Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 9:1-38

9  Nítorí náà, ní wíwọ ọkọ̀ ojú omi, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọdá, ó sì lọ sí ìlú ńlá tirẹ̀.+  Sì wò ó! wọ́n ń gbé ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà kan tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀.+ Bí ó ti rí ìgbàgbọ́ wọn, Jésù wí fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: “Mọ́kànle, ọmọ; a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì.”+  Sì wò ó! àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin sọ fún ara wọn pé: “Àwé yìí ń sọ̀rọ̀ òdì.”+  Ní mímọ ìrònú wọn,+ Jésù sì wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ro àwọn ohun burúkú nínú ọkàn-àyà yín?+  Fún àpẹẹrẹ, èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì, tàbí láti sọ pé, Dìde kí o sì máa rìn?+  Bí ó ti wù kí ó rí, kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ ènìyàn ní ọlá àṣẹ ní ilẹ̀ ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini+—” nígbà náà ni ó sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé rẹ.”+  Ó sì dìde, ó sì lọ sí ilé rẹ̀.  Ní rírí èyí, ẹ̀rù ba àwọn ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo,+ ẹni tí ó fi irúfẹ́ ọlá àṣẹ+ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn.  Lẹ́yìn èyí, bí ó ti ń kọjá lọ láti ibẹ̀, Jésù tajú kán rí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Mátíù, tí ó jókòó ní ọ́fíìsì owó orí, ó sì wí fún un pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.”+ Lójú ẹsẹ̀, ó dìde, ó sì tẹ̀ lé e.+ 10  Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì nínú ilé,+ wò ó! ọ̀pọ̀ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀gbọ̀kú pẹ̀lú Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. 11  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí èyí, àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé olùkọ́ yín ń jẹun pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?”+ 12  Nígbà tí ó gbọ́ wọn, ó wí pé: “Àwọn ẹni tí ó ní ìlera kò nílò oníṣègùn,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀. 13  Ẹ lọ, nígbà náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’+ Nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” 14  Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì béèrè pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwa àti àwọn Farisí sọ ààwẹ̀ gbígbà dàṣà ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”+ 15  Látàrí èyí, Jésù wí fún wọn pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó kò ní ìdí kankan láti ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ ìyàwó+ wà pẹ̀lú wọn, àbí wọ́n ní? Ṣùgbọ́n àwọn ọjọ́ yóò dé nígbà tí a óò mú ọkọ ìyàwó lọ+ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nígbà náà wọn yóò sì gbààwẹ̀.+ 16  Kò sí ẹnì kankan tí í rán ìrépé aṣọ tí kò tíì sún kì sórí ògbólógbòó ẹ̀wù àwọ̀lékè; nítorí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ okun rẹ̀ yóò fà kúrò lára ẹ̀wù àwọ̀lékè náà, yíya náà yóò sì burú jù.+ 17  Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kì í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ; ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà àwọn àpò awọ náà a bẹ́, wáìnì a sì dà sílẹ̀, àwọn àpò awọ náà a sì bàjẹ́.+ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn a máa fi wáìnì tuntun sínú àwọn àpò awọ tuntun, àwọn ohun méjèèjì náà ni a sì pa mọ́.”+ 18  Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, wò ó! olùṣàkóso kan+ tí ó ti sún mọ́ tòsí bẹ̀rẹ̀ sí wárí fún un,+ ó wí pé: “Ní báyìí, ọmọbìnrin mi á ti kú;+ ṣùgbọ́n wá, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóò sì yè.”+ 19  Nígbà náà, ní dídìde, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e; àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀. 20  Sì wò ó! obìnrin kan tí ó ti ń jìyà fún ọdún méjìlá lọ́wọ́ ìṣàn ẹ̀jẹ̀+ wá láti ẹ̀yìn, ó sì fọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀;+ 21  nítorí ó ń sọ fún ara rẹ̀ ṣáá pé: “Bí èmi bá sáà ti fọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, ara mi yóò dá.”+ 22  Jésù yíjú padà àti pé, ní kíkíyèsí i, ó wí pé: “Mọ́kànle, ọmọbìnrin; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ Láti wákàtí yẹn sì ni ara obìnrin náà ti dá.+ 23  Wàyí o, nígbà tí ó dé ilé olùṣàkóso náà,+ tí ó sì tajú kán rí àwọn afunfèrè àti ogunlọ́gọ̀ nínú ìdàrúdàpọ̀ aláriwo,+ 24  Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Ẹ kúrò níbẹ̀, nítorí ọmọdébìnrin kékeré náà kò kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.”+ Látàrí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi í rẹ́rìn-ín tẹ̀gàn-tẹ̀gàn.+ 25  Kété lẹ́yìn tí a ti ní kí ogunlọ́gọ̀ náà bọ́ sóde, ó wọlé, ó sì di ọwọ́ rẹ̀ mú,+ ọmọdébìnrin kékeré náà sì dìde.+ 26  Dájúdájú, ọ̀rọ̀ nípa èyí tàn kálẹ̀ dé gbogbo ẹkùn ilẹ̀ yẹn. 27  Bí Jésù ti ń kọjá lọ láti ibẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì+ tẹ̀ lé e, wọ́n ń ké jáde, wọ́n sì ń wí pé: “Ṣàánú fún wa,+ Ọmọkùnrin Dáfídì.” 28  Lẹ́yìn tí ó ti wọnú ilé, àwọn ọkùnrin afọ́jú náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Jésù sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ẹ ha ní ìgbàgbọ́+ pé mo lè ṣe èyí bí?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa.” 29  Nígbà náà ni ó fọwọ́ kan ojú wọn,+ ó wí pé: “Kí ó ṣẹlẹ̀ sí yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30  Ojú wọ́n sì ríran. Ní àfikún, Jésù pàṣẹ kíkankíkan fún wọn, pé: “Kí ẹ rí i pé ẹnì kankan kò mọ èyí.”+ 31  Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí wọ́n bọ́ sóde, wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn nípa rẹ̀ ní gbogbo ẹkùn ilẹ̀ yẹn.+ 32  Wàyí o, nígbà tí wọ́n ń lọ, wò ó! àwọn ènìyàn mú ọkùnrin odi tí ẹ̀mí èṣù kan sọ di òǹdè wá sọ́dọ̀ rẹ̀;+ 33  lẹ́yìn tí ó sì ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ọkùnrin odi náà sọ̀rọ̀.+ Tóò, kàyéfì ṣe àwọn ogunlọ́gọ̀ náà,+ wọ́n sì wí pé: “A kò tíì rí ohunkóhun tí ó dà bí èyí rí ní Ísírẹ́lì.” 34  Ṣùgbọ́n àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: “Nípasẹ̀ olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”+ 35  Jésù sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé, ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara.+ 36  Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú+ wọ́n ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.+ 37  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.+ 38  Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé