Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Náhúmù 3:1-19

3  Ègbé ni fún ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.+ Gbogbo rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn àti fún ìjanilólè. Ẹran ọdẹ kì í kúrò!  Ìró pàṣán+ àti dídún àgbá kẹ̀kẹ́ wà, àti ẹṣin tí ń já lọ fìà-fìà àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ tí ń tọ sókè.  Àwọn ẹlẹ́ṣin tí ó gẹṣin, àti ọwọ́ iná idà, àti mànàmáná ọ̀kọ̀,+ àti ògìdìgbó àwọn tí a pa, àti àgbájọ àwọn òkú tìrìgàngàn; àwọn òkú kò sì lópin. Wọ́n ń kọsẹ̀ láàárín àwọn òkú wọn;  nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ìṣe kárùwà ti kárùwà,+ tí ń fi òòfà ẹwà fani mọ́ra, ìyálóde àwọn iṣẹ́ àjẹ́, ẹni tí ń dẹkùn mú àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ àwọn ìṣe kárùwà rẹ̀, àti àwọn ìdílé nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ àjẹ́+ rẹ̀.  “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ìwọ,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, “dájúdájú, èmi yóò sì fi apá gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ bò ọ́ lójú, èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè rí ìhòòhò rẹ,+ àwọn ìjọba yóò sì rí àbùkù rẹ.  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ àwọn ohun ìríra lù ọ́,+ èmi yóò sì sọ ọ́ di ohun ìtẹ́ńbẹ́lú; èmi yóò sì gbé ọ kalẹ̀ bí ìran àpéwò.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, gbogbo ẹni tí ó bá rí ọ yóò sá lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,+ yóò sì sọ dájúdájú pé, ‘A ti fi Nínéfè ṣe ìjẹ! Ta ni yóò bá a kẹ́dùn?’ Ibo ni èmi yóò ti wá àwọn olùtùnú fún ọ?  Ìwọ ha sàn ju Noo-ámónì,+ tí ó jókòó lẹ́bàá àwọn ipa odò Náílì?+ Omi ni ó yí i ká, ẹni tí ọlà rẹ̀ jẹ́ òkun, ẹni tí ògiri rẹ jẹ́ láti òkun.  Etiópíà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá rẹ̀, àti Íjíbítì+ pẹ̀lú; ìyẹn kò sì lópin. Pútì àti àwọn ará Líbíà pàápàá ti ṣe ìrànwọ́ fún ọ.+ 10  Òun, pẹ̀lú, ni a pète fún ìgbèkùn;+ ó lọ sí oko òǹdè. Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú ni a wá fọ́ túútúú ní orí gbogbo ojú pópó;+ wọ́n sì ṣẹ́ kèké+ lórí àwọn ọkùnrin rẹ̀ àyìnlógo, gbogbo àwọn ẹni ńlá rẹ̀ ni a sì ti dè ní ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.+ 11  “Ìwọ alára yóò mu àmupara+ pẹ̀lú; ìwọ yóò di ohun fífarasin.+ Ìwọ alára pẹ̀lú yóò wá ibi odi agbára kúrò lọ́dọ̀ ọ̀tá.+ 12  Gbogbo ibi olódi rẹ dà bí àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ó so àkọ́pọ́n èso, èyí tí ó jẹ́ pé, bí a bá gbò ó jìgìjìgì, bíbọ́ ni yóò bọ́ sí ẹnu olùjẹ.+ 13  “Wò ó! Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ obìnrin ní àárín rẹ.+ Láìsí àní-àní, àwọn ẹnubodè ilẹ̀ rẹ ni a óò ṣí fún àwọn ọ̀tá rẹ. Dájúdájú, iná yóò jẹ àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ run. 14  Fa omi ìsàgatì fún ara rẹ.+ Fún àwọn ibi olódi+ rẹ lókun. Bọ́ sínú ẹrẹ̀, kí o sì ṣe títẹ̀mọ́lẹ̀ nínú amọ̀; di irinṣẹ́ àfimọ-bíríkì mú. 15  Àní ibẹ̀ ni iná yóò ti jẹ ọ́ run. Idà yóò ké ọ kúrò.+ Yóò jẹ ọ́ run bí àwọn irú eéṣú kan.+ Mú ara rẹ pọ̀ súà níye bí àwọn irú eéṣú kan; mú ara rẹ pọ̀ súà níye bí eéṣú. 16  Ìwọ ti sọ àwọn oníṣòwò rẹ di púpọ̀ ju àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run.+ “Ní ti àwọn irú eéṣú kan, ó bó awọ ara rẹ̀ kúrò ní ti tòótọ́; nígbà náà ni ó fò lọ. 17  Àwọn ẹ̀ṣọ́kùnrin rẹ dà bí eéṣú, àwọn tí ń bá ọ gbani síṣẹ́ ogun sì dà bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ eéṣú. Wọ́n dó sínú ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe ní ọjọ́ òtútù. Kí oòrùn kàn ràn ni, wọn a sì sá lọ dájúdájú; ipò wọn níbi tí wọ́n wà ni a kò sì mọ̀ ní ti tòótọ́.+ 18  “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rẹ ti tòògbé,+ ìwọ ọba Ásíríà; àwọn ọlọ́lá ọba rẹ dúró sí ibùgbé wọn.+ A ti tú àwọn ènìyàn rẹ ká sórí àwọn òkè ńlá, kò sì sí ẹni tí ń kó wọn jọpọ̀.+ 19  Kò sí ìtura fún àjálù ibi rẹ. Ọgbẹ́ rẹ ti di aláìṣeéwòsàn.+ Gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ìròyìn nípa rẹ yóò pàtẹ́wọ́ sí ọ dájúdájú;+ nítorí pé, orí ta ni ìwà búburú rẹ kò ti kọjá nígbà gbogbo?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé