Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Náhúmù 1:1-15

1  Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Nínéfè:+ Ìwé ìran Náhúmù ará Élíkóṣì:  Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe,+ ó sì ń gbẹ̀san; Jèhófà ń gbẹ̀san,+ ó sì ti ṣe tán láti fi ìhónú+ hàn. Jèhófà ń gbẹ̀san lára àwọn elénìní+ rẹ̀, ó sì ń fìbínú hàn sí àwọn ọ̀tá+ rẹ̀.  Jèhófà ń lọ́ra láti bínú,+ ó sì tóbi ní agbára,+ láìsí àní-àní, Jèhófà kì yóò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹni.+ Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú ẹ̀fúùfù apanirun àti nínú ìjì, ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà sì ni erukutu ẹsẹ̀+ rẹ̀.  Ó ń bá òkun+ wí lọ́nà mímúná, ó sì gbẹ ẹ́ táútáú;+ gbogbo odò ni ó sì mú gbẹ ní ti tòótọ́. Báṣánì àti Kámẹ́lì ti rọ, àní ìtànná Lẹ́bánónì ti rọ.+  Àwọn òkè ńláńlá ti mì jìgìjìgì nítorí rẹ̀, àní àwọn òkè kéékèèké bẹ̀rẹ̀ sí yọ́.+ Ilẹ̀ ayé yóò sì ru gùdù sókè nítorí ojú rẹ̀; àti ilẹ̀ eléso pẹ̀lú, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+  Ta ni ó lè dúró lójú ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá?+ Ta ni ó sì lè dìde lòdì sí ooru ìbínú rẹ̀?+ Dájúdájú, ìhónú rẹ̀ ni a óò tú jáde bí iná,+ àní àwọn àpáta ni a ó sì bì wó ní ti tòótọ́ nítorí rẹ̀.  Jèhófà jẹ́ ẹni rere,+ ibi odi agbára+ ní ọjọ́ wàhálà.+ Ó sì mọ àwọn tí ń wá ibi ìsádi lọ́dọ̀ rẹ̀.+  Ìkún omi tí ń kọjá lọ ni òun yóò sì fi pa ibẹ̀ run pátápátá,+ òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá+ rẹ̀ pàápàá.  Kí ni ẹ̀yin yóò gbìrò lòdì sí Jèhófà?+ Ó ń fa ìparun pátápátá. Wàhálà kì yóò dìde nígbà kejì.+ 10  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a hun wọ́n pọ̀ mọ́ra àní bí ẹ̀gún,+ tí wọ́n sì mu àmupara bí ẹni pé ọtí bíà+ àlìkámà wọn ni wọ́n mu, dájúdájú, a ó jẹ wọ́n run bí àgékù pòròpórò tí ó ti gbẹ pátápátá.+ 11  Láti inú rẹ ni ẹnì kan tí ń gbìrò ohun tí ó burú+ sí Jèhófà yóò ti jáde lọ ní ti tòótọ́, tí ń pète ohun tí kò wúlò.+ 12  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà ní ipò pípé pérépéré, tí ọ̀pọ̀ sì wà nínú ipò yẹn, inú ipò yẹn ni a ó ti ké wọn lulẹ̀;+ ẹnì kan yóò sì kọjá lọ. Dájúdájú, èmi yóò ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, kí n má bàa ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́ mọ́.+ 13  Wàyí o, èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá gbọọrọ rẹ̀ tí a fi ń gbé nǹkan, kúrò lọ́rùn rẹ,+ àwọn ọ̀já tí ó sì wà lára rẹ ni èmi yóò fà já sí méjì.+ 14  Jèhófà sì ti pàṣẹ nípa rẹ pé, ‘Kò sí nǹkan kan tí ó jẹ mọ́ orúkọ rẹ tí a óò fúnrúgbìn mọ́.+ Èmi yóò ké ère gbígbẹ́ àti ère dídà kúrò nínú ilé àwọn ọlọ́run rẹ.+ Èmi yóò ṣe ibi ìsìnkú fún ọ,+ nítorí o kò jámọ́ nǹkan kan.’ 15  “Wò ó! Lórí àwọn òkè ńlá, ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá, ẹni tí ń kéde àlàáfíà+ fáyé gbọ́. Ìwọ Júdà, ṣe ayẹyẹ àwọn àjọyọ̀+ rẹ. San àwọn ẹ̀jẹ́+ rẹ; nítorí tí aláìdára fún ohunkóhun kì yóò tún kọjá nínú rẹ mọ́.+ Dájúdájú, a óò ké e kúrò pátápátá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé