Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 28:1-20

28  Lẹ́yìn sábáàtì, nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀ ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, Màríà Magidalénì àti Màríà kejì wá láti wo sàréè náà.+  Sì kíyèsí i! ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà kan ti sẹ̀; nítorí áńgẹ́lì Jèhófà ti sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì wá yí òkúta náà kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀.+  Ìrísí òde ara rẹ̀ rí bí mànàmáná,+ aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìrì dídì.+  Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀, àwọn olùṣọ́ wárìrì, wọ́n sì dà bí òkú ènìyàn.  Ṣùgbọ́n ní ìdáhùn áńgẹ́lì+ náà wí fún àwọn obìnrin náà pé: “Ẹ má bẹ̀rù, nítorí mo mọ̀ pé Jésù+ tí a kàn mọ́gi ni ẹ ń wá.  Kò sí níhìn-ín, nítorí a ti gbé e dìde,+ gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wá, ẹ wo ibi tí a tẹ́ ẹ sí.  Ẹ sì lọ ní kíákíá, kí ẹ sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé a ti gbé e+ dìde kúrò nínú òkú, sì wò ó! ó ń lọ ṣáájú yín sí Gálílì;+ ẹ óò rí i níbẹ̀. Wò ó! Mo ti sọ fún yín.”+  Nítorí náà, ní fífi ibojì ìrántí náà sílẹ̀ ní kíá pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìdùnnú ńláǹlà, wọ́n sáré lọ ròyìn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.+  Sì wò ó! Jésù pàdé wọn, ó sì wí pé: “Ẹ kú déédéé ìwòyí o!” Wọ́n sún mọ́ ọn, wọ́n sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wárí fún un. 10  Jésù wá wí fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi,+ kí wọ́n lè lọ sí Gálílì; wọn yóò sì rí mi níbẹ̀.” 11  Nígbà tí wọ́n ń lọ ní ọ̀nà wọn, wò ó! àwọn kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́+ náà wọ ìlú ńlá náà, wọ́n sì ròyìn gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí àlùfáà. 12  Lẹ́yìn tí àwọn wọ̀nyí sì ti kóra jọpọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbà ọkùnrin, tí wọ́n sì ti gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ ogun náà ní iye ẹyọ fàdákà tí ó pọ̀ tó,+ 13  wọ́n sì wí pé: “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ ẹ̀yìn+ rẹ̀ wá ní òru, wọ́n sì jí i gbé nígbà tí a ń sùn.’ 14  Bí èyí bá sì dé etí-ìgbọ́ gómìnà, dájúdájú, àwa yóò yí i lérò padà, a ó sì gbà yín sílẹ̀ kúrò nínú ìdààmú-ọkàn.” 15  Nítorí náà, wọ́n gba àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì ṣe bí a ti fún wọn ní ìtọ́ni; àsọjáde yìí sì ti tàn káàkiri láàárín àwọn Júù títí di òní yìí gan-an. 16  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá lọ sí Gálílì+ sí òkè ńlá níbi tí Jésù ti ṣètò fún wọn, 17  nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n wárí, ṣùgbọ́n àwọn kan ṣiyèméjì.+ 18  Jésù sì sún mọ́ tòsí, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀, pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ+ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. 19  Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè+ di ọmọ ẹ̀yìn,+ ẹ máa batisí+ wọn ní orúkọ Baba+ àti ti Ọmọ+ àti ti ẹ̀mí mímọ́,+ 20  ẹ máa kọ́+ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín+ mọ́.+ Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín+ ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé