Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 3:1-17

3  Ní ọjọ́ wọnnì, Jòhánù Oníbatisí+ wá ń wàásù ní aginjù+ Jùdíà,  wí pé: “Ẹ ronú pìwà dà,+ nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”+  Èyí, ní ti tòótọ́, ni ẹni tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì+ ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń ké jáde ní aginjù pé, ‘Ẹ palẹ̀+ ọ̀nà Jèhófà mọ́! Ẹ mú àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.’”  Ṣùgbọ́n Jòhánù yìí gan-an ni aṣọ rẹ̀ jẹ́ irun ràkúnmí+ àti àmùrè awọ+ yí ká abẹ́nú rẹ̀; oúnjẹ rẹ̀ pẹ̀lú jẹ́ eéṣú+ àti oyin ìgàn.+  Nígbà náà ni Jerúsálẹ́mù àti gbogbo Jùdíà àti gbogbo ìgbèríko tí ó wà yí ká Jọ́dánì jáde lọ bá a,  ó sì batisí àwọn ènìyàn ní Odò Jọ́dánì,+ tí wọ́n ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.  Nígbà tí ó tajú kán rí ọ̀pọ̀ lára àwọn Farisí àti Sadusí+ tí ń wá fún ìbatisí, ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ ta ní fi tó yín létí láti sá kúrò nínú ìrunú tí ń bọ̀?+  Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ mú èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà jáde;+  kí ẹ má sì kùgbù láti sọ fún ara yín pé, ‘Àwa ní Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí baba.’+ Nítorí mo wí fún yín pé Ọlọ́run lè gbé àwọn ọmọ dìde fún Ábúráhámù+ láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí. 10  Nísinsìnyí, àáké+ ń bẹ níbi gbòǹgbò àwọn igi; nígbà náà, gbogbo igi tí kò bá mú èso àtàtà jáde ni a ó ké lulẹ̀,+ tí a óò sì sọ sínú iná.+ 11  Èmi, ní tèmi, ń fi omi batisí+ yín nítorí ìrònúpìwàdà yín;+ ṣùgbọ́n ẹni tí ń bọ̀+ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí èmi kò tó láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀ kúrò.+ Ẹni yẹn yóò fi ẹ̀mí mímọ́+ àti iná+ batisí yín. 12  Ṣọ́bìrì ìfẹ́kà rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, yóò sì gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tóní-tóní, yóò sì kó àlìkámà rẹ̀ jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́,+ ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná tí kò ṣeé pa sun.”+ 13  Lẹ́yìn náà, Jésù wá láti Gálílì+ sí Jọ́dánì sọ́dọ̀ Jòhánù, kí ó lè batisí+ òun. 14  Ṣùgbọ́n ẹni yẹn gbìyànjú láti dá a dúró, ní wíwí pé: “Èmi ni ó yẹ kí a batisí láti ọwọ́ rẹ, ìwọ ha sì ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ mi bí?” 15  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún un pé: “Jọ̀wọ́ rẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí, nítorí ní ọ̀nà yẹn ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo èyí tí ó jẹ́ òdodo ṣẹ.”+ Nígbà náà ni ó ṣíwọ́ dídá a dúró. 16  Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀ Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀,+ ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà+ bọ̀ wá sórí rẹ̀.+ 17  Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn+ kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi,+ olùfẹ́ ọ̀wọ́n,+ ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé