Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 4:1-25

4  Nígbà náà ni ẹ̀mí ṣamọ̀nà Jésù lọ sínú aginjù+ kí Èṣù lè dẹ ẹ́ wò.+  Lẹ́yìn tí ó ti gbààwẹ̀ ogójì ọ̀sán àti ogójì òru,+ ebi wá ń pa á.  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Adẹniwò+ náà dé, ó sì wí fún un pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run,+ sọ fún àwọn òkúta wọ̀nyí pé kí wọ́n di àwọn ìṣù búrẹ́dì.”  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, òun wí pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’”+  Lẹ́yìn náà ni Èṣù mú un lọ sí ìlú ńlá mímọ́,+ ó sì mú un dúró lórí odi orí òrùlé tẹ́ńpìlì,  ó sì wí fún un pé: “Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, fi ara rẹ sọ̀kò sílẹ̀;+ nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Òun yóò pàṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, àti pé wọn yóò gbé ọ ní ọwọ́ wọn, kí ìwọ má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta nígbà kankan.’”+  Jésù wí fún un pé: “A tún kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run rẹ wò.’”+  Èṣù tún mú un lọ sí òkè ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo ìjọba ayé+ àti ògo wọn hàn án,  ó sì wí fún un pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú+ bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.”+ 10  Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo+ sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’”+ 11  Nígbà náà ni Èṣù fi í sílẹ̀,+ sì wò ó! àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún un.+ 12  Wàyí o, nígbà tí ó gbọ́ pé a ti fi àṣẹ ọba mú Jòhánù,+ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Gálílì.+ 13  Síwájú sí i, lẹ́yìn fífi Násárétì sílẹ̀, ó wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Kápánáúmù+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní àgbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì,+ 14  kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: 15  “Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní ìhà kejì Jọ́dánì, Gálílì+ àwọn orílẹ̀-èdè! 16  àwọn ènìyàn tí ó jókòó nínú òkùnkùn+ rí ìmọ́lẹ̀ ńlá kan,+ àti ní ti àwọn tí ó jókòó ní ẹkùn ilẹ̀ òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀++ sórí wọn.” 17  Láti ìgbà náà lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ wíwàásù, ó sì ń wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà,+ nítorí ìjọba+ ọ̀run ti sún mọ́lé.” 18  Bí ó ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Gálílì, ó rí arákùnrin méjì, Símónì+ tí à ń pè ní Pétérù+ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n ń rọ àwọ̀n ìpẹja sínú òkun, nítorí wọ́n jẹ́ apẹja. 19  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, ṣe ni èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.”+ 20  Kíá, ní pípa àwọn àwọ̀n náà tì,+ wọ́n tẹ̀ lé e. 21  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní lílọ láti ibẹ̀, ó rí àwọn méjì mìíràn+ tí wọ́n jẹ́ arákùnrin, Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè+ àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀, nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, ó sì pè wọ́n. 22  Kíá, ní fífi ọkọ̀ ojú omi náà àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé e. 23  Lẹ́yìn náà, ó lọ yí ká+ jákèjádò Gálílì,+ ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn,+ ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn+ àti gbogbo onírúurú àìlera ara láàárín àwọn ènìyàn. 24  Ìròyìn nípa rẹ̀ sì jáde lọ sí gbogbo Síríà;+ wọ́n sì mú gbogbo àwọn tí nǹkan kò sàn fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀,+ àwọn tí onírúurú òkùnrùn àti ìjoró ń wàhálà, àwọn tí ẹ̀mí èṣù sọ di òǹdè àti alárùn wárápá àti àwọn alárùn ẹ̀gbà,+ ó sì wò wọ́n sàn. 25  Nítorí náà, ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e láti Gálílì+ àti Dekapólì àti Jerúsálẹ́mù+ àti Jùdíà àti láti ìhà kejì Jọ́dánì.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé