Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Míkà 4:1-13

4  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́+ pé òkè ńlá+ ilé+ Jèhófà yóò di èyí tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in sí orí àwọn òkè ńláńlá, dájúdájú, a óò gbé e lékè àwọn òkè kéékèèké;+ àwọn ènìyàn yóò sì máa wọ́ tìrítìrí+ lọ síbẹ̀.  Dájúdájú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò lọ, wọn yóò sì wí pé: “Ẹ wá,+ ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí òkè ńlá Jèhófà àti sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù;+ òun yóò sì fún wa ní ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà+ rẹ̀, àwa yóò sì máa rìn ní àwọn ipa ọ̀nà+ rẹ̀.” Nítorí láti Síónì ni òfin yóò ti jáde lọ, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò sì jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù.+  Dájúdájú, òun yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,+ yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́+ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá tí ó jìnnà réré.+ Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀,+ wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+  Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́+ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì;+ nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.+  Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run+ tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run+ wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+  “Ní ọjọ́ yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “Dájúdájú, èmi yóò kó ẹni tí ń tiro+ jọ; ẹni tí a fọ́n ká ni èmi yóò sì kó jọpọ̀+ dájúdájú, àní ẹni tí mo ti ṣe ṣúkaṣùka pàápáá.  Dájúdájú, èmi yóò sọ ẹni tí ń tiro di àṣẹ́kù,+ èmi yóò sì sọ ẹni tí a mú kúrò jìnnà réré di orílẹ̀-èdè alágbára ńlá;+ Jèhófà yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn ní ti tòótọ́ ní Òkè Ńlá Síónì, láti ìsinsìnyí lọ àti fún àkókò tí ó lọ kánrin.+  “Àti ní ti ìwọ, ilé gogoro agbo ẹran ọ̀sìn, òkìtì ọmọbìnrin Síónì,+ yóò wá títí dé ọ̀dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni, àgbègbè ìṣàkóso àkọ́kọ́ yóò wá+ dájúdájú, ìjọba tí ó jẹ́ ti ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.+  “Wàyí o, èé ṣe tí o fi ń kígbe tantan?+ Ọba kò ha sí nínú rẹ, tàbí agbani-nímọ̀ràn rẹ ha ti ṣègbé, tí ìroragógó bí ti obìnrin tí ó fẹ́ bímọ fi rá ọ mú?+ 10  Máa jẹ ìrora mímúná, kí o sì bú jáde, ìwọ ọmọbìnrin Síónì, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ,+ nítorí ìsinsìnyí ni ìwọ yóò jáde lọ kúrò ní ìlú, ìwọ yóò sì ní láti máa gbé nínú pápá.+ Ìwọ yóò sì ní láti lọ títí dé Bábílónì.+ Ibẹ̀ ni a ó ti dá ọ nídè.+ Ibẹ̀ ni Jèhófà yóò ti rà ọ́ padà kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọ̀tá+ rẹ. 11  “Àti nísinsìnyí, a óò kó orílẹ̀-èdè púpọ̀ jọ lòdì sí ọ dájúdájú, àwọn tí ń sọ pé, ‘Kí ó di eléèérí, kí ojú wa sì wo Síónì.’+ 12  Ṣùgbọ́n ní tiwọn, wọn kò mọ ìrònú Jèhófà, wọn kò sì lóye ète+ rẹ̀; nítorí dájúdájú, òun yóò kó wọn jọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sí ilẹ̀ ìpakà.+ 13  “Dìde, kí o sì pakà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+ nítorí ìwo rẹ ni èmi yóò yí padà di irin, àwọn pátákò rẹ ni èmi yóò sì yí padà di bàbà, dájúdájú, ìwọ yóò lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lúúlúú;+ ní ti tòótọ́, nípasẹ̀ ìfòfindè, ìwọ yóò sì ya èrè+ wọn tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu sọ́tọ̀ fún Jèhófà, àti àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn fún Olúwa tòótọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé