Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 24:1-51

24  Ní lílọ kúrò nísinsìnyí, Jésù wà ní ọ̀nà rẹ̀ kúrò ní tẹ́ńpìlì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá láti fi àwọn ilé tẹ́ńpìlì hàn án.+  Ní ìdáhùnpadà, ó wí fún wọn pé: “Ẹ kò ha rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí bí? Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Lọ́nàkọnà a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yóò sì wó palẹ̀.”+  Bí ó ti jókòó lórí Òkè Ńlá Ólífì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tọ̀ ọ́ wá ní ìdákọ́ńkọ́, wọ́n wí pé: “Sọ fún wa, Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín+ rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”+  Ní ìdáhùn, Jésù sì wí fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnì kankan má ṣì yín lọ́nà;+  nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá ní orúkọ mi, wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà.+  Ẹ óò gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun; ẹ rí i pé ẹ kò jáyà. Nítorí nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.+  “Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè+ àti ìjọba sí ìjọba,+ àìtó oúnjẹ+ àti ìsẹ̀lẹ̀+ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn.  Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.  “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́,+ wọn yóò sì pa yín,+ ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra+ lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.+ 10  Nígbà náà, pẹ̀lú, a óò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn kọsẹ̀,+ wọn yóò sì da ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, wọn yóò sì kórìíra ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì.+ 11  Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké+ yóò sì dìde, wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà;+ 12  àti nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin,+ ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.+ 13  Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fara dà+ á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.+ 14  A ó sì wàásù ìhìn rere+ ìjọba+ yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè;+ nígbà náà ni òpin+ yóò sì dé. 15  “Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá tajú kán rí ohun ìríra+ tí ń ṣokùnfà ìsọdahoro, tí ó dúró ní ibi mímọ́,+ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ nípasẹ̀ Dáníẹ́lì wòlíì, (kí òǹkàwé lo ìfòyemọ̀,) 16  nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ+ sí àwọn òkè ńlá. 17  Kí ẹni tí ó wà ní orí ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ láti kó àwọn ẹrù kúrò nínú ilé rẹ̀; 18  kí ẹni tí ó wà ní pápá má sì padà sí ilé láti mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀. 19  Ègbé ni fún àwọn obìnrin tí ó lóyún àti àwọn tí ń fi ọmú fún ọmọ ọwọ́ ní ọjọ́ wọnnì!+ 20  Ẹ máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà òtútù, tàbí ní ọjọ́ sábáàtì; 21  nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà,+ irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí,+ rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́. 22  Ní ti tòótọ́, láìjẹ́ pé a ké ọjọ́ wọnnì kúrú, kò sí ẹran ara kankan tí à bá gbà là; ṣùgbọ́n ní tìtorí àwọn àyànfẹ́,+ a óò ké ọjọ́ wọnnì kúrú.+ 23  “Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wò ó! Kristi+ nìyí níhìn-ín,’ tàbí, ‘Lọ́hùn-ún!’ ẹ má ṣe gba èyí gbọ́.+ 24  Nítorí àwọn èké Kristi+ àti àwọn èké wòlíì+ yóò dìde, wọn yóò sì fúnni ní àwọn àmì ńláǹlà+ àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, bí ó bá ṣeé ṣe.+ 25  Wò ó! Mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.+ 26  Nítorí náà, bí àwọn ènìyàn bá sọ fún yín pé, ‘Wò ó! Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe jáde lọ; ‘Wò ó! Ó wà nínú àwọn ìyẹ̀wù inú lọ́hùn-un,’ ẹ má ṣe gbà á gbọ́.+ 27  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí mànàmáná+ ti ń jáde wá láti àwọn apá ìlà-oòrùn, tí ó sì ń mọ́lẹ̀ dé àwọn apá ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.+ 28  Ibikíbi tí òkú bá wà, ibẹ̀ ni àwọn idì+ yóò kóra jọpọ̀ sí.+ 29  “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọnnì, oòrùn yóò ṣókùnkùn,+ òṣùpá+ kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn, àwọn ìràwọ̀ yóò sì jábọ́ láti ọ̀run, àwọn agbára ọ̀run ni a ó sì mì.+ 30  Nígbà náà sì ni àmì Ọmọ ènìyàn+ yóò fara hàn ní ọ̀run, nígbà náà sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn nínú ìdárò,+ wọn yóò sì rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ lórí àwọsánmà ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.+ 31  Yóò sì rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde pẹ̀lú ìró ńlá kàkàkí,+ wọn yóò sì kó àwọn àyànfẹ́+ rẹ̀ jọpọ̀ láti inú ẹ̀fúùfù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin,+ láti ìkángun kan ọ̀run sí ìkángun rẹ̀ kejì. 32  “Wàyí o, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé.+ 33  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.+ 34  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ìran+ yìí kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀. 35  Ọ̀run àti ilẹ̀ ayé yóò kọjá lọ,+ ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà.+ 36  “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí+ yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.+ 37  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà+ ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.+ 38  Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà+ wọ ọkọ̀ áàkì;+ 39  wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ,+ bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. 40  Nígbà náà, àwọn ọkùnrin méjì yóò wà nínú pápá:+ a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì; 41  àwọn obìnrin méjì yóò máa lọ nǹkan lórí ọlọ ọlọ́wọ́: a óò mú ọ̀kan lọ, a ó sì pa èkejì tì.+ 42  Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.+ 43  “Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni,+ ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. 44  Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán,+ nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ̀. 45  “Ní ti tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́+ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn sípò lórí àwọn ará ilé rẹ̀, láti fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu?+ 46  Aláyọ̀+ ni ẹrú náà bí ọ̀gá rẹ̀ nígbà tí ó bá dé, bá rí i tí ó ń ṣe bẹ́ẹ̀! 47  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Òun yóò yàn án sípò lórí gbogbo àwọn nǹkan ìní rẹ̀.+ 48  “Ṣùgbọ́n bí ẹrú búburú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ́nrẹ́n pé,+ ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’+ 49  tí ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń jẹ, tí ó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, 50  ọ̀gá ẹrú yẹn yóò dé ní ọjọ́ tí kò fojú sọ́nà fún àti ní wákàtí+ tí kò mọ̀, 51  yóò sì fi ìyà mímúná jù lọ jẹ ẹ́,+ yóò sì yan ipa tirẹ̀ fún un pẹ̀lú àwọn alágàbàgebè. Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé