Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 22:1-46

22  Ní fífèsì síwájú sí i, Jésù tún fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí pé:+  “Ìjọba ọ̀run ti wá dà bí ọkùnrin kan, ọba kan, tí ó se àsè ìgbéyàwó+ fún ọmọkùnrin rẹ̀.  Ó sì rán àwọn ẹrú rẹ̀ jáde láti pe àwọn tí a ti ké sí fún àsè ìgbéyàwó náà,+ ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá.+  Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn jáde,+ wí pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí a ti ké sí pé: “Wò ó! Mo ti pèsè oúnjẹ mi sílẹ̀,+ a ti pa àwọn akọ màlúù àti àwọn ẹran àbọ́sanra mi, gbogbo nǹkan sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá síbi àsè ìgbéyàwó.”’+  Ṣùgbọ́n láìbìkítà, wọ́n jáde lọ, ọ̀kan sí pápá tirẹ̀, òmíràn sẹ́nu iṣẹ́ òwò rẹ̀;+  ṣùgbọ́n àwọn yòókù, ní gbígbá àwọn ẹrú rẹ̀ mú, hùwà sí wọn lọ́nà àfojúdi, wọ́n sì pa wọ́n.+  “Ṣùgbọ́n ọba náà kún fún ìrunú, ó sì rán ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn òṣìkàpànìyàn wọnnì run, ó sì fi iná sun ìlú ńlá wọn.+  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́ ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn tí a ti ké sí kò yẹ.+  Nítorí náà, ẹ lọ sí àwọn ojú ọ̀nà tí ó jáde láti inú ìlú ńlá yìí, ẹnikẹ́ni tí ẹ bá rí ni kí ẹ ké sí wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.’+ 10  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ẹrú wọnnì jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí jọpọ̀, àwọn ẹni burúkú àti àwọn ẹni rere;+ yàrá fún àwọn ayẹyẹ ìgbéyàwó náà sì kún fún àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú+ nídìí tábìlì. 11  “Nígbà tí ọba náà wọlé láti bẹ àwọn àlejò wò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ ẹ̀wù ìgbéyàwó.+ 12  Nítorí náà, ó wí fún un pé, ‘Àwé, báwo ni ìwọ ṣe wọlé dé ìhín láìwọ ẹ̀wù ìgbéyàwó?’+ Kò wá lè sọ̀rọ̀. 13  Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú síta nínú òkùnkùn lóde. Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.’+ 14  “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a ké sí, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”+ 15  Nígbà náà ni àwọn Farisí bá ọ̀nà wọn lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pa pọ̀ láti dẹ pańpẹ́ mú un nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 16  Nítorí náà, wọ́n rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn àjọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù,+ wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ jẹ́ olùsọ òtítọ́, o sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́, ìwọ kò sì bìkítà fún ẹnikẹ́ni, nítorí ìwọ kì í wo ìrísí òde àwọn ènìyàn.+ 17  Nítorí náà, sọ fún wa, Kí ni ìwọ rò? Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?”+ 18  Ṣùgbọ́n Jésù, ní mímọ ìwà burúkú wọn, wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń dán mi wò, ẹ̀yin alágàbàgebè?+ 19  Ẹ fi ẹyọ owó ti owó orí hàn mí.” Wọ́n mú owó dínárì kan wá fún un. 20  Ó sì wí fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?”+ 21  Wọ́n wí pé: “Ti Késárì.” Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 22  Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìyẹn, ẹnu yà wọ́n, ní fífi í sílẹ̀, wọ́n sì lọ.+ 23  Ní ọjọ́ yẹn, àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde, wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé:+ 24  “Olùkọ́, Mósè sọ pé, ‘Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá kú láìní àwọn ọmọ, kí arákùnrin rẹ̀ gbé aya rẹ̀ níyàwó, kí ó sì gbé ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀.’+ 25  Wàyí o, arákùnrin méje wà pẹ̀lú wa; èkíní gbéyàwó, ó sì di olóògbé, bí kò sì ti ní ọmọ, ó fi aya rẹ̀ sílẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀.+ 26  Ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà kan náà pẹ̀lú sí èkejì àti ẹ̀kẹta, títí kan gbogbo àwọn méjèèje.+ 27  Ní ìkẹyìn gbogbo wọn, obìnrin náà kú. 28  Nítorí náà, ní àjíǹde, èwo nínú àwọn méje náà ni yóò jẹ́ aya fún? Nítorí gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ ẹ.”+ 29  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ ṣàṣìṣe, nítorí ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tàbí agbára Ọlọ́run;+ 30  nítorí ní àjíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó,+ ṣùgbọ́n wọ́n yóò wà gẹ́gẹ́ bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run. 31  Ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ kò ka ohun tí Ọlọ́run sọ fún yín ni, pé,+ 32  ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè.”+ 33  Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìyẹn, háà ṣe àwọn ogunlọ́gọ̀ náà sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.+ 34  Lẹ́yìn tí àwọn Farisí gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, wọ́n kóra jọpọ̀ ní àwùjọ kan. 35  Ọ̀kan nínú wọn, tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin,+ sì béèrè, ní dídán an wò pé: 36  “Olùkọ́, èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin?”+ 37  Ó wí fún un pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ 38  Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.+ 39  Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’+ 40  Lórí àwọn àṣẹ méjì wọ̀nyí ni gbogbo Òfin so kọ́, àti àwọn Wòlíì.”+ 41  Wàyí o, bí àwọn Farisí ti kóra jọpọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé:+ 42  “Kí ni ẹ̀yin rò nípa Kristi? Ọmọkùnrin ta ni ó jẹ́?” Wọ́n wí fún un pé: “Ti Dáfídì.”+ 43  Ó wí fún wọn pé: “Báwo wá ni ó ṣe jẹ́ tí Dáfídì nípasẹ̀ ìmísí+ fi pè é ní ‘Olúwa,’ ní wíwí pé, 44  ‘Jèhófà wí fún Olúwa mi pé: “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’?+ 45  Nítorí náà, bí Dáfídì bá pè é ní ‘Olúwa,’ báwo ni òun ṣe jẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀?”+ 46  Kò sì sí ẹni tí ó lè sọ ọ̀rọ̀ kan ní ìfèsìpadà fún un, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò gbójúgbóyà láti ọjọ́ yẹn lọ láti tún bi í ní ìbéèrè mọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé