Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Míkà 3:1-12

3  Mo sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí Jékọ́bù àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì.+ Kì í ha ṣe iṣẹ́ yín ni láti mọ ìdájọ́ òdodo?+  Ẹ̀yin olùkórìíra ohun rere+ àti olùfẹ́ ìwà búburú,+ tí ń bó awọ ara kúrò lára àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà ara kúrò lára egungun+ wọn;  ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ ẹ̀yà ara àwọn ènìyàn+ mi pẹ̀lú, tí ẹ sì ti bó awọ ara wọn kúrò lára wọn, tí ẹ sì fọ́ egungun wọn pàápàá sí wẹ́wẹ́, tí ẹ sì fọ́ wọn túútúú bí ohun tí ó wà nínú ìkòkò ẹlẹ́nu fífẹ̀ àti bí ẹran ní inú ìkòkò ìse-oúnjẹ.+  Ní àkókò yẹn, wọn yóò ké pe Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kì yóò dá wọn lóhùn.+ Yóò sì fi ojú rẹ̀ pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní àkókò yẹn,+ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe búburú nínú ìbánilò+ wọn.  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí lòdì sí àwọn wòlíì tí ń mú kí àwọn ènìyàn mi rìn gbéregbère,+ tí ń fi eyín+ wọn buni ṣán, tí wọ́n sì ń ké ní ti gidi pé, ‘Àlàáfíà!’+ tí ó jẹ́ pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò bá fi nǹkan sí wọn lẹ́nu, wọn a tún sọ ogun di mímọ́ lòdì sí i ní ti tòótọ́,+  ‘Nítorí náà, òru+ yóò wà fún yín, tí kò fi ní sí ìran;+ òkùnkùn yóò sì ṣú fún yín, kí ẹ má bàa woṣẹ́. Dájúdájú, oòrùn yóò wọ̀ lórí àwọn wòlíì, ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.+  Ojú yóò sì ti+ àwọn olùríran,+ a ó sì já àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ kulẹ̀ dájúdájú. Wọn yóò sì bo túbọ̀mu,+ gbogbo wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’”+  Ní ọwọ́ kejì, ẹ̀wẹ̀, èmi alára sì ti kún fún agbára, nípa ẹ̀mí Jèhófà, àti ti ìdájọ́ òdodo àti agbára ńlá,+ kí n bàa lè sọ ìdìtẹ̀ Jékọ́bù fún un, kí n sì sọ ẹ̀ṣẹ̀+ Ísírẹ́lì fún un.  Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì,+ ẹ̀yin tí ń ṣe họ́ọ̀ sí ìdájọ́ òdodo àti ẹ̀yin tí ń ṣe ohun gbogbo tí ó tọ́ pàápàá ní wíwọ́;+ 10  tí ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ Síónì, tí ó sì ń fi àìṣòdodo+ kọ́ Jerúsálẹ́mù. 11  Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ kìkì fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+ àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń fúnni ní ìtọ́ni kìkì fún iye+ kan, àwọn wòlíì rẹ̀ sì ń woṣẹ́ kìkì fún owó;+ síbẹ̀, wọ́n ń gbára lé Jèhófà, wọ́n wí pé: “Jèhófà kò ha wà ní àárín wa?+ Ìyọnu àjálù+ kankan kì yóò wá sórí wa.” 12  Nítorí náà, ní tìtorí yín, a ó tu Síónì bí ilẹ̀ pápá lásán-làsàn, Jerúsálẹ́mù yóò sì di òkìtì àwókù+ lásán-làsàn, òkè ńlá ilé yóò sì dà bí àwọn ibi gíga igbó.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé