Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 23:1-39

23  Nígbà náà ni Jésù bá àwọn ogunlọ́gọ̀ àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀,+ pé:  “Àwọn akọ̀wé òfin+ àti àwọn Farisí mú ara wọn jókòó ní ìjókòó Mósè.+  Nítorí náà, gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ+ fún yín, ni kí ẹ ṣe kí ẹ sì pa mọ́, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣe+ wọn, nítorí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe.  Wọ́n di àwọn ẹrù wíwúwo, wọ́n sì gbé wọn lé èjìká àwọn ènìyàn,+ ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò fẹ́ láti fi ìka+ wọn sún wọn kẹ́rẹ́.  Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n ń ṣe kí àwọn ènìyàn lè rí wọn;+ nítorí wọ́n mú àwọn akóló [ìkó-ìwé-mímọ́-sí] fẹ̀,+ èyí tí wọ́n ń dè mọ́ ara láti fi ṣe ìṣọ́rí, wọ́n sì sọ ìṣẹ́tí+ ẹ̀wù wọn di títóbi.  Wọ́n fẹ́ ibi yíyọrí ọlá jù lọ+ níbi oúnjẹ alẹ́ àti àwọn ìjókòó iwájú nínú àwọn sínágọ́gù,+ 7  àti ìkíni+ ní àwọn ibi ọjà àti kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní Rábì.+  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín,+ nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín,+ Ẹni ti ọ̀run. 10  Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’+ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi. 11  Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ òjíṣẹ́ yín.+ 12  Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀,+ ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.+ 13  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ sé ìjọba ọ̀run pa+ níwájú àwọn ènìyàn; nítorí ẹ̀yin+ tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gba àwọn tí wọ́n wà lójú ọ̀nà wọn sí ibẹ̀ láyè láti wọlé. 14  —— 15  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!+ nítorí pé ẹ̀yin a máa la òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ kọjá láti sọ ẹnì kan di aláwọ̀ṣe, nígbà tí ó bá sì di ọ̀kan, ẹ̀yin a sọ ọ́ di olùdojúkọ ewu Gẹ̀hẹ́nà ní ìlọ́po méjì ju ara yín lọ. 16  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú afinimọ̀nà,+ tí ó wí pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, ó wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe.’+ 17  Ẹ̀yin òmùgọ̀ àti afọ́jú! Èwo, ní ti tòótọ́, ni ó tóbi jù, wúrà ni tàbí tẹ́ńpìlì tí ó sọ wúrà di mímọ́?+ 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá fi pẹpẹ búra, kò ṣe nǹkan kan; ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe.’ 19  Ẹ̀yin afọ́jú! Èwo, ní ti tòótọ́, ni ó tóbi jù, ẹ̀bùn ni tàbí pẹpẹ+ tí ó sọ ẹ̀bùn di mímọ́? 20  Nítorí náà, ẹni tí ó bá fi pẹpẹ búra ń fi í búra àti ohun gbogbo tí ó wà lórí rẹ̀; 21  ẹni tí ó bá sì fi tẹ́ńpìlì búra ń fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀;+ 22  ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra ń fi ìtẹ́ Ọlọ́run+ àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra. 23  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá+ efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì, ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo+ àti àánú+ àti ìṣòtítọ́.+ Àwọn ohun wọ̀nyí pọndandan ní ṣíṣe, síbẹ̀ àwọn ohun yòókù ni kí ẹ má ṣàìkà sí. 24  Ẹ̀yin afọ́jú afinimọ̀nà,+ tí ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí+ ṣùgbọ́n tí ń gbé ràkúnmí mì kàló!+ 25  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ fọ òde ife+ àti àwopọ̀kọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún ìpiyẹ́+ àti àìmọníwọ̀n. 26  Farisí afọ́jú,+ kọ́kọ́ fọ inú ife+ àti àwopọ̀kọ́ mọ́, kí òde rẹ̀ pẹ̀lú le di èyí tí ó mọ́. 27  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!+ nítorí pé ẹ jọ àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun,+ tí wọ́n fara hàn lóde bí ẹlẹ́wà ní tòótọ́ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn àti gbogbo onírúurú ohun àìmọ́. 28  Ní ọ̀nà yẹn, ẹ̀yin pẹ̀lú, ní tòótọ́, fara hàn lóde bí olódodo sí àwọn ènìyàn,+ ṣùgbọ́n ní inú, ẹ kún fún àgàbàgebè àti ìwà-àìlófin. 29  “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!+ nítorí pé ẹ kọ́ sàréè àwọn wòlíì, ẹ sì ṣe ibojì ìrántí àwọn olódodo lọ́ṣọ̀ọ́,+ 30  ẹ sì wí pé, ‘Ì bá ṣe pé àwa wà ní àwọn ọjọ́ àwọn baba ńlá wa, àwa kì bá jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì.’+ 31  Nítorí náà, ẹ ń jẹ́rìí lòdì sí ara yín pé ẹ̀yin jẹ́ ọmọ àwọn tí wọ́n ṣìkà pa àwọn wòlíì.+ 32  Tóò, nígbà náà, ẹ mú òṣùwọ̀n+ àwọn baba ńlá yín kún. 33  “Ẹ̀yin ejò, ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo ni ẹ ó ṣe sá kúrò nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?+ 34  Fún ìdí yìí, ní báyìí èmi ń rán+ àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn àti àwọn olùkọ́ni ní gbangba jáde sí yín.+ Àwọn kan lára wọn ni ẹ ó pa,+ tí ẹ ó sì kàn mọ́gi, àwọn kan lára wọn ni ẹ ó sì nà lọ́rẹ́+ nínú àwọn sínágọ́gù yín, tí ẹ ó sì ṣe inúnibíni sí láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá; 35  kí gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí a ti ta sílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lè wá sórí yín,+ láti ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì+ olódodo+ títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà ọmọkùnrin Barakáyà, ẹni tí ẹ ṣìkà pa láàárín ibùjọsìn àti pẹpẹ.+ 36  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wá sórí ìran yìí.+ 37  “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, olùpa àwọn wòlíì+ àti olùsọ àwọn tí a rán sí i+ lókùúta,+—iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀!+ Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ.+ 38  Wò ó! A pa ilé yín+ tì fún yín.+ 39  Nítorí mo wí fún yín pé, Ẹ kì yóò rí mi lọ́nàkọnà láti ìsinsìnyí lọ títí ẹ ó fi wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé