Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 14:1-45

14  Nígbà náà ni gbogbo àpéjọ náà gbé ohùn wọn sókè, àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ ní títú ohùn wọn jáde, wọ́n sì ń sunkún+ ní gbogbo òru yẹn.  Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mósè àti Áárónì,+ gbogbo àpéjọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí wọn pé: “Àwa ì bá kúkú ti kú ní ilẹ̀ Íjíbítì, tàbí àwa ì bá kúkú ti kú ní aginjù yìí!  Èé sì ti ṣe tí Jèhófà fi ń mú wa bọ̀ ní ilẹ̀ yìí láti tipa idà ṣubú?+ Àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa kéékèèké yóò di ohun tí a piyẹ́.+ Kò ha sàn fún wa láti padà sí Íjíbítì?”+  Wọ́n tilẹ̀ ń sọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ẹ jẹ́ kí a yan olórí sípò, kí a sì padà sí Íjíbítì!”+  Látàrí èyí, Mósè àti Áárónì dojú bolẹ̀+ níwájú gbogbo ìjọ àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì+ àti Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè,+ tí wọ́n wà lára àwọn tí wọ́n ṣe amí ilẹ̀ náà, sì gbọn ẹ̀wù wọn ya,+  wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ èyí fún gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ilẹ̀ náà tí a là kọjá láti ṣe amí rẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára gidigidi.+  Bí Jèhófà bá ní inú dídùn sí wa,+ dájúdájú, nígbà náà òun yóò mú wa wá sínú ilẹ̀ yìí, yóò sì fi í fún wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.+  Kì kì kí ẹ má ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà;+ àti ẹ̀yin, kí ẹ má bẹ̀rù àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà,+ nítorí oúnjẹ ni wọ́n jẹ́ fún wa. Ibi ààbò wọ́n ti ṣí kúrò lórí wọn,+ Jèhófà sì wà pẹ̀lú wa.+ Ẹ má bẹ̀rù wọn.”+ 10  Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo àpéjọ náà sọ̀rọ̀ nípa sísọ wọ́n ní òkúta.+ Ògo Jèhófà sì fara hàn lórí àgọ́ ìpàdé sí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 11  Níkẹyìn, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Yóò ti pẹ́ tó+ tí àwọn ènìyàn yìí yóò máa hùwà àìlọ́wọ̀+ sí mi, yóò sì ti pẹ́ tó tí wọn kì yóò ní ìgbàgbọ́ nínú mi fún gbogbo iṣẹ́ àmì tí mo mú ṣe láàárín wọn?+ 12  Jẹ́ kí n fi àjàkálẹ̀ àrùn kọlù wọ́n, kí n sì lé wọn lọ, sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè tí ó tóbi, tí ó sì jẹ́ alágbára ńlá jù wọ́n lọ.”+ 13  Ṣùgbọ́n Mósè wí fún Jèhófà pé: “Nígbà náà ni àwọn ọmọ Íjíbítì yóò gbọ́ dájúdájú pé o ti mú àwọn ènìyàn yìí gòkè wá láti àárín wọn nípa agbára rẹ.+ 14  Dájúdájú, wọn yóò sọ ọ́ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Wọ́n ti gbọ́ pé ìwọ ni Jèhófà láàárín àwọn ènìyàn yìí,+ ẹni tí ó ti fara hàn lójúkojú.+ Ìwọ ni Jèhófà, àwọsánmà rẹ sì ń dúró lórí wọn, ìwọ sì ń lọ níwájú wọn nínú ọwọ̀n àwọsánmà ní ọ̀sán àti nínú ọwọ̀n iná ní òru.+ 15  Bí ìwọ bá fi ikú pa àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣoṣo,+ nígbà náà, àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gbọ́ nípa òkìkí rẹ dájúdájú yóò sọ èyí, 16  ‘Nítorí tí Jèhófà kò lè mú àwọn ènìyàn yìí wá sínú ilẹ̀ tí ó búra fún wọn nípa rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n ní aginjù.’+ 17  Nísinsìnyí, jọ̀wọ́, kí agbára rẹ di ńlá,+ Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí o ti sọ, pé, 18  ‘Jèhófà, ó ń lọ́ra láti bínú,+ ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+ ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá jì ,+ ṣùgbọ́n láìsí àní-àní kì í dáni sí láìjẹni-níyà,+ ní mímú ìyà fún ìṣìnà àwọn baba wá sórí àwọn ọmọ, wá sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin.’+ 19  Jọ̀wọ́, dárí ìṣìnà àwọn ènìyàn yìí jì gẹ́gẹ́ bí títóbi inú-rere rẹ onífẹ̀ẹ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí o sì ti dárí ji àwọn ènìyàn yìí láti Íjíbítì títí di ìsinsìnyí.”+ 20  Nígbà náà ni Jèhófà wí pé: “Mo dárí jì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.+ 21  Àti pé, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí mo ti ń bẹ, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò kún fún ògo Jèhófà.+ 22  Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọkùnrin náà tí ó ti ń rí ògo+ mi àti àwọn iṣẹ́ àmì+ mi tí mo ti ṣe ní Íjíbítì àti ní aginjù, síbẹ̀ tí wọ́n sì ń dán mi wò+ ní ìgbà mẹ́wàá yìí, tí wọn kò sì fetí sí ohùn mi,+ 23  kì yóò rí ilẹ̀ náà tí mo búra fún àwọn baba wọn nípa rẹ̀ láé, bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tí ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí mi kì yóò rí i.+ 24  Ní ti ìránṣẹ́ mi Kálébù,+ nítorí pé ẹ̀mí tí ó yàtọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó sì ń bá a nìṣó ní títọ̀ mí lẹ́yìn ní kíkún,+ dájúdájú, èmi yóò mú un wá sí ilẹ̀ náà níbi tí ó lọ, ọmọ rẹ̀ yóò sì gbà á.+ 25  Nígbà tí àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì+ ń gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀, kí ẹ yí padà lọ́la, kí ẹ sì ṣí láti lọ sí aginjù gba ti Òkun Pupa.”+ 26  Jèhófà sì ń bá a lọ ní bíbá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé: 27  “Yóò ti pẹ́ tó tí àpéjọ yìí tí ó jẹ́ ti ibi yóò máa ṣe ìkùnsínú yìí tí wọ́n ń bá nìṣó sí mi?+ Mo ti gbọ́ ìkùnsínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n ń kùn sí mi.+ 28  Sọ fún wọn pé, ‘“Bí mo ti ń bẹ,” ni àsọjáde Jèhófà, “bí èmi kò bá ní ṣe sí yín gan-an lọ́nà yẹn gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe sọ ní etí mi!+ 29  Aginjù yìí ni òkú yín yóò ṣubú sí,+ bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ lára yín nínú gbogbo iye yín láti ẹni ogún ọdún sókè, ẹ̀yin tí ẹ ti kùn sí mi.+ 30  Ní ti yín, ẹ̀yin kì yóò wọ ilẹ̀ náà tí mo gbé ọwọ́+ mi sókè ní ìbúra láti máa gbé pẹ̀lú yín, àyàfi Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.+ 31  “‘“Àwọn ọmọ yín kéékèèké tí ẹ sì sọ pé yóò di ohun tí a piyẹ́,+ dájúdájú, àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wọlé pẹ̀lú, ní tòótọ́ wọn yóò sì mọ ilẹ̀ náà tí ẹ ti kọ̀.+ 32  Ṣùgbọ́n òkú ẹ̀yin alára yóò ṣubú ní aginjù+ yìí. 33  Àwọn ọmọ yín yóò sì di olùṣọ́ àgùntàn ní aginjù+ fún ogójì ọdún, wọn yóò sì ní láti dáhùn fún àwọn ìwà àgbèrè+ yín, títí òkú yín yóò fi wá sí òpin wọn ní aginjù.+ 34  Nípa iye àwọn ọjọ́ tí ẹ fi ṣe amí ilẹ̀ náà, ogójì ọjọ́,+ ọjọ́ kan fún ọdún kan,+ ọjọ́ kan fún ọdún kan, ni ẹ ó fi dáhùn fún àwọn ìṣìnà yín fún ogójì ọdún,+ níwọ̀n bí ẹ ó ti mọ ohun tí kíkọ tí ẹ kẹ̀yìn sí mi túmọ̀ sí.+ 35  “‘“Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀ bí kì í bá ṣe ohun tí èmi yóò ṣe sí gbogbo àpéjọ+ yìí tí ó jẹ́ ti ibi nìyí, àwọn tí ó ti kóra jọpọ̀ lòdì sí mi: Aginjù yìí ni wọn yóò ti wá sí òpin wọn, ibẹ̀ ni wọn yóò sì kú sí.+ 36  Àti àwọn ọkùnrin tí Mósè rán lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú kí gbogbo àpéjọ náà kùn sí i nígbà tí wọ́n padà, nípa mímú ìròyìn búburú wá lòdì sí ilẹ̀ náà,+ 37  bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ọkùnrin tí ń mú ìròyìn búburú wá nípa ilẹ̀ náà yóò tipa òjòjò àrànkálẹ̀ kú níwájú Jèhófà.+ 38  Ṣùgbọ́n Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì àti Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè, lára àwọn ọkùnrin tí ó lọ ṣe amí ilẹ̀ náà, dájúdájú yóò máa bá a nìṣó láti wà láàyè.”’”+ 39  Nígbà tí Mósè bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ̀fọ̀ gidigidi.+ 40  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, wọ́n sì gbìyànjú láti gòkè lọ sí orí òkè ńlá náà, wọ́n sọ pé: “Àwa nìyí, a sì ní láti gòkè lọ sí ibi tí Jèhófà mẹ́nu kàn. Nítorí pé a ti ṣẹ̀.”+ 41  Ṣùgbọ́n Mósè wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ré àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà kọjá?+ Ṣùgbọ́n ìyẹn kì yóò kẹ́sẹ járí. 42  Ẹ má gòkè lọ, nítorí pé Jèhófà kò sí ní àárín yín, kí a má bàa ṣẹ́gun yín níwájú àwọn ọ̀tá yín.+ 43  Nítorí àwọn ọmọ Ámálékì àti àwọn ọmọ Kénáánì wà níbẹ̀ níwájú yín;+ ẹ̀yin yóò sì tipa idà ṣubú dájúdájú, nítorí, fún ìdí náà pé ẹ yí padà kúrò ní títọ Jèhófà lẹ́yìn, Jèhófà kì yóò máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú yín.”+ 44  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n kùgbù láti gòkè lọ sí orí òkè ńlá náà,+ ṣùgbọ́n àpótí májẹ̀mú Jèhófà àti Mósè kò kúrò ní àárín ibùdó.+ 45  Nígbà náà ni àwọn ọmọ Ámálékì+ àti àwọn ọmọ Kénáánì tí ń gbé ní òkè ńlá yẹn sọ̀ kalẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọlù wọ́n, tí wọ́n sì ń tú wọn ká títí dé Hóómà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé