Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Míkà 2:1-13

2  “Ègbé ni fún àwọn tí ń pète-pèrò ohun apanilára, àti fún àwọn tí ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù, lórí ibùsùn+ wọn! Ìgbà ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é,+ nítorí pé ó wà ní agbára ọwọ́+ wọn.  Ojú wọn sì ti wọ pápá, wọ́n sì ti já wọn gbà;+ àti àwọn ilé pẹ̀lú, wọ́n sì ti gbà wọ́n; wọ́n sì ti lu abarapá ọkùnrin àti agbo ilé+ rẹ̀ ní jìbìtì, ènìyàn àti ohun ìní àjogúnbá rẹ̀.+  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi ń gbìrò ìyọnu àjálù+ sí ìdílé yìí,+ nínú èyí tí ẹ kì yóò ti lè yọ ọrùn+ yín, kí ẹ má bàa rìn lọ́nà ìrera;+ nítorí àkókò ìyọnu àjálù ni.+  Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan yóò gbé ọ̀rọ̀ òwe+ dìde nípa yín, yóò sì ṣe ìdárò dájúdájú, àní ìdárò.+ Ẹnì kan yóò sì sọ pé: “A ti fi wá ṣe ìjẹ+ dájúdájú! Àní ìpín àwọn ènìyàn mi ni ó mú ìyípadà+ bá. Ẹ wo bí ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi tó! Ó fi pápá wa fún aláìṣòótọ́.”  Nítorí náà, ìwọ kì yóò ní ẹnì kankan tí ń ta okùn, nípa kèké,+ nínú ìjọ Jèhófà.  Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́.+ Wọ́n jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́. Wọn kì yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́ nípa nǹkan wọ̀nyí. Ìtẹ́lógo kì yóò kúrò.+  “‘Ìwọ ilé Jékọ́bù,+ a ha ń sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ha ti di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tàbí ìwọ̀nyí ha ni ìbánilò+ rẹ̀ bí?” Àwọn ọ̀rọ̀ mi kò ha ń ṣe rere+ nínú ọ̀ràn ẹni tí ń rìn ní ìdúróṣánṣán?+  “‘Lánàá, àwọn ènìyàn mi sì bẹ̀rẹ̀ sí dìde gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá+ paraku. Ẹ bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ ọlọ́lá ńlá kúrò ní iwájú ẹ̀wù, kúrò lára àwọn tí ń kọjá lọ tìgbọ́kànlé-tìgbọ́kànlé, bí àwọn tí ń padà bọ̀ láti ojú ogun.  Obìnrin àwọn ènìyàn mi ni ẹ lé jáde kúrò nínú ilé tí obìnrin ní inú dídùn kíkọyọyọ sí. Ẹ̀yin mú ọlá ńlá+ mi kúrò lára àwọn ọmọ rẹ̀, fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 10  Dìde, kí o sì máa lọ,+ nítorí pé èyí kì í ṣe ibi+ ìsinmi. Nítorí òtítọ náà pé ó ti di aláìmọ́,+ ìfọ́bàjẹ́ wà; iṣẹ́ ìfọ́bàjẹ́ náà sì ń roni lára.+ 11  Bí ènìyàn kan, tí ń rìn nínú ẹ̀fúùfù àti èké, bá purọ́+ pé: “Èmi yóò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́ fún ọ nípa wáìnì àti nípa ọtí tí ń pani,” dájúdájú, òun pẹ̀lú yóò di ẹni tí ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ bọ́ fún àwọn ènìyàn yìí.+ 12  “‘Èmi yóò kó Jékọ́bù jọ dájúdájú, gbogbo yín;+ láìsí àní-àní, èmi yóò kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì jọpọ̀.+ Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran, bí agbo ẹran ọ̀sìn láàárín pápá ìjẹko rẹ̀;+ ibẹ̀ yóò sì kún fún ariwo àwọn ènìyàn.’+ 13  “Ẹni tí ń lànà kọjá yóò gòkè wá níwájú wọn+ dájúdájú: wọn yóò lànà kọjá ní ti tòótọ́. Wọn yóò sì la ẹnubodè kọjá, wọn yóò sì gba ibẹ̀ jáde lọ.+ Ọba wọn yóò sì kọja lọ níwájú wọn, Jèhófà yóò sì wà ní ipò orí wọn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé