Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Númérì 1:1-54

1  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì,+ nínú àgọ́ ìpàdé,+ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì  ní ọdún kejì  tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ó sì sọ pé:  “Ẹ ka iye+ àpéjọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn, nípa iye orúkọ, gbogbo àwọn ọkùnrin, orí kọ̀ọ̀kan wọn,  láti ẹni ogún ọdún sókè,+ olúkúlùkù tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ísírẹ́lì.+ Kí ẹ orúkọ wọn sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìwọ àti Áárónì.  “Kí àwọn ọkùnrin mélòó kan sì wà pẹ̀lú yín, ọkùnrin kan fún ẹ̀yà kan; ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ olórí ilé àwọn baba rẹ̀.+  Ìwọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò dúró pẹ̀lú yín: Ti Rúbẹ́nì,+ Élísúrì+ ọmọkùnrin Ṣédéúrì;  ti Síméónì,+ Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọkùnrin Súríṣádáì;  ti Júdà,+ Náṣónì+ ọmọkùnrin Ámínádábù;  ti Ísákárì,+ Nétánélì+ ọmọkùnrin Súárì;  ti Sébúlúnì,+ Élíábù+ ọmọkùnrin Hélónì; 10  ti àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù:+ ti Éfúráímù,+ Élíṣámà ọmọkùnrin Ámíhúdù; ti Mánásè,+ Gàmálíẹ́lì ọmọkùnrin Pédásúrì; 11  ti Bẹ́ńjámínì,+ Ábídánì+ ọmọkùnrin Gídíónì; 12  ti Dánì,+ Áhíésérì+ ọmọkùnrin Ámíṣádáì; 13  ti Áṣérì,+ Págíẹ́lì+ ọmọkùnrin Ókíránì; 14  ti Gádì,+ Élíásáfù+ ọmọkùnrin Déúélì;+ 15  ti Náfútálì,+ Áhírà+ ọmọkùnrin Énánì. 16  Àwọn wọ̀nyí ni a pè láti inú àpéjọ náà, àwọn ìjòyè+ láti inú ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì.”+ 17  Nítorí náà, Mósè àti Áárónì mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí a ti yàn sọ́tọ̀ nípa orúkọ. 18  Wọ́n sì pe gbogbo àpéjọ náà jọpọ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì , kí wọ́n bàa lè sọ orírun+ wọn di mímọ̀ ní ti ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ, láti ẹni ogún ọdún sókè,+ orí kọ̀ọ̀kan wọn, 19  gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí forúkọ wọn sílẹ̀+ ní aginjù Sínáì. 20  Àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, àkọ́bí+ Ísírẹ́lì, ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, wá jẹ́ nípa iye orúkọ, orí kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo ọkùnrin láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 21  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì, ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 22  Ti àwọn ọmọkùnrin Síméónì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé àwọn baba wọn, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ nípa iye orúkọ, orí kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo ọkùnrin láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 23  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Síméónì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó dín ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+ 24  Ti àwọn ọmọkùnrin Gádì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 25  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Gádì+ jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ.+ 26  Ti àwọn ọmọkùnrin Júdà,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 27  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì  ó lé ẹgbẹ̀ta.+ 28  Ti àwọn ọmọkùnrin Ísákárì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 29  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísákárì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó.+ 30  Ti àwọn ọmọkùnrin Sébúlúnì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 31  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Sébúlúnì jẹ́ ẹgbàá méjì dínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+ 32  Ti àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù: ti àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 33  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Éfúráímù+ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+ 34  Ti àwọn ọmọkùnrin Mánásè,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 35  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba.+ 36  Ti àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 37  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje.+ 38  Ti àwọn ọmọkùnrin Dánì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 39  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+ 40  Ti àwọn ọmọkùnrin Áṣérì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 41  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì  ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ.+ 42  Ti àwọn ọmọkùnrin Náfútálì,+ ìbí wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé wọn ní ilé baba wọn, nípa iye orúkọ láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun, 43  àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Náfútálì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+ 44  Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀, tí Mósè forúkọ wọn sílẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú Áárónì àti àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì, àwọn ọkùnrin méjì lá. Olúkúlùkù wọ́n ṣojú fún ilé baba rẹ̀. 45  Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn láti ẹni ogún ọdún sókè, olúkúlùkù ẹni tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ísírẹ́lì, wá jẹ́, 46  bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ wá jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjì dínlógún dín àádọ́ta.+ 47  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Léfì+ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀yà baba wọn, kò forúkọ sílẹ̀ láàárín wọn.+ 48  Nítorí náà, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 49  “Kì kì ẹ̀yà Léfì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, iye wọn ni ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 50  Kí ìwọ fúnra rẹ sì yan àwọn ọmọ Léfì sípò lórí àgọ́ ìjọsìn Gbólóhùn Ẹ̀rí+ àti lórí gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti lórí gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ọn.+ Àwọn fúnra wọn ni yóò ru àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo nǹkan èlò rẹ̀,+ àwọn fúnra wọn ni yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́+ nídìí rẹ̀; wọn yóò sì dó yí àgọ́ ìjọsìn náà ká.+ 51  Nígbàkigbà tí àgọ́ ìjọsìn náà bá sì ń ṣí lọ, kí àwọn ọmọ Léfì tú u palẹ̀;+ nígbà tí àgọ́ ìjọsìn náà bá sì dó, kí àwọn ọmọ Léfì gbé e nà ró; àjèjì  èyíkéyìí tí ó bá sì sún mọ́ tòsí ni kí a fi ikú pa.+ 52  “Kí olúkúlùkù ọmọ Ísírẹ́lì sì dó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ibùdó rẹ̀, àti olúkúlùkù ọkùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ìpín+ rẹ̀ tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. 53  Kí àwọn ọmọ Léfì sì dó yí àgọ́ ìjọsìn Gbólóhùn Ẹ̀rí ká, kí ìkannú+ kankan má bàa dìde sí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; àwọn ọmọ Léfì sì ní láti máa pa iṣẹ́ ìsìn tí ó yẹ àgọ́ ìjọsìn Gbólóhùn Ẹ̀rí+ mọ́.” 54  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún Mósè. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé