Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 26:1-75

26  Wàyí o, nígbà tí Jésù ti parí gbogbo àsọjáde wọ̀nyí, ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé:  “Ẹ mọ̀ pé ọjọ́ méjì òní, ìrékọjá yóò wáyé,+ a ó sì fa Ọmọ ènìyàn léni lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.”+  Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà kóra jọpọ̀ nínú àgbàlá àlùfáà àgbà tí a ń pè ní Káyáfà,+  wọ́n sì gbìmọ̀+ pọ̀ láti fi ọgbọ́n àrékérekè gbá Jésù mú, kí wọ́n sì pa á.  Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n ń sọ ṣáá pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀, kí ìrọ́kẹ̀kẹ̀ kankan má bàa dìde láàárín àwọn ènìyàn.”+  Nígbà tí ó ṣẹlẹ̀ pé Jésù wà ní Bẹ́tánì+ ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+  obìnrin kan tí ó ní orùba alabásítà ti òróró onílọ́fínńdà olówó iyebíye+ tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dà á sí orí rẹ̀ bí ó ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì.  Nígbà tí wọ́n rí èyí, ìkannú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ru, wọ́n sì wí pé: “Kí ní fa ìfiṣòfò yìí?+  Nítorí à bá ti ta èyí ní iye púpọ̀ gan-an, kí a sì fi fún àwọn òtòṣì.”+ 10  Ní mímọ èyí,+ Jésù wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń gbìyànjú láti da obìnrin náà láàmú? Nítorí ó ṣe iṣẹ́ tí ó dára púpọ̀ sí mi.+ 11  Nítorí ẹ ní àwọn òtòṣì+ pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n ẹ kì yóò ní mi nígbà gbogbo.+ 12  Nítorí nígbà tí obìnrin yìí fi òróró onílọ́fínńdà yìí sí ara mi, ó ṣe é fún ìmúra mi sílẹ̀ fún ìsìnkú.+ 13  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ibikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere yìí ní gbogbo ayé, ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a ó sọ pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”+ 14  Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá náà, ẹni tí a ń pè ní Júdásì Ísíkáríótù,+ lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà 15  ó sì wí pé: “Kí ni ẹ óò fún mi láti fi í lé yín lọ́wọ́?”+ Wọ́n ṣe àdéhùn pàtó láti fún un ní ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà.+ 16  Nítorí náà, láti ìgbà náà lọ, ó tẹra mọ́ wíwá àyè ṣíṣí sílẹ̀ tí ó dára láti fi í lé wọn lọ́wọ́.+ 17  Ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú,+ àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n wí pé: “Ibo ni o fẹ́ kí a múra sílẹ̀ fún ọ láti jẹ ìrékọjá?”+ 18  Ó wí pé: “Ẹ lọ sínú ìlú ńlá náà, sọ́dọ̀ Lágbájá+ kí ẹ sì wí fún un pé, Olùkọ́ wí pé, ‘Àkókò mi tí a yàn kalẹ̀ ti sún mọ́lé; dájúdájú, èmi yóò ṣe ayẹyẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’”+ 19  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn, wọ́n sì pèsè àwọn nǹkan sílẹ̀ fún ìrékọjá náà.+ 20  Wàyí o, nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́,+ ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá.+ 21  Bí wọ́n ti ń jẹun, ó wí pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọ̀kan nínú yín yóò dà mí.”+ 22  Bí ẹ̀dùn-ọkàn ti bá wọn gidigidi látàrí èyí, gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe èmi, àbí èmi ni?”+ 23  Ní ìfèsìpadà, ó wí pé: “Ẹni tí ó tẹ ọwọ́ rẹ̀ bọ àwo kòtò pẹ̀lú mi ni ẹni tí yóò dà mí.+ 24  Lóòótọ́, Ọmọ ènìyàn ń lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé+ nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé+ ni fún ọkùnrin yẹn tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ ènìyàn léni lọ́wọ́!+ Ì bá ti sàn fún un ká ní a kò bí ọkùnrin yẹn.” 25  Ní ọ̀nà ìfèsìpadà, Júdásì, ẹni tí ó máa tó dà á, wí pé: “Kì í ṣe èmi, àbí èmi ni, Rábì?” Ó wí fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i.” 26  Bí wọ́n ti ń jẹun lọ, Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan,+ lẹ́yìn sísúre, ó sì bù ú,+ ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: “Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 27  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife+ kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó fi í fún wọn, ó wí pé: “Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín;+ 28  nítorí èyí túmọ̀ sí+ ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’+ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn+ fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+ 29  Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín, dájúdájú, èmi kì yóò mu èyíkéyìí nínú àmújáde àjàrà yìí lọ́nàkọnà láti ìsinsìnyí lọ títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí èmi yóò mu ún ní tuntun pẹ̀lú yín nínú ìjọba Baba mi.”+ 30  Níkẹyìn, lẹ́yìn kíkọrin ìyìn,+ wọ́n jáde lọ sí Òkè Ńlá Ólífì.+ 31  Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé: “Gbogbo yín ni a óò mú kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní òru yìí, nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò kọlu olùṣọ́ àgùntàn, àwọn àgùntàn agbo ni a ó sì tú ká káàkiri.’+ 32  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a bá ti gbé mi dìde, dájúdájú, èmi yóò lọ ṣáájú yín sí Gálílì.”+ 33  Ṣùgbọ́n Pétérù, ní ìdáhùn, wí fún un pé: “Bí a bá tilẹ̀ mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, dájúdájú, a kì yóò mú èmi kọsẹ̀ láé!”+ 34  Jésù wí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Ní òru yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+ 35  Pétérù wí fún un pé: “Àní bí mo bá ní láti kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, dájúdájú, èmi kì yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ lọ́nàkọnà.” Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù pẹ̀lú sọ ohun kan náà.+ 36  Nígbà náà ni Jésù bá wọn wá sí ibi+ tí a ń pè ní Gẹtisémánì, ó sì wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí èmi yóò kọjá lọ sí ọ̀hún lọ gbàdúrà.”+ 37  Ní mímú Pétérù àti àwọn ọmọkùnrin Sébédè méjèèjì+ lọ́wọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ẹ̀dùn-ọkàn, ó sì dààmú gidigidi.+ 38  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, àní títí dé ikú.+ Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà pẹ̀lú mi.”+ 39  Bí ó sì ti lọ síwájú díẹ̀, ó dojú bolẹ̀, ó ń gbàdúrà,+ ó sì ń wí pé: “Baba mi, bí ó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kí ife+ yìí ré mi kọjá lọ. Síbẹ̀, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́,+ bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.”+ 40  Ó sì wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń sùn, ó sì wí fún Pétérù pé: “Ṣé ẹ kò tilẹ̀ lè ṣọ́nà pẹ̀lú mi fún wákàtí kan péré ni?+ 41  Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,+ kí ẹ sì máa gbàdúrà+ nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.+ Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”+ 42  Fún ìgbà kejì,+ ó tún lọ, ó sì gbàdúrà, ó wí pé: “Baba mi, bí kò bá ṣeé ṣe fún èyí láti ré kọjá lọ àyàfi bí mo bá mu ún, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ.”+ 43  Ó sì tún wá bá wọn tí wọ́n ń sùn, nítorí ojú wọn wúwo fún oorun.+ 44  Nítorí náà, ní fífi wọ́n sílẹ̀, ó tún lọ, ó sì gbàdúrà ní ìgbà kẹta, ó sọ ọ̀rọ̀ kan náà lẹ́ẹ̀kan sí i.+ 45  Nígbà náà ni ó wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Wò ó! Wákàtí náà ti sún mọ́lé tí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.+ 46  Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ. Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.”+ 47  Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! Júdásì,+ ọ̀kan lára àwọn méjìlá, dé àti ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ní idà+ àti ọ̀gọ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà.+ 48  Wàyí o, afinihàn rẹ̀ ti fún wọn ní àmì kan, pé: “Ẹnì yòówù tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; ẹ fi í sínú ìhámọ́.”+ 49  Bí ó sì ti lọ tààràtà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé: “Kú déédéé ìwòyí o, Rábì!”+ ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu+ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an. 50  Ṣùgbọ́n Jésù+ wí fún un pé: “Àwé, fún ète wo ni ìwọ fi wà níhìn-ín?” Nígbà náà ni wọ́n wá síwájú, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé Jésù, wọ́n sì fi í sínú ìhámọ́.+ 51  Ṣùgbọ́n, wò ó! ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ dànù.+ 52  Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀,+ nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.+ 53  Tàbí ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí?+ 54  Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?” 55  Ní wákàtí yẹn, Jésù wí fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà pé: “Ẹ ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀gọ bí ẹní wá bá ọlọ́ṣà láti fi àṣẹ ọba mú mi?+ Láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni mo máa ń jókòó nínú tẹ́ńpìlì+ tí mo ń kọ́ni, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ kò fi mí sínú ìhámọ́. 56  Ṣùgbọ́n gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ kí ìwé mímọ́ àwọn wòlíì lè ṣẹ.”+ Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn pa á tì, wọ́n sì sá lọ.+ 57  Àwọn tí wọ́n fi Jésù sínú ìhámọ́ mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà+ àlùfáà àgbà, níbi tí àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbà ọkùnrin kóra jọpọ̀ sí.+ 58  Ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀ lé e ní òkèèrè réré, títí dé àgbàlá+ àlùfáà àgbà, lẹ́yìn tí ó sì wọlé, ó jókòó pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà inú ilé láti rí àbárèbábọ̀ rẹ̀.+ 59  Láàárín àkókò náà, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sànhẹ́dírìn pátá ń wá ẹ̀rí èké lòdì sí Jésù láti fi ikú pa á,+ 60  ṣùgbọ́n wọn kò rí ọ̀kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí èké wá síwájú.+ Nígbà tí ó ṣe, àwọn méjì wá síwájú, 61  wọ́n sì wí pé: “Ọkùnrin yìí wí pé, ‘Èmi lè wó tẹ́ńpìlì Ọlọ́run palẹ̀, kí n sì kọ́ ọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’”+ 62  Pẹ̀lú ìyẹn, àlùfáà àgbà dìde dúró, ó sì wí fún un pe: “Ṣé ìwọ kò ní ìdáhùn kankan ni? Kí ni ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jẹ́rìí lòdì sí ọ?”+ 63  Ṣùgbọ́n Jésù dákẹ́.+ Nítorí náà, àlùfáà àgbà wí fún un pé: “Mo fi Ọlọ́run alààyè mú kí o wá sábẹ́ ìbúra+ láti sọ fún wa yálà ìwọ ni Kristi+ Ọmọ Ọlọ́run!” 64  Jésù wí+ fún un pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i.+ Síbẹ̀ mo wí fún yín pé, Láti ìsinsìnyí lọ,+ ẹ óò rí Ọmọ ènìyàn+ tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún+ agbára, tí yóò sì máa bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run.”+ 65  Nígbà náà ni àlùfáà àgbà fa ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ ya, ó wí pé: “Ó ti sọ̀rọ̀ òdì!+ Kí ni a tún nílò àwọn ẹlẹ́rìí fún?+ Ẹ wò ó! Nísinsìnyí, ẹ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà.+ 66  Kí ni èrò yín?” Wọ́n dáhùn padà pé: “Ó yẹ fún ikú.”+ 67  Nígbà náà ni wọ́n tutọ́ sí ojú rẹ̀+ wọ́n sì lù+ ú ní ẹ̀ṣẹ́. Àwọn mìíràn gbá a lójú,+ 68  wọ́n wí pé: “Sọ tẹ́lẹ̀ fún wa, ìwọ Kristi.+ Ta ni ẹni tí ó gbá ọ?”+ 69  Wàyí o, Pétérù jókòó lóde nínú àgbàlá náà; ìránṣẹ́bìnrin kan sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú Jésù ará Gálílì!”+ 70  Ṣùgbọ́n ó sẹ́ níwájú gbogbo wọn, pé: “Èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” 71  Lẹ́yìn tí ó ti jáde lọ sí ilé ẹnubodè, ọmọdébìnrin mìíràn ṣàkíyèsí rẹ̀, ó sì wí fún àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ pé: “[Ọkùnrin] yìí wà pẹ̀lú Jésù ará Násárétì.”+ 72  Ó sì tún sẹ́, pẹ̀lú ìbúra pé: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!”+ 73  Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, àwọn tí wọ́n dúró ní àyíká wá, wọ́n sì wí fún Pétérù pé: “Dájúdájú, ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára wọn, nítorí, ní ti tòótọ́, ẹ̀ka èdè rẹ tú ọ fó.”+ 74  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí gégùn-ún, ó sì ń búra pé: “Èmi kò mọ ọkùnrin náà!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ sì kọ.+ 75  Pétérù sì rántí àsọjáde tí Jésù sọ, èyíinì ni: “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+ Ó sì bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé