Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Númérì 12:1-16

12  Wàyí o, Míríámù àti Áárónì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ lòdì sí Mósè tìtorí aya tí ó jẹ́ ará Kúṣì tí ó fẹ́, nítorí pé aya tí ó jẹ́ ará Kúṣì ni ó fẹ́.+  Wọ́n sì ń sọ ṣáá pé: “Ṣé kìkì nípasẹ̀ Mósè nìkan ṣoṣo ni Jèhófà ti gbà sọ̀rọ̀ ni? Kò ha ti sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwa pẹ̀lú bí?”+ Jèhófà sì ń fetí sílẹ̀.+  Ọkùnrin náà Mósè sì fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù+ jù lọ nínú gbogbo ènìyàn tí ó wà ní orí ilẹ̀.  Nígbà náà ni Jèhófà sọ fún Mósè àti Áárónì àti Míríámù lójijì pé: “Ẹ jáde lọ, ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, sí àgọ́ ìpàdé.” Nítorí náà, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde lọ.  Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ wá nínú ọwọ̀n àwọsánmà,+ ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, ó sì pe Áárónì àti Míríámù. Látàrí èyí, àwọn méjèèjì jáde lọ.  Ó sì ń bá a lọ wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Bí wòlíì kan bá wà nínú yín fún Jèhófà, yóò jẹ́ nínú ìran+ ni èmi yóò ti sọ ara mi di mímọ̀ fún un. Ojú àlá+ ni èmi yóò ti bá a sọ̀rọ̀.  Ìránṣẹ́ mi Mósè+ kò rí bẹ́ẹ̀! Ìkáwọ́ rẹ̀ ni a fi gbogbo ilé mi sí.+  Ẹnu ko ẹnu ni mo ń bá a sọ̀rọ̀,+ ní títipa báyìí fi hàn án, kì í sì í ṣe nípasẹ̀ àlọ́;+ ìrísí Jèhófà ni ó sì ń rí.+ Kí wá ni ìdí tí ẹ kò fi bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ lòdì sí ìránṣẹ́ mi, lòdì sí Mósè?”+  Ìbínú Jèhófà sì wá gbóná sí wọn, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. 10  Àwọsánmà sì yí kúrò lórí àgọ́ náà, sì wò ó! ẹ̀tẹ̀ tí ó funfun bí ìrì dídì ti bo Míríámù.+ Nígbà náà ni Áárónì yíjú sọ́dọ̀ Míríámù, sì wò ó! ẹ̀tẹ̀+ ti bò ó. 11  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì wí fún Mósè pé: “Dákun, olúwa mi! Jọ̀wọ́, má ṣe ṣírò ẹ̀ṣẹ̀ náà sí wa lọ́rùn, èyí tí a ti fi ìwà òmùgọ hù àti èyí tí a ti dá!+ 12  Jọ̀wọ́, má ṣe jẹ́ kí ó máa bá a lọ ní wíwà bí ẹni tí ó ti kú,+ ẹni tí ẹran ara rẹ̀ ti jẹ dé ìdajì nígbà tí ó ń jáde bọ̀ láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀!” 13  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Jèhófà, pé: “Ọlọ́run, jọ̀wọ́! Mú un lára dá, jọ̀wọ́!”+ 14  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Mósè pé: “Ká ní baba rẹ̀ ni ó tutọ́+ sí i lójú, a kò ha ní tẹ́ ẹ lógo fún ọjọ́ méje bí? Kí a sé e mọ́+ nítorí àrùn fún ọjọ́ méje ní òde ibùdó,+ lẹ́yìn ìgbà náà, kí a sì gbà á wọlé.”+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a sé Míríámù mọ́ nítorí àrùn ní òde ibùdó fún ọjọ́ méje,+ àwọn ènìyàn náà kò sì ṣí kúrò títí a fi gba Míríámù wọlé. 16  Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ènìyàn náà sì ṣí kúrò ní Hásérótì,+ wọ́n sì dó sí aginjù Páránì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé