Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 11:1-35

11  Wàyí o, àwọn ènìyàn náà dà bí àwọn tí ó ní ohun kan tí ó jẹ́ ibi láti ráhùn lé lórí ní etí Jèhófà.+ Nígbà tí Jèhófà gbọ́, ìbínú rẹ̀ wá gbóná, iná kan láti ọ̀dọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí jó wọn, ó sì jó àwọn kan run ní ìkángun ibùdó náà.+  Nígbà tí àwọn ènìyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí Mósè, nígbà náà ni ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà,+ iná náà sì rọlẹ̀.  Orúkọ ibẹ̀ yẹn ni a sì wá pè ní Tábérà,+ nítorí pé iná kan láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ti jó wọn.  Ogunlọ́gọ̀+ onírúurú ènìyàn tí ó wà ní àárín wọ́n sì fi ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan hàn,+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú sì tún bẹ̀rẹ̀ sí sunkún pé: “Ta ni yóò fún wa ní ẹran jẹ?+  Ẹ wo bí a ṣe rántí ẹja tí a máa ń jẹ ní Íjíbítì lọ́fẹ̀ẹ́,+ àwọn apálá àti bàrà olómi àti ewébẹ̀ líìkì àti àlùbọ́sà àti aáyù!  Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ọkàn wa ti gbẹ táútáú. Ojú wa kò rí nǹkan kan rárá bí kò ṣe mánà+ yìí.”  Ó ṣẹlẹ̀ pé, mánà+ náà dà bí irúgbìn ewéko kọriáńdà,+ ìrí rẹ̀ sì dà bí ìrí gọ́ọ̀mù bídẹ́líọ́mù.+  Àwọn ènìyàn náà tàn ká, wọ́n sì kó o,+ wọ́n sì lọ̀ ọ́ nínú ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí wọ́n gún un nínú odó, wọ́n sì sè é nínú ìkòkò ìse-oúnjẹ+ tàbí wọ́n fi í ṣe àkàrà ribiti, adùn rẹ̀ sì wá dà bí adùn àkàrà+ dídùn tí a fi òróró sí.  Nígbà tí ìrì bá sì sọ̀ kalẹ̀ sórí ibùdó ní òru, mánà yóò sọ̀ kalẹ̀ sórí rẹ̀.+ 10  Mósè sì wá gbọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń sunkún nínú ìdílé wọn, olúkúlùkù ọkùnrin ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀. Ìbínú Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbóná+ gidigidi, ó sì burú ní ojú Mósè.+ 11  Nígbà náà ni Mósè wí fún Jèhófà pé: “Èé ṣe tí o fi mú ibi bá ìránṣẹ́ rẹ, èé sì ti ṣe tí èmi kò tíì fi rí ojú rere ní ojú rẹ, ní ti pé o gbé ẹrù gbogbo àwọn ènìyàn yìí lé mi lórí?+ 12  Èmi ni ó ha lóyún gbogbo àwọn ènìyàn yìí bí? Ṣé èmi ni ó bí wọn ni, tí o fi ní láti sọ fún mi pé, ‘Gbé wọn sí oókan àyà+ rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣètọ́jú tí ó jẹ́ akọ ṣe ń gbé ọmọ ẹnu ọmú,’+ lọ sí ilẹ̀ tí o búra nípa rẹ̀ fún àwọn baba ńlá wọn?+ 13  Ibo ni èmi yóò ti rí ẹran fún gbogbo àwọn ènìyàn yìí? Nítorí wọ́n ń bá a nìṣó ní sísunkún sí mi, pé, ‘Fún wa ní ẹran, kí àwa sì jẹ!’ 14  Kò ṣeé ṣe fún mi, ní èmi nìkan, láti gbé gbogbo àwọn ènìyàn yìí, nítorí tí wọ́n wúwo jù fún mi.+ 15  Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ báyìí ni ìwọ yóò ṣe ṣe sí mi ni, jọ̀wọ́ kúkú pa mí dànù,+ bí mo bá ti rí ojú rere ní ojú rẹ, má sì ṣe jẹ́ kí n fojú rí ìyọnu àjálù mi.” 16  Ẹ̀wẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kó àádọ́rin ọkùnrin jọ fún mi nínú àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì,+ àwọn tí o mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àgbà ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn náà àti àwọn onípò àṣẹ láàárín wọn,+ kí o sì mú wọn lọ sí àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ. 17  Èmi yóò sì sọ̀ kalẹ̀+ wá dájúdájú, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ níbẹ̀;+ dájúdájú, èmi yóò mú lára ẹ̀mí+ tí ó wà lára rẹ, èmi yóò sì fi í sára wọn, wọn yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ríru ẹrù àwọn ènìyàn náà, kí ìwọ nìkan ṣoṣo+ má ṣe rù ú. 18  Kí o sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, ‘Ẹ sọ ara yín di mímọ́ fún ọ̀la,+ níwọ̀n bí ẹ̀yin yóò ti jẹ ẹran dájúdájú, nítorí ẹ ti sunkún ní etí Jèhófà,+ pé: “Ta ni yóò fún wa ní ẹran jẹ, nítorí nǹkan dára fún wa ní Íjíbítì?”+ Jèhófà yóò sì fún yín ní ẹran dájúdájú, ẹ̀yin yóò sì jẹ ní tòótọ́.+ 19  Ẹ̀yin yóò jẹ, kì í ṣe fún ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì  tàbí ọjọ́ márùn-ún tàbí ọjọ́ mẹ́wàá tàbí ogún ọjọ́, 20  ṣùgbọ́n títí dé oṣù kan gbáko, títí yóò fi jáde ní ihò imú yín, tí yóò sì di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin sí yín,+ kìkì nítorí pé ẹ kọ Jèhófà, ẹni tí ó wà ní àárín yín, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún níwájú rẹ̀, pé: “Èé ṣe tí a fi jáde wá láti Íjíbítì?”’”+ 21  Nígbà náà ni Mósè wí pé: “Àwọn ènìyàn tí mo wà ní àárín wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ènìyàn+ tí ń fẹsẹ̀ rìn, síbẹ̀ ìwọ—ìwọ sì ti wí pé, ‘Èmi yóò fún wọn ní ẹran, dájúdájú, wọn yóò sì jẹ ẹ́ fún oṣù kan gbáko’! 22  A ó ha pa agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran fún wọn, kí ó lè tó wọn?+ Tàbí a ó ha mú gbogbo ẹja òkun fún wọn, kí ó lè tó wọn?” 23  Látàrí èyí, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Ọwọ́ Jèhófà kúrú, àbí?+ Nísinsìnyí ìwọ yóò rí bóyá ohun tí mo wí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”+ 24  Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè jáde lọ, ó sì sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún àwọn ènìyàn náà. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kó àádọ́rin ọkùnrin jọ lára àwọn àgbà ọkùnrin nínú àwọn ènìyàn náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn dúró yí àgọ́ ká.+ 25  Nígbà náà ni Jèhófà sọ̀ kalẹ̀ wá nínú àwọsánmà,+ ó sì bá a sọ̀rọ̀,+ ó sì mú díẹ̀ lára ẹ̀mí+ tí ó wà lára rẹ̀ kúrò, ó sì fi í sára ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àádọ́rin àgbà ọkùnrin náà. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí ẹ̀mí náà sọ̀ kalẹ̀ sára wọn, nígbà náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí àwọn wòlíì; ṣùgbọ́n wọn kò tún ṣe é mọ́.+ 26  Wàyí o, ó ku méjì  nínú àwọn ọkùnrin náà sí ibùdó. Orúkọ ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Ẹ́lídádì, orúkọ ìkejì  sì ń jẹ́ Médádì. Ẹ̀mí náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀ kalẹ̀ sára wọn, níwọ̀n bí wọ́n tí wà lára àwọn tí a kọ sílẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò jáde lọ sí àgọ́. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí wòlíì ní ibùdó. 27  Ọ̀dọ́kùnrin kan sì bẹ̀rẹ̀ sí sáré, ó sì ń ròyìn fún Mósè pé: “Ẹ́lídádì àti Médádì ń ṣe bí wòlíì ní ibùdó!” 28  Nígbà náà ni Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì, òjíṣẹ́+ Mósè láti ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀, dáhùn padà, ó sì wí pé: “Olúwa mi Mósè, dá wọn lẹ́kun!”+ 29  Bí ó ti wù kí ó rí, Mósè sọ fún un pé: “Ṣé o ń jowú fún mi ni? Rárá, ì bá wù mí kí gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà jẹ́ wòlíì, nítorí pé Jèhófà yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ sára wọn!”+ 30  Lẹ́yìn náà, Mósè fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ibùdó, òun àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì. 31  Ẹ̀fúùfù+ kan sì rọ́ jáde láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá àwọn àparò láti òkun,+ ó sì mú kí wọ́n bọ́ sí ibùdó ní nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan síhìn-ín àti nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ kan sọ́hùn-ún, yí ibùdó ká, àti nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́ méjì  sókè lórí ilẹ̀. 32  Nígbà náà ni àwọn ènìyàn náà dìde ní gbogbo ọjọ́ yẹn àti ní gbogbo òru àti ní gbogbo ọjọ́ kejì , wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíkó àparò jọ. Ẹni tí ó kó kéré jù lọ kó òṣùwọ̀n hómérì+ mẹ́wàá jọ, wọ́n sì ń sá wọn sílẹ̀ lọ jàra fún ara wọn yíká-yíká ibùdó náà. 33  Ẹran náà ṣì wà láàárín eyín+ wọn, kí wọ́n tó jẹ ẹ́ lẹ́nu, nígbà tí ìbínú Jèhófà ru+ sí àwọn ènìyàn náà, Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpakúpa púpọ̀ gan-an kọlu àwọn ènìyàn náà.+ 34  Orúkọ ibẹ̀ yẹn ni a wá pè ní Kiburoti-hátááfà, nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n sin àwọn ènìyàn tí ó fi ìfàsí-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan hàn sí.+ 35  Láti Kiburoti-hátááfà+ àwọn ènìyàn náà ṣí lọ sí Hásérótì, wọ́n sì ń bá a lọ ní wíwà ní Hásérótì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé