Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 8:1-34

8  Lẹ́yìn tí ó ti sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e.  Sì wò ó! ọkùnrin adẹ́tẹ̀+ kan wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wárí fún un, ó wí pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.”  Àti nítorí náà, ní nína ọwọ́ rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án, ó wí pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, a sì wẹ ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ mọ́.+  Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: “Rí i pé ìwọ kò sọ fún ẹnì kankan,+ ṣùgbọ́n lọ, fi ara rẹ han àlùfáà,+ kí o sì pèsè ẹ̀bùn+ tí Mósè yàn kalẹ̀, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”  Nígbà tí ó wọ Kápánáúmù,+ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ń pàrọwà fún un,  ó sì ń wí pé: “Ọ̀gá, àrùn ẹ̀gbà dá ìránṣẹ́kùnrin mi dùbúlẹ̀ ní ilé, tí a ń mú un joró lọ́nà lílékenkà.”  Ó wí fún un pé: “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, dájúdájú èmi yóò wò ó sàn.”  Ní ìfèsìpadà, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà wí pé: “Ọ̀gá, èmi kì í ṣe ọkùnrin tí ó yẹ fún ọ láti wọ abẹ́ òrùlé mi, ṣùgbọ́n sáà sọ ọ̀rọ̀ náà, ara ìránṣẹ́kùnrin mi yóò sì dá.  Nítorí èmi pẹ̀lú jẹ́ ẹni tí a fi sí ipò ọlá àṣẹ, tí mo ní àwọn ọmọ ogun lábẹ́ mi, èmi a sì wí fún ẹni yìí pé, ‘Mú ọ̀nà rẹ pọ̀n!’+ òun a sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, àti fún òmíràn pé, ‘Wá!’ òun a sì wá, àti fún ẹrú mi pé, ‘Ṣe èyí!’ òun a sì ṣe é.” 10  Ní gbígbọ́ ìyẹn, kàyéfì ṣe Jésù, ó sì wí fún àwọn tí ń tẹ̀ lé e pé: “Mo sọ òtítọ́ fún yín pé, Kò sí ẹnì kan ní Ísírẹ́lì tí èmi tíì rí tí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀.+ 11  Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín pé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti àwọn apá ìlà-oòrùn àti àwọn apá ìwọ̀-oòrùn+ yóò wá, wọn yóò sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì pẹ̀lú Ábúráhámù àti Ísákì àti Jékọ́bù nínú ìjọba+ ọ̀run;+ 12  nígbà tí ó jẹ́ pé, àwọn ọmọ ìjọba+ náà ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde. Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.”+ 13  Jésù wá wí fún ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà pé: “Máa lọ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ ìgbàgbọ́ rẹ, kí ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún ọ.”+ A sì mú ìránṣẹ́kùnrin náà lára dá ní wákàtí yẹn. 14  Bí Jésù sì ti wọ ilé Pétérù, ó rí ìyá ìyàwó+ rẹ̀ tí ó dùbúlẹ̀, tí ibà sì ń ṣe é.+ 15  Nítorí náà, ó fọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀,+ ibà náà sì fi í sílẹ̀, ó sì dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún un.+ 16  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó ti di ìrọ̀lẹ́, àwọn ènìyàn mú ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè wá sọ́dọ̀ rẹ̀; òun sì fi ọ̀rọ̀ lé àwọn ẹ̀mí náà jáde, ó sì wo gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún sàn; 17  kí a lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: “Òun fúnra rẹ̀ gba àwọn àìsàn wa, ó sì ru àwọn òkùnrùn wa.”+ 18  Nígbà tí Jésù rí ogunlọ́gọ̀ tí ó yí i ká, ó pàṣẹ pé kí a ti ọkọ̀ kúrò ní èbúté lọ sí ìhà kejì.+ 19  Akọ̀wé òfin kan sì wá, ó sì wí fún un pé: “Olùkọ́, dájúdájú, èmi yóò tẹ̀ lé ọ lọ sí ibì yòówù tí ìwọ bá fẹ́ lọ.”+ 20  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibi kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.”+ 21  Nígbà náà ni òmíràn nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: “Olúwa, gbà mí láyè láti kọ́kọ́ lọ sìnkú baba mi.” 22  Jésù wí fún un pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn, sì jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú wọn.”+ 23  Nígbà tí ó sì wọ ọkọ̀ ojú omi kan,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ lé e. 24  Wàyí o, wò ó! ìrugùdù ńlá kan dìde nínú òkun, tó bẹ́ẹ̀ tí ìgbì ń bo ọkọ̀ ojú omi náà; ṣùgbọ́n, ó ń sùn.+ 25  Wọ́n sì wá, wọ́n sì jí i,+ wọ́n wí pé: “Olúwa, gbà wá là, a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣègbé!” 26  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣọkàn ojo, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?”+ Nígbà náà, ní dídìde, ó bá ẹ̀fúùfù àti òkun náà wí lọ́nà mímúná, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.+ 27  Nítorí náà, kàyéfì ṣe àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì wí pé: “Irú ènìyàn wo nìyí,+ tí ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i?” 28  Nígbà tí ó dé ìhà kejì, sí ilẹ̀ àwọn ará Gádárà,+ níbẹ̀ àwọn ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè,+ tí wọn ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì ìrántí, pàdé rẹ̀, wọ́n rorò lọ́nà kíkàmàmà, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹnì kankan kò ní ìgboyà láti gba ojú ọ̀nà yẹn kọjá. 29  Sì wò ó! wọ́n lọgun, pé: “Kí ní pa tàwa tìrẹ pọ̀, Ọmọ Ọlọ́run?+ Ìwọ ha wá síhìn-ín láti mú wa joró+ ṣáájú àkókò tí a yàn kalẹ̀?”+ 30  Ṣùgbọ́n ní ọ̀nà jíjìnréré sí ọ̀dọ̀ wọn, ọ̀wọ́ ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan ń jẹ̀ nínú pápá ìjẹko. 31  Nítorí náà, àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un, pé: “Bí ìwọ bá lé wa jáde, rán wa jáde lọ sínú ọ̀wọ́ ẹlẹ́dẹ̀ náà.”+ 32  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí fún wọn pé: “Ẹ lọ!” Wọ́n jáde, wọ́n sì lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà; sì wò ó! gbogbo ọ̀wọ́ ẹran náà pátá tú pùú sáré ré bèbè ọ̀gbun náà kọjá sínú òkun, wọ́n sì kú nínú omi.+ 33  Ṣùgbọ́n àwọn darandaran náà sá lọ àti pé, ní lílọ sínú ìlú ńlá náà, wọ́n ròyìn ohun gbogbo, títí kan àlámọ̀rí àwọn ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù sọ di òǹdè náà. 34  Sì wò ó! gbogbo ìlú ńlá náà jáde wá láti pàdé Jésù; lẹ́yìn tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n fi taratara rọ̀ ọ́ láti lọ kúrò ní àwọn àgbègbè wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé