Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 5:1-48

5  Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, ó gòkè lọ sí orí òkè ńlá; lẹ́yìn tí ó sì jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀;  ó sì la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé:  “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,+ níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.+  “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, níwọ̀n bí a ó ti tù wọ́n nínú.+  “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù,+ níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.+  “Aláyọ̀ ni àwọn tí ebi ń pa, tí òùngbẹ sì ń gbẹ+ fún òdodo, níwọ̀n bí a ó ti bọ́ wọn yó.+  “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú,+ níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.  “Aláyọ̀ ni àwọn ẹni mímọ́ gaara ní ọkàn-àyà,+ níwọ̀n bí wọn yóò ti rí Ọlọ́run.+  “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà,+ níwọ̀n bí a ó ti pè wọ́n ní ‘ọmọ+ Ọlọ́run.’ 10  “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni+ sí nítorí òdodo, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn. 11  “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn+ yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni+ sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. 12  Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú,+ níwọ̀n bí èrè+ yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì+ tí ó wà ṣáájú yín. 13  “Ẹ̀yin ni iyọ̀+ ilẹ̀ ayé; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá pàdánù okun rẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú adùn-iyọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ sípò? Kò ṣeé lò fún ohunkóhun mọ́, bí kò ṣe kí a dà á sóde,+ kí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. 14  “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.+ Ìlú ńlá kan kò lè fara sin nígbà tí ó bá wà lórí òkè ńlá. 15  Àwọn ènìyàn a tan fìtílà, wọn a sì gbé e kalẹ̀, kì í ṣe sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n,+ bí kò ṣe sórí ọ̀pá fìtílà, a sì tàn sára gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ilé. 16  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kí ìmọ́lẹ̀+ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà+ yín, kí wọ́n sì lè fi ògo+ fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. 17  “Ẹ má ṣe rò pé mo wá láti pa Òfin+ tàbí àwọn Wòlíì run. Èmi kò wá láti pa run, bí kò ṣe láti mú ṣẹ;+ 18  nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò tètè kọjá lọ+ jù kí lẹ́tà kan tí ó kéré jù lọ tàbí kí gínńgín kan lára lẹ́tà kan kọjá lọ kúrò nínú Òfin lọ́nàkọnà kí ohun gbogbo má sì ṣẹlẹ̀.+ 19  Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá rú+ ọ̀kan nínú àwọn àṣẹ kékeré jù lọ wọ̀nyí, tí ó sì ń kọ́ aráyé láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni a ó pè ní ‘ẹni kékeré jù lọ’ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọba ọ̀run.+ Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń fi wọ́n kọ́ni,+ ẹni yìí ni a ó pè ní ‘ẹni ńlá’+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọba ọ̀run. 20  Nítorí mo wí fún yín pé bí òdodo yín kò bá pọ̀ gidigidi ju ti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí,+ lọ́nàkọnà ẹ kì yóò wọ+ ìjọba ọ̀run. 21  “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn;+ ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá ṣìkà pànìyàn+ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́.’+ 22  Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú+ sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn+ fún kóòtù ìgbẹ́jọ́; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ ìfojú-tín-ín-rín tí kò ṣeé fẹnu sọ sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún Kóòtù Gíga Jù Lọ; nígbà tí ó jẹ́ pé, ẹnì yòówù tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ òkúùgbẹ́!’ yóò yẹ fún Gẹ̀hẹ́nà oníná.+ 23  “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ,+ tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ,+ 24  fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà,+ ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.+ 25  “Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá pẹ̀lú ẹni tí ń fi ọ́ sùn lábẹ́ òfin, nígbà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ lójú ọ̀nà sí ibẹ̀, pé lọ́nà kan ṣáá, kí afinisùn+ náà má bàa fi ọ́ lé onídàájọ́ lọ́wọ́, kí onídàájọ́ sì fi ọ́ lé ẹmẹ̀wà inú kóòtù lọ́wọ́, kí a sì sọ ọ́ sí ẹ̀wọ̀n. 26  Mo wí fún ọ ní tòótọ́, Dájúdájú, ìwọ kì yóò kúrò níbẹ̀ títí ìwọ yóò fi san ẹyọ owó tí ó kù, tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an.+ 27  “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’+ 28  Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan+ láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà+ pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.+ 29  Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara rẹ ju kí a gbé gbogbo ara rẹ sọ+ sínú Gẹ̀hẹ́nà. 30  Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń mú ọ kọsẹ̀, ké e kúrò, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+ Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà-ara rẹ ju kí gbogbo ara rẹ balẹ̀ sínú Gẹ̀hẹ́nà. 31  “Síwájú sí i, a sọ ọ́ pé, ‘Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀,+ kí ó fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀.’+ 32  Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe ní tìtorí àgbèrè,+ sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu panṣágà,+ ẹnì yòówù tí ó bá sì gbé obìnrin tí a kọ̀ sílẹ̀ níyàwó, ṣe panṣágà.+ 33  “Ẹ tún gbọ́ pé a sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra+ láìmúṣẹ, ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’+ 34  Bí ó ti wù kí ó rí, èmi wí fún yín pé: Má ṣe búra+ rárá, yálà fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́+ Ọlọ́run ni; 35  tàbí ilẹ̀ ayé, nítorí àpótí ìtìsẹ̀+ fún ẹsẹ̀ rẹ̀ ni; tàbí Jerúsálẹ́mù, nítorí pé ìlú ńlá+ ti Ọba ńlá náà ni. 36  Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, nítorí pé ìwọ kò lè sọ irun kan di funfun tàbí dúdú. 37  Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́;+ nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.+ 38  “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’+ 39  Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Má ṣe dúró tiiri lòdì sí ẹni burúkú; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún,+ yí èkejì sí i pẹ̀lú. 40  Bí ẹnì kan bá sì fẹ́ mú ọ lọ sí kóòtù, kí ó sì gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ pẹ̀lú lọ sọ́wọ́ rẹ̀;+ 41  bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá sì fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.+ 42  Fi fún ẹni tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ, má sì ṣe yí kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó fẹ́ yá lọ́wọ́ rẹ láìsí èlé.+ 43  “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ,+ kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’+ 44  Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín+ àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín;+ 45  kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run,+ níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.+ 46  Nítorí bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè wo ni ẹ ní?+ Àwọn agbowó orí kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? 47  Bí ẹ bá sì kí àwọn arákùnrin yín nìkan, ohun àrà ọ̀tọ̀ wo ni ẹ ń ṣe? Àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú kò ha ń ṣe ohun kan náà bí? 48  Kí ẹ jẹ́ pípé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, bí Baba yín ọ̀run ti jẹ́ pípé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé