Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Míkà 1:1-16

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Míkà+ ti Móréṣétì wá, ní àwọn ọjọ́ Jótámù,+ Áhásì,+ Hesekáyà,+ àwọn ọba Júdà,+ èyí tí ó rí ní ìran nípa Samáríà+ àti Jerúsálẹ́mù:+  “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn, gbogbo yín; fetí sílẹ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ,+ sì jẹ́ kí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí+ lòdì sí yín, Jèhófà láti inú tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ̀ wá.  Nítorí, wò ó! Jèhófà ń jáde lọ láti ipò+ rẹ̀, dájúdájú, òun yóò sọ̀ kalẹ̀ wá, yóò sì tẹ àwọn ibi+ gíga ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀.  Àwọn òkè ńlá yóò sì yọ́ lábẹ́ rẹ̀,+ àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ yóò sì pínyà, bí ìda nítorí iná,+ bí omi tí a dà sórí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.  “Gbogbo èyí jẹ́ nítorí ìdìtẹ̀ Jékọ́bù, àní nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì.+ Kí ni ìdìtẹ̀ Jékọ́bù? Kì í ha ṣe Samáríà bí?+ Kí sì ni àwọn ibi gíga Júdà?+ Wọn kì í ha ṣe Jerúsálẹ́mù bí?  Dájúdájú, èmi yóò sọ Samáríà di òkìtì àwókù inú pápá,+ àwọn ibi tí a ń gbin nǹkan sí nínú ọgbà àjàrà; èmi yóò sì da àwọn òkúta rẹ̀ sínú àfonífojì dájúdájú, àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò sì tú sí borokoto.+  Gbogbo ère fífín rẹ̀ ni a ó sì fọ́ sí wẹ́wẹ́,+ gbogbo ẹ̀bùn tí a fún un gẹ́gẹ́ bí owó ìháyà rẹ̀ ni a ó sì sun nínú iná;+ gbogbo òrìṣà rẹ̀ ni èmi yóò sì sọ di ahoro. Nítorí láti inú àwọn ohun tí a fúnni gẹ́gẹ́ bí owó ìháyà kárùwà ni ó ti kó wọn jọ, inú ohun tí a fúnni gẹ́gẹ́ bí owó ìháyà kárùwà ni wọn yóò sì padà sí.”+  Ní tìtorí èyí, èmi yóò pohùn réré ẹkún, èmi yóò sì hu+ dájúdájú; èmi yóò rìn láìwọ bàtà àti ní ìhòòhò.+ Èmi yóò pohùn réré ẹkún bí àwọn akátá, èmi yóò sì ṣọ̀fọ̀ bí àwọn abo ògòǹgò.  Nítorí ọgbẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ aláìṣeéwòsàn;+ nítorí ó ti dé Júdà,+ ìyọnu àjàkálẹ̀ náà dé ẹnubodè àwọn ènìyàn mi, títí dé Jerúsálẹ́mù.+ 10  “Ẹ má sọ ọ́ jáde ní Gátì; ẹ má sunkún rárá.+ “Ẹ yíràá àní nínú ekuru+ ní ilé Áfírà. 11  Wá ọ̀nà sọdá, ìwọ obìnrin olùgbé Ṣáfírì, ní ìhòòhò goloto+ tí ń tini lójú. Obìnrin olùgbé Sáánánì kò tíì jáde lọ. Ìpohùnréré ẹkún Bẹti-ésélì yóò gba ibi ìdúró rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yín. 12  Nítorí obìnrin olùgbé Márótì ń dúró de ire,+ ṣùgbọ́n ohun tí ó burú sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà sí ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+ 13  So kẹ̀kẹ́ ẹṣin mọ́ àgbájọ ọ̀wọ́ ẹṣin, ìwọ obìnrin olùgbé Lákíṣì.+ Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ ni òun jẹ́ fún ọmọbìnrin Síónì,+ nítorí a ti rí ìdìtẹ̀ Ísírẹ́lì nínú rẹ.+ 14  Nítorí náà, ìwọ yóò fún Moreṣeti-gátì+ ní àwọn ẹ̀bùn ìdágbére. Àwọn ilé Ákísíbù+ dà bí ohun ẹ̀tàn sí àwọn ọba Ísírẹ́lì. 15  Èmi yóò ṣì mú alénikúrò wá bá ọ,+ ìwọ obìnrin olùgbé Máréṣà.+ Ògo Ísírẹ́lì yóò wá títí dé Ádúlámù.+ 16  Mú orí rẹ pá, kí o sì fá irun rẹ kúrò ní tìtorí àwọn ọmọ rẹ tí ń mú inú dídùn kíkọyọyọ+ wá fún ọ. Mú ìpárí rẹ fẹ̀ sí i bí ti idì, nítorí wọ́n ti fi ọ́ sílẹ̀ lọ sí ìgbèkùn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé