Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 7:1-29

7  “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́+ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́;  nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́;+ àti òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n fún yín.+  Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?+  Tàbí báwo ni ìwọ ṣe lè sọ fún arákùnrin rẹ pé, ‘Yọ̀ǹda fún mi láti yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú rẹ’; nígbà tí, wò ó! igi ìrólé kan ń bẹ nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?+  Alágàbàgebè! Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.  “Ẹ má ṣe fi ohun tí ó jẹ́ mímọ́ fún àwọn ajá,+ bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe sọ àwọn péálì yín síwájú àwọn ẹlẹ́dẹ̀, kí wọ́n má bàa tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀+ lábẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n sì yíjú padà, kí wọ́n sì fà yín ya.  “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè,+ a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn,+ a ó sì ṣí i fún yín.  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà,+ àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún.  Ní tòótọ́, ta ni ọkùnrin náà láàárín yín, tí ọmọ+ rẹ̀ béèrè búrẹ́dì—òun kì yóò fi òkúta lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 10  Tàbí, bóyá, òun yóò béèrè ẹja—òun kì yóò fi ejò lé e lọ́wọ́, yóò ha ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 11  Nítorí náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú,+ bá mọ bí a ṣe ń fi àwọn ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi àwọn ohun rere+ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀! 12  “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín,+ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn; ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.+ 13  “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé;+ nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; 14  nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.+ 15  “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké+ tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú aṣọ àgùntàn,+ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò.+ 16  Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀.+ Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti ara òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?+ 17  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde;+ 18  igi rere kò lè so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. 19  Gbogbo igi tí kì í mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀, tí a ó sì sọ sínú iná.+ 20  Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.+ 21  “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe+ ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.+ 22  Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa,+ àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’+ 23  Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí!+ Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.+ 24  “Nítorí náà, olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.+ 25  Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. 26  Síwájú sí i, gbogbo ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí kì í sì í ṣe+ wọ́n ni a ó fi wé òmùgọ̀ ọkùnrin,+ ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. 27  Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì kọlu ilé náà,+ ó sì ya lulẹ̀, ìwólulẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀.”+ 28  Wàyí o, nígbà tí Jésù parí àwọn àsọjáde wọ̀nyí, ìyọrísí rẹ̀ ni pé háà ń ṣe+ ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀; 29  nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ,+ kì í sì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin wọn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé