yín gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ní gbogbo ìran-ìran yín. 22  “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ṣe àṣìṣe, tí ẹ kò sì pa gbogbo àṣẹ+ wọ̀nyí mọ́, tí Jèhófà ti sọ fún Mósè, 23  gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún yín nípasẹ̀ Mósè láti ọjọ́ náà tí Jèhófà pàṣẹ àti láti ìgbà náà lọ fún ìran-ìran yín, 24  nígbà náà, yóò ṣẹlẹ̀ pé bí a bá ti ṣe é jì nnà sí ojú àpéjọ nípa èèṣì, nígbà náà, kí gbogbo àpéjọ fi ẹgbọrọ akọ màlúù kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun fún òórùn amáratuni sí Jèhófà, àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é,+ àti ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 25  Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù+ fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a ó sì dárí rẹ̀ jì wọ́n; nítorí pé àṣìṣe+ ni, àwọn, ní tiwọn, sì mú ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá síwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ wọn fún àṣìṣe wọn. 26  A ó sì dárí rẹ̀ ji+ gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín wọn, nítorí pé gbogbo àwọn ènìyàn náà ṣèèṣì ṣe é ni. 27  “‘Bí ọkàn èyíkéyìí bá sì ṣèèṣì+ dẹ́ṣẹ̀, nígbà náà, kí ó mú abo ewúrẹ́ ọlọ́dún kan wá fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.+ 28  Kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún ọkàn náà tí ó ṣe àṣìṣe nípa dídá ẹ̀ṣẹ̀ kan láìmọ̀ọ́mọ̀ níwájú Jèhófà, kí ó bàa lè ṣe ètùtù rẹ̀, a ó sì dárí rẹ̀ jì  í.+ 29  Ní ti ọmọ ìbílẹ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àtìpó tí ń ṣe àtìpó ní àárín wọn, òfin kan ni kí ó wà fún yín ní ti ṣíṣe ohun kan láìmọ̀ọ́mọ̀.+ 30  “‘Ṣùgbọ́n ọkàn náà tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀+ ṣe nǹkan, yálà ọmọ ìbílẹ̀ ni tàbí àtìpó ni, tí ó ń sọ̀rọ̀ sí Jèhófà tèébútèébú,+ nínú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ọkàn náà ni kí a ké kúrò láàárín àwọn ènìyàn rẹ̀.+ 31  Nítorí pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni ó ti tẹ́ńbẹ́lú,+ àṣẹ rẹ̀ ni ó sì ti rú,+ ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò láìsí àní-àní.+ Ìṣìnà òun fúnra rẹ̀ wà lórí rẹ̀.’”+ 32  Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá a lọ ní aginjù, nígbà kan wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣa igi jọ ní ọjọ́ sábáàtì.+ 33  Nígbà náà ni àwọn tí ó rí i tí ń ṣa igi jọ mú un tọ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ wá. 34  Nítorí náà, wọ́n fi í sínú ìhámọ́,+ nítorí pé a kò tíì sọ ọ́ lọ́nà tí ó ṣe kedere ohun tí a ó ṣe sí i. 35  Nígbà tí ó ṣe, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Láìsí àní-àní, ọkùnrin náà ni kí a fi ikú pa,+ kí gbogbo àpéjọ sọ ọ́ ní òkúta ní òde ibùdó.”+ 36  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo àpéjọ mú un jáde wá sí òde ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta tí ó fi kú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 37  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ èyí fún Mósè pé: 38  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì wí fún wọn pé kí wọ́n ṣe ìṣẹ́tí fún ara wọn sétí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ wọn ní gbogbo ìran-ìran wọn, kí wọ́n sì fi okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sókè ìṣẹ́tí apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ náà,+ 39  ‘Kí ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ́tí fún yín, kí ẹ sì rí i, kí ẹ sì rántí gbogbo àṣẹ+ Jèhófà, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́, kí ẹ má sì máa lọ káàkiri ní títọ ọkàn-àyà yín àti ojú+ yín lẹ́yìn, èyí tí ẹ ń tẹ̀ lé nínú ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe.+ 40  Ète rẹ̀ ni pé kí ẹ lè rántí, kí ẹ sì pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ dájúdájú, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run+ yín ní tòótọ́. 41  Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Íjíbítì wá kí n bàa lè fi ara mi hàn ní Ọlọ́run yín.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé