Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 13:1-33

13  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Rán àwọn ọkùnrin jáde fún ara rẹ kí wọn lè ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí èmi yóò fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Ẹ óò rán ọkùnrin kan jáde fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ti àwọn baba rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìjòyè+ láàárín wọn.”  Nítorí náà, Mósè rán wọn jáde láti aginjù Páránì+ nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà. Gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ olórí nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ wọn: Nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Ṣámúà ọmọkùnrin Sákúrì;  nínú ẹ̀yà Síméónì, Ṣáfátì ọmọkùnrin Hórì;  nínú ẹ̀yà Júdà, Kálébù+ ọmọkùnrin Jéfúnè;  nínú ẹ̀yà Ísákárì, Ígálì ọmọkùnrin Jósẹ́fù;  nínú ẹ̀yà Éfúráímù, Hóṣéà+ ọmọkùnrin Núnì;  nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Pálítì ọmọkùnrin Ráfù; 10  nínú ẹ̀yà Sébúlúnì, Gádíélì ọmọkùnrin Sódì; 11  nínú ẹ̀yà Jósẹ́fù,+ fún ẹ̀yà Mánásè,+ Gádáì ọmọkùnrin Súsì; 12  nínú ẹ̀yà Dánì, Ámíélì ọmọkùnrin Gémálì; 13  nínú ẹ̀yà Áṣérì, Sẹ́túrì ọmọkùnrin Máíkẹ́lì; 14  nínú ẹ̀yà Náfútálì, Náhíbì ọmọkùnrin Fófísì; 15  nínú ẹ̀yà Gádì, Géúélì ọmọkùnrin Mákì. 16  Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí Mósè rán láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Mósè sì ń bá a lọ láti pe Hóṣéà ọmọkùnrin Núnì ní Jèhóṣúà.+ 17  Nígbà tí Mósè ń rán wọn láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ gòkè níhìn-ín lọ sí Négébù,+ kí ẹ sì gòkè lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá.+ 18  Kí ẹ sì rí ohun tí ilẹ̀ náà jẹ́+ àti àwọn ènìyàn tí ń gbé lórí rẹ̀, bóyá wọ́n jẹ́ alágbára tàbí aláìlera, bóyá wọ́n kéré níye tàbí wọ́n pọ̀; 19  àti ohun tí ilẹ̀ náà jẹ́ nínú èyí tí wọ́n ń gbé, bóyá ó dára tàbí ó burú, àti ohun tí àwọn ìlú ńlá náà jẹ́ nínú èyí tí wọ́n ń gbé, bóyá ó wà nínú àwọn ibi ìdósí tàbí nínú odi; 20  àti ohun tí ilẹ̀ náà jẹ́, bóyá ọlọ́ràá ni tàbí aláìlọ́ràá,+ bóyá àwọn igi wà nínú rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kí ẹ sì fi ara yín hàn ní onígboyà,+ kí ẹ sì mú lára èso ilẹ̀ náà.” Wàyí o, àwọn ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ àkọ́pọ́n èso àjàrà.+ 21  Nítorí náà, wọ́n gòkè lọ, wọ́n sì ṣe amí ilẹ̀ náà láti aginjù Síínì+ dé Réhóbù+ dé àtiwọ Hámátì.+ 22  Nígbà tí wọ́n gòkè lọ sí Négébù,+ nígbà náà ni wọ́n dé Hébúrónì.+ Wàyí o, Áhímánì, Ṣéṣáì àti Tálímáì,+ àwọn tí a bí fún Ánákì,+ wà níbẹ̀. Ó ṣẹlẹ̀ pé, a ti tẹ Hébúrónì+ dó ní ọdún méje ṣáájú Sóánì+ ti Íjíbítì. 23  Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá ti Éṣíkólì,+ nígbà náà ni wọ́n tẹ̀ síwájú láti gé ọ̀mùnú kan tí ó ní òṣùṣù èso àjàrà+ kan níbẹ̀. Wọ́n sì fi ọ̀pá gbọọrọ kan gbé e nípasẹ̀ méjì  lára àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì mú díẹ̀ lára àwọn pómégíránétì+ àti díẹ̀ lára àwọn ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24  Wọ́n pe ibẹ̀ ní àfonífojì  olójú ọ̀gbàrá ti Éṣíkólì,+ tìtorí òṣùṣù tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gé láti ibẹ̀. 25  Níkẹyìn, ní òpin ogójì  ọjọ́,+ wọ́n padà dé lẹ́nu ṣíṣe amí ilẹ̀ náà. 26  Nítorí náà, wọ́n rìn, wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Mósè àti Áárónì àti gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù Páránì, ní Kádéṣì.+ Wọ́n sì wá mú ọ̀rọ̀ padà wá fún wọn àti fún gbogbo àpéjọ náà, wọ́n sì fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27  Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti ròyìn fún un, wọ́n sì wí pé: “Àwa wọnú ilẹ̀ náà èyí tí o rán wa jáde lọ, ó sì ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin+ ní tòótọ́, èyí sì ni èso rẹ̀.+ 28  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òtítọ́ náà ni pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára, àwọn ìlú ńlá olódi náà sì tóbi gan-an;+ àti pé, a rí àwọn tí a bí fún Ánákì níbẹ̀ pẹ̀lú.+ 29  Àwọn ọmọ Ámálékì+ ń gbé ní ilẹ̀ Négébù,+ àwọn ọmọ Hétì àti àwọn ará Jébúsì+ àti àwọn Ámórì+ sì ń gbé ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá, àwọn ọmọ Kénáánì+ sì ń gbé lẹ́bàá òkun àti lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì.” 30  Nígbà náà ni Kálébù+ gbìyànjú láti mú àwọn ènìyàn náà pa rọ́rọ́ níwájú Mósè, ó sì ń bá a lọ láti sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ tààràtà, ó sì dájú pé a ó gbà á, nítorí pé a lè borí rẹ̀ dájúdájú.”+ 31  Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí ó gòkè lọ pẹ̀lú rẹ̀ wí pé: “Àwa kò lè gòkè lọ láti gbéjà ko àwọn ènìyàn náà, nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.”+ 32  Wọ́n sì ń bá a nìṣó ní mímú ìròyìn búburú+ nípa ilẹ̀ náà tí wọ́n ṣe amí rẹ̀ wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé: “Ilẹ̀ náà, èyí tí a là kọjá láti ṣe amí rẹ̀, jẹ́ ilẹ̀ tí ń jẹ àwọn olùgbé rẹ̀; gbogbo àwọn ọkùnrin tí a sì rí nínú rẹ̀ jẹ́ àwọn ọkùnrin tí ó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.+ 33  A sì rí àwọn Néfílímù níbẹ̀, àwọn ọmọkùnrin Ánákì,+ tí wọ́n wá láti inú àwọn Néfílímù; tó bẹ́ẹ̀ tí a fi dà bí tata ní ojú ara wa, bákan náà ni a sì rí ní ojú wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé