Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 20:1-34

20  “Nítorí ìjọba ọ̀run dà bí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ó jáde lọ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù láti háyà àwọn òṣìṣẹ́ fún ọgbà àjàrà rẹ̀.+  Nígbà tí ó ti bá àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣe àdéhùn owó dínárì kan fún ọjọ́ kan,+ ó rán wọn jáde lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.  Bí ó ti ń jáde lọ ní nǹkan bí wákàtí kẹta pẹ̀lú,+ ó rí àwọn mìíràn tí wọ́n dúró láìríṣẹ́ ṣe ní ibi ọjà;+  ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà, ohun yòówù tí ó bá tọ́ ni èmi yóò sì fún yín.’  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jáde lọ. Ó tún jáde lọ ní nǹkan bí wákàtí kẹfà+ àti ní wákàtí kẹsàn-án,+ ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.  Níkẹyìn, ní nǹkan bí wákàtí kọkànlá, ó jáde lọ, ó sì rí àwọn mìíràn tí wọ́n dúró, ó sì wí fún wọn pé, ‘Èé ṣe tí ẹ fi dúró síhìn-ín ní gbogbo òní láìríṣẹ́ṣe?’  Wọ́n wí fún un pé, ‘Nítorí pé ẹnikẹ́ni kò háyà wa ni.’ Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ lọ sínú ọgbà àjàrà.’+  “Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́,+ ọ̀gá ọgbà àjàrà náà wí fún ọkùnrin tí ó fi ṣe alámòójútó pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́, kí o sì san owó ọ̀yà wọn fún wọn,+ ní bíbẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn ẹni ìkẹyìn títí dé àwọn ẹni àkọ́kọ́.’  Nígbà tí àwọn ọkùnrin ti wákàtí kọkànlá dé, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. 10  Nítorí náà, nígbà tí àwọn ẹni àkọ́kọ́ dé, wọ́n parí èrò pé àwọn yóò gbà jù bẹ́ẹ̀ lọ; ṣùgbọ́n àwọn pẹ̀lú gba owó iṣẹ́ ní iye ìdíwọ̀n owó dínárì kan. 11  Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí baálé ilé náà,+ 12  wọ́n sì wí pé, ‘Àwọn ẹni ìkẹyìn wọ̀nyí ṣe iṣẹ́ wákàtí kan; síbẹ̀ ìwọ mú wọn bá wa dọ́gba, àwa tí a fàyà rán iṣẹ́ ìnira òní àti ooru tí ń jóni!’ 13  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà fún ọ̀kan lára wọn, ó wí pé, ‘Àwé, èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí ọ. Àdéhùn owó dínárì kan ni ìwọ bá mi ṣe, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+ 14  Gba ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn yìí ní ohun kan náà tí mo fún ọ.+ 15  Kò ha bófin mu fún mi láti fi àwọn nǹkan tí ó jẹ́ tèmi ṣe ohun tí mo fẹ́? Tàbí ojú rẹ ha burú+ nítorí mo jẹ́ ẹni rere?’+ 16  Ní ọ̀nà yìí, àwọn ẹni ìkẹyìn yóò jẹ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́, àwọn ẹni àkọ́kọ́ yóò sì jẹ́ àwọn ẹni ìkẹyìn.”+ 17  Wàyí o, bí ó ti fẹ́ gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjìlá+ lọ sápá kan ní ìdákọ́ńkọ́, ó sì wí fún wọn ní ojú ọ̀nà pé: 18  “Wò ó! A ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú,+ 19  wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ láti fi í ṣe yẹ̀yẹ́ àti láti nà án lọ́rẹ́+ àti láti kàn án mọ́gi, a ó sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 20  Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọkùnrin Sébédè+ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, ó wárí fún un, ó sì béèrè fún ohun kan lọ́wọ́ rẹ̀.+ 21  Ó wí fún un pé: “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Ó wí fún un pé: “Sọ ọ̀rọ̀ náà kí àwọn ọmọkùnrin mi méjì wọ̀nyí lè jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ìjọba rẹ.”+ 22  Jésù wí ní ìdáhùn pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ ń béèrè fún. Ẹ ha lè mu ife+ tí èmi máa tó mu?” Wọ́n wí fún un pé: “Àwa lè mu ún.” 23  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ ó mu ife+ mi ní tòótọ́, ṣùgbọ́n jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọwọ́ Baba mi.”+ 24  Nígbà tí àwọn mẹ́wàá yòókù gbọ́ nípa èyí, ìkannú wọ́n ru sí àwọn arákùnrin méjì náà.+ 25  Ṣùgbọ́n Jésù, ní pípè wọ́n wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, wí pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn olùṣàkóso orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn ènìyàn ńlá a sì máa lo ọlá àṣẹ lórí wọn.+ 26  Báyìí kọ́ ni láàárín yín;+ ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín,+ 27  ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.+ 28  Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́,+ kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”+ 29  Wàyí o, bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní Jẹ́ríkò,+ ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e. 30  Sì wò ó! àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tí wọ́n jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jésù ń kọjá lọ, wọ́n ké jáde, pé: “Olúwa, ṣàánú fún wa, Ọmọkùnrin Dáfídì!”+ 31  Ṣùgbọ́n ogunlọ́gọ̀ náà sọ fún wọn kíkankíkan pé kí wọ́n dákẹ́; síbẹ̀ wọ́n túbọ̀ ké rara jù bẹ́ẹ̀ lọ, pé: “Olúwa, ṣàánú fún wa, Ọmọkùnrin Dáfídì!”+ 32  Nítorí náà, Jésù dúró, ó pè wọ́n, ó sì wí pé: “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fún yín?” 33  Wọ́n wí fún un pé: “Olúwa, jẹ́ kí ojú wá là.”+ 34  Bí àánú ti ṣe é, Jésù fọwọ́ kan ojú wọn,+ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ wọ́n sì ríran, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé