Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 6:1-34

6  “Ẹ ṣọ́ra gidigidi láti má ṣe fi òdodo+ yín ṣe ìwà hù níwájú àwọn ènìyàn kí wọ́n bàa lè ṣàkíyèsí rẹ̀; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ kì yóò ní èrè kankan lọ́dọ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.  Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí o bá ń lọ fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni,+ má ṣe fun kàkàkí+ níwájú rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn alágàbàgebè ti ń ṣe nínú sínágọ́gù àti ní àwọn ojú pópó, kí àwọn ènìyàn lè yìn wọ́n lógo. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.  Ṣùgbọ́n ìwọ, nígbà tí o bá ń fi àwọn ẹ̀bùn àánú fúnni, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe,  kí àwọn ẹ̀bùn àánú rẹ lè wà ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.+  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn alágàbàgebè; nítorí wọ́n fẹ́ láti máa gbàdúrà ní dídúró+ nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun oríta, kí àwọn ènìyàn bàa lè rí wọn.+ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún.  Ìwọ, bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ+ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀;+ nígbà náà Baba rẹ tí ń ríran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.  Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.  Nítorí náà, ẹ má ṣe dà bí wọn, nítorí Ọlọ́run tí í ṣe Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní+ kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.  “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí:+ “‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ+ rẹ di sísọ di mímọ́.+ 10  Kí ìjọba+ rẹ dé. Kí ìfẹ́+ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.+ 11  Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní;+ 12  kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.+ 13  Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò,+ ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’+ 14  “Nítorí bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú;+ 15  nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.+ 16  “Nígbà tí ẹ bá ń gbààwẹ̀,+ ẹ dẹ́kun fífajúro bí àwọn alágàbàgebè, nítorí wọn a máa ba ojú wọn jẹ́ kí wọ́n lè fara han àwọn ènìyàn pé wọ́n ń gbààwẹ̀.+ Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Wọ́n ń gba èrè wọn ní kíkún. 17  Ṣùgbọ́n ìwọ, nígbà tí o bá ń gbààwẹ̀, fi gírísì pa orí rẹ, kí o sì bọ́ ojú rẹ,+ 18  kí ìwọ má bàa fara hàn pé ènìyàn ni o ń gbààwẹ̀ fún, bí kò ṣe Baba rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀;+ nígbà náà, Baba rẹ tí ń wòran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ. 19  “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín+ lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. 20  Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run,+ níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run,+ àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè. 21  Nítorí pé ibi tí ìṣúra rẹ bá wà, ibẹ̀ ni ọkàn-àyà rẹ yóò wà pẹ̀lú. 22  “Fìtílà ara ni ojú.+ Nígbà náà, bí ojú rẹ bá mú ọ̀nà kan, gbogbo ara rẹ yóò mọ́lẹ̀ yòò; 23  ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá burú,+ gbogbo ara rẹ yóò ṣókùnkùn. Bí ó bá jẹ́ pé ní tòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú rẹ jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn yẹn mà pọ̀ o!+ 24  “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì,+ tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.+ 25  “Ní tìtorí èyí, mo wí fún yín pé: Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn+ nípa ọkàn yín, ní ti ohun tí ẹ ó jẹ tàbí ohun tí ẹ ó mu, tàbí nípa ara yín, ní ti ohun tí ẹ ó wọ̀.+ Ọkàn kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ àti ara ju aṣọ lọ?+ 26  Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ+ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?+ 27  Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?+ 28  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní ti ọ̀ràn ti aṣọ, èé ṣe tí ẹ fi ń ṣàníyàn? Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n lára àwọn òdòdó lílì+ pápá, bí wọ́n ṣe ń dàgbà; wọn kì í ṣe làálàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í rànwú; 29  ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Sólómọ́nì+ pàápàá nínú gbogbo ògo rẹ̀ ni a kò ṣe ní ọ̀ṣọ́ bí ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. 30  Wàyí o, bí Ọlọ́run bá wọ ewéko pápá láṣọ báyìí, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí, tí a sì sọ sínú ààrò ní ọ̀la, òun kì yóò ha kúkú wọ̀ yín láṣọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?+ 31  Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé,+ kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ 32  Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+ 33  “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀+ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.+ 34  Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la,+ nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé