Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 25:1-46

25  “Nígbà náà, ìjọba ọ̀run yóò wá dà bí wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn,+ tí wọ́n sì jáde lọ láti pàdé ọkọ ìyàwó.+  Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ òmùgọ̀,+ márùn-ún sì jẹ́ olóye.+  Nítorí àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú òróró pẹ̀lú wọn,  nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn olóye mú òróró sínú kòlòbó wọn pẹ̀lú fìtílà wọn.  Nígbà tí ọkọ ìyàwó ń pẹ́, gbogbo wọ́n tòògbé, wọ́n sì sùn lọ.+  Ní àárín òru gan-an, igbe ta,+ ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n láti pàdé rẹ̀.’  Nígbà náà ni gbogbo wúńdíá wọnnì dìde, wọ́n sì mú fìtílà+ wọn wà létòletò.  Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín,+ nítorí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.’  Àwọn olóye+ fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dáhùn pé, ‘Bóyá ó lè má tó rárá fún àwa àti ẹ̀yin. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.’ 10  Bí wọ́n tí ń lọ láti rà á, ọkọ ìyàwó dé, àwọn wúńdíá tí wọ́n sì ti gbára dì wọlé pẹ̀lú rẹ̀ síbi àsè ìgbéyàwó náà;+ a sì ti ilẹ̀kùn. 11  Lẹ́yìn ìgbà náà, ìyókù àwọn wúńdíá náà pẹ̀lú dé, wọ́n wí pé, ‘Ọ̀gá, ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’+ 12  Ní ìdáhùn, ó wí pé, ‘Mo sọ òtítọ́ fún yín, èmi kò mọ̀ yín.’+ 13  “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,+ nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.+ 14  “Nítorí ó rí gan-an bí ìgbà tí ọkùnrin kan,+ tí ó máa tó rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀,+ fi ọlá àṣẹ pe àwọn ẹrú rẹ̀, tí ó sì fi àwọn nǹkan ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.+ 15  Ó sì fi tálẹ́ńtì márùn-ún fún ọ̀kan, méjì fún òmíràn, àti ẹyọ kan fún òmíràn síbẹ̀, fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀,+ ó sì lọ sí ìdálẹ̀. 16  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì márùn-ún bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì fi wọ́n ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i.+ 17  Lọ́nà kan náà, ẹni tí ó gba méjì jèrè méjì sí i. 18  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó sì wa ilẹ̀, ó sì fi owó fàdákà ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́. 19  “Lẹ́yìn àkókò gígùn,+ ọ̀gá ẹrú wọnnì dé, ó sì yanjú ìṣírò owó pẹ̀lú wọn.+ 20  Nítorí náà, ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì márùn-ún wá síwájú, ó sì mú àfikún tálẹ́ńtì márùn-ún wá, ó wí pé, ‘Ọ̀gá, ìwọ fi tálẹ́ńtì márùn-ún lé mi lọ́wọ́; wò ó, mo jèrè tálẹ́ńtì márùn-ún sí i.’+ 21  Ọ̀gá rẹ̀ wí fún un pé, ‘O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́!+ Ìwọ jẹ́ olùṣòtítọ́+ lórí ìwọ̀nba àwọn ohun díẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò yàn ọ́ sípò lórí ohun púpọ̀.+ Bọ́ sínú ìdùnnú+ ọ̀gá rẹ.’ 22  Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì méjì wá síwájú, ó sì wí pé, ‘Ọ̀gá, ìwọ fi tálẹ́ńtì méjì lé mi lọ́wọ́; wò ó, mo jèrè tálẹ́ńtì méjì sí i.’+ 23  Ọ̀gá rẹ̀ wí fún un pé, ‘O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́! Ìwọ jẹ́ olùṣòtítọ́ lórí ìwọ̀nba àwọn ohun díẹ̀. Dájúdájú, èmi yóò yàn ọ́ sípò lórí ohun púpọ̀.+ Bọ́ sínú ìdùnnú+ ọ̀gá rẹ.’ 24  “Níkẹyìn, ẹni tí ó gba tálẹ́ńtì kan wá síwájú,+ ó sì wí pé, ‘Ọ̀gá, mo mọ̀ pé afipámúni ni ọ́, tí o ń ká irúgbìn níbi tí o kò ti fúnrúgbìn, tí o sì ń kó jọ níbi tí o kò ti fẹ́kà. 25  Nítorí náà, àyà fò mí,+ mo sì lọ, mo sì fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Ohun tí í ṣe tìrẹ nìyí.’ 26  Ní ìfèsìpadà, ọ̀gá rẹ̀ wí fún un pé, ‘Ẹrú burúkú àti onílọ̀ọ́ra, ìwọ mọ̀, àbí, pé èmi ń ká irúgbìn níbi tí èmi kò ti fúnrúgbìn, mo sì ń kó jọ níbi tí èmi kò ti fẹ́kà? 27  Tóò, nígbà náà, ó yẹ kí ìwọ ti kó àwọn owó fàdákà mi sọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ báǹkì, nígbà tí mo bá sì dé, èmi ì bá wá gba ohun tí ó jẹ́ tèmi pẹ̀lú èlé.+ 28  “‘Nítorí náà, ẹ gba tálẹ́ńtì náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní tálẹ́ńtì mẹ́wàá.+ 29  Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ní, ni a óò fún ní púpọ̀ sí i, yóò sì ní ọ̀pọ̀ yanturu; ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí kò ní, àní ohun tí ó ní ni a ó gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 30  Ẹ sì ju ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun náà síta nínú òkùnkùn lóde. Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.’+ 31  “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn+ bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀,+ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.+ 32  Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀,+ yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀+ ọ̀kan kúrò lára èkejì,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. 33  Yóò sì fi àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún+ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí òsì+ rẹ̀. 34  “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba+ mi ti bù kún,+ ẹ jogún ìjọba+ tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.+ 35  Nítorí ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan láti jẹ;+ òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan láti mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò;+ 36  mo wà ní ìhòòhò,+ ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí. Mo dùbúlẹ̀ àìsàn, ẹ sì bójú tó mi. Mo wà nínú ẹ̀wọ̀n,+ ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi.’ 37  Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá a lóhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì bọ́ ọ, tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́,+ tí a sì fún ọ ní nǹkan láti mu?+ 38  Nígbà wo ni àwa rí ọ ní àjèjì, tí a sì gbà ọ́ pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò, tàbí tí o wà ní ìhòòhò, tí a sì fi aṣọ wọ̀ ọ́? 39  Nígbà wo ni àwa rí ọ tí o ń ṣàìsàn tàbí tí o wà nínú ẹ̀wọ̀n, tí a sì lọ sọ́dọ̀ rẹ?’ 40  Ní ìfèsìpadà, ọba+ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin ti ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ+ nínú àwọn arákùnrin+ mi wọ̀nyí, ẹ ti ṣe é fún mi.’+ 41  “Nígbà náà ni yóò sọ, ẹ̀wẹ̀, fún àwọn tí wọ́n wà ní òsì rẹ̀ pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n kúrò lọ́dọ̀ mi,+ ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, sínú iná àìnípẹ̀kun+ tí a ti pèsè sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.+ 42  Nítorí ebi pa mí, ṣùgbọ́n ẹ kò fún mi ní nǹkan kan láti jẹ,+ òùngbẹ sì gbẹ mí,+ ṣùgbọ́n ẹ kò fún mi ní nǹkan kan láti mu. 43  Mo jẹ́ àjèjì, ṣùgbọ́n ẹ kò gbà mí pẹ̀lú ẹ̀mí aájò àlejò; mo wà ní ìhòòhò, ṣùgbọ́n ẹ kò fi aṣọ wọ̀+ mí; mo ṣàìsàn mo sì wà nínú ẹ̀wọ̀n,+ ṣùgbọ́n ẹ kò tọ́jú mi.’ 44  Nígbà náà ni àwọn pẹ̀lú yóò fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tàbí tí o jẹ́ àjèjì tàbí tí o wà ní ìhòòhò tàbí tí o ń ṣàìsàn tàbí tí o wà nínú ẹ̀wọ̀n, tí a kò sì ṣe ìránṣẹ́ fún ọ?’ 45  Nígbà náà ni yóò fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá wọn lóhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Dé ìwọ̀n tí ẹ̀yin kò ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ó kéré jù lọ wọ̀nyí,+ ẹ kò ṣe é+ fún mi.’+ 46  Àwọn wọ̀nyí yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun,+ ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé