Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Náhúmù 2:1-13

2  Atúniká ti gòkè wá sí iwájú rẹ.+ Kí fífi ìṣọ́ ṣọ́ ibi olódi kí ó wà. Ṣọ́ ọ̀nà. Fún ìgbáròkó lókun. Mú agbára pọ̀ sí i gidigidi.+  Nítorí Jèhófà yóò kó ohun ìyangàn Jékọ́bù+ jọ dájúdájú, bí ohun ìyangàn Ísírẹ́lì, nítorí àwọn atúnidànù ti tú wọn dànù;+ wọ́n sì ti run+ ọ̀mùnú wọn.  Apata àwọn ọkùnrin rẹ̀ alágbára ńlá ni a pa láró pupa; àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí ó ní ìmí wọ ẹ̀yà aṣọ pípọ́ndòdò.+ Bí iná àwọn ohun àdèmọ́ tí a fi irin ṣe ni àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ní ọjọ́ ìmúrasílẹ̀ rẹ̀, àwọn ọ̀kọ̀ onígi júnípà+ ni a sì ti mú kí ó gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.  Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ń sáre àsápajúdé+ ní ojú pópó. Wọ́n ń sáré sókè-sódò ní ojúde ìlú. Ìrísí wọn dà bí ògùṣọ̀. Wọ́n ń sáré bí mànàmáná.+  Òun yóò rántí àwọn ọlọ́lá+ ọba rẹ̀. Wọn yóò kọsẹ̀ ní ìrìn wọn.+ Wọn yóò ṣe kánkán lọ sí ibi ògiri rẹ̀, a ó sì fìdí odi ìdènà múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.  Àní àwọn ẹnubodè odò yóò ṣí dájúdájú, ààfin pàápàá ni a ó sì tú palẹ̀ ní ti tòótọ́.  A sì ti fi í lélẹ̀; a ti tú u síta; a óò gbé e lọ+ dájúdájú, àwọn ẹrúbìnrin rẹ̀ yóò sì máa kédàárò, bí ìró àwọn àdàbà,+ wọn yóò máa lu ọkàn-àyà+ wọn léraléra.  Àti Nínéfè, láti àwọn ọjọ́ tí ó ti wà,+ ó dà bí adágún omi;+ ṣùgbọ́n wọ́n ń sá lọ. “Ẹ dúró jẹ́ẹ́! Ẹ dúró jẹ́ẹ́!” Ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kan tí ó yí padà.+  Ẹ piyẹ́ fàdákà; ẹ piyẹ́ wúrà;+ níwọ̀n bí àwọn nǹkan tí a ṣètò kò ti lópin. Iye gbogbo onírúurú ohun èlò+ fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ó wà bùáyà. 10  Òfìfo àti ìṣófo, àti ìlú ńlá tí a sọ di ahoro!+ Ọkàn-àyà sì domi,+ àwọn eékún+ sì ń ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, ìrora mímúná sì wà ní gbogbo ìgbáròkó;+ àti ní ti ojú gbogbo wọn, wọn yóò ràn koko fún ìdààmú.+ 11  Ibo ni ibùgbé àwọn kìnnìún wà, àti hòrò tí ó jẹ́ ti àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀, ibi tí kìnnìún rìn, tí ó sì wọ̀,+ ibi tí ọmọ kìnnìún wà, tí ẹnì kankan kò sì mú wọn wárìrì?+ 12  Kìnnìún ń fa èyí tí ó tó ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì ń fún lọ́rùn pa fún àwọn abo kìnnìún rẹ̀. Ó sì mú kí ihò rẹ̀ kún fún ẹran ọdẹ, àwọn ibi ìfarapamọ́ rẹ̀ sì kún fún àwọn ẹran tí a fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.+ 13  “Wò ó! Mo dojú ìjà kọ ìwọ,” ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ “dájúdájú, èmi yóò sì sun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ nínú èéfín.+ Idà yóò sì jẹ àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ rẹ run.+ Dájúdájú, èmi yóò sì ké ẹran ọdẹ rẹ kúrò ní ilẹ̀ ayé, a kì yóò sì tún gbọ́ ohùn àwọn ońṣẹ́ rẹ mọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé