Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Míkà 6:1-16

6  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ ohun tí Jèhófà ń wí.+ Dìde, bá àwọn òkè ńláńlá ṣe ẹjọ́, kí àwọn òkè kéékèèké sì gbọ́ ohùn+ rẹ.  Ẹ gbọ́ ẹjọ́ Jèhófà, ẹ̀yin òkè ńlá, àti ẹ̀yin ohun alálòpẹ́, ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé;+ nítorí Jèhófà ní ẹjọ́ láti ṣe pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, yóò sì bá Ísírẹ́lì jiyàn:+  “Ìwọ ènìyàn+ mi, kí ni mo fi ṣe ọ́? Ọ̀nà wo ni mo sì fi kó àárẹ̀ bá ọ?+ Jẹ́rìí lòdì sí mi.+  Nítorí mo mú ọ gòkè wá kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ mo sì tún ọ rà padà kúrò ní ilé ẹrú;+ mo sì tẹ̀ síwájú láti rán Mósè, Áárónì àti Míríámù+ ṣíwájú rẹ.  Ìwọ ènìyàn mi, jọ̀wọ́, rántí+ ohun tí Bálákì ọba Móábù pète,+ àti ohun tí Báláámù ọmọkùnrin Béórì fi dá a lóhùn.+ Láti Ṣítímù+ ni, dé iyàn-níyàn Gílígálì,+ pẹ̀lú ìpètepèrò pé kí àwọn ìṣe òdodo Jèhófà lè di mímọ̀.”+  Kí ni èmi yóò gbé wá pàdé Jèhófà?+ Kí ni èmi yóò fi tẹrí ba fún Ọlọ́run ní ibi gíga lókè?+ Èmi yóò ha gbé odindi ọrẹ ẹbọ+ sísun wá pàdé rẹ̀, pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?  Inú Jèhófà yóò ha dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò, sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá ọ̀gbàrá òróró?+ Èmi yóò ha fi ọmọkùnrin mi àkọ́bí lélẹ̀ fún ìdìtẹ̀ mi, èso ikùn mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn+ mi?  Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára.+ Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,+ kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere,+ kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà+ ní bíbá Ọlọ́run+ rẹ rìn?  Àní ohùn Jèhófà ké+ sí ìlú ńlá náà, ẹni tí ó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ yóò sì bẹ̀rù orúkọ+ rẹ. Ẹ gbọ́ ọ̀pá náà àti ẹni tí ó yàn án.+ 10  Àwọn ìṣúra ìwà burúkú+ ha ṣì wà ní ilé ẹni burúkú, àti òṣùwọ̀n eéfà tí kò kún, tí í ṣe ohun ìdálẹ́bi? 11  Mo ha lè mọ́ ní ìwà pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n burúkú àti pẹ̀lú àpò tí ó kún fún òkúta àfiwọn-ìwúwo tí a fi ń tanni jẹ?+ 12  Nítorí àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ̀ ti kún fún ìwà ipá, àwọn olùgbé rẹ̀ sì ti sọ̀rọ̀ èké,+ ahọ́n wọ́n sì jẹ́ alágàálámàṣà ní ẹnu wọn.+ 13  “Èmi pẹ̀lú, ní tèmi, yóò sì mú ọ ṣàìsàn dájúdájú nípa lílù ọ́;+ ìsọdahoro rẹ yóò sì wà, ní tìtorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.+ 14  Ìwọ, ní tìrẹ, yóò jẹun, ìwọ kì yóò sì yó, òfìfo rẹ yóò sì wà ní inú rẹ.+ Ìwọ yóò sì kó àwọn nǹkan kúrò, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kó wọn lọ láìséwu; ohun yòówù tí o bá sì kó lọ láìséwu, ni èmi yóò fi í fún idà.+ 15  Ìwọ, ní tìrẹ, yóò fún irúgbìn, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kárúgbìn. Ìwọ, ní tìrẹ, yóò tẹ ólífì, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró para; àti wáìnì dídùn pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.+ 16  Àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ Ómírì+ àti gbogbo iṣẹ́ ilé Áhábù ni a sì ń ṣàkíyèsí,+ ẹ sì ń rìn nínú ìmọ̀ràn+ wọn; kí n lè sọ ọ́ di ohun ìyàlẹ́nu àti àwọn olùgbé rẹ̀ di ohun ìsúfèé sí;+ ẹ ó sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé