Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 2:1-23

2  Lẹ́yìn tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù+ Ọba, wò ó! àwọn awòràwọ̀+ láti àwọn apá ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù,  wọ́n wí pé: “Ibo ni ẹni tí a bí ní ọba+ àwọn Júù wà? Nítorí a rí ìràwọ̀+ rẹ̀ nígbà tí a wà ní ìlà-oòrùn, a sì ti wá láti wárí fún un.”  Ní gbígbọ́ èyí, ṣìbáṣìbo bá Ọba Hẹ́rọ́dù, àti gbogbo Jerúsálẹ́mù pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀;  nígbà tí ó sì kó gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lọ́wọ́ wọn ibi tí a ó ti bí Kristi.  Wọ́n wí fún un pé: “Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti Jùdíà; nítorí báyìí ni a ti kọ̀wé rẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì náà,  ‘Àti ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ ti ilẹ̀ Júdà, lọ́nàkọnà, ìwọ kì í ṣe ìlú ńlá tí ìjámọ́pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ lára àwọn gómìnà Júdà; nítorí láti inú rẹ ni alákòóso yóò ti jáde wá,+ ẹni tí yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn+ àwọn ènìyàn mi, Ísírẹ́lì.’”  Nígbà náà ni Hẹ́rọ́dù fi ọlá àṣẹ pe àwọn awòràwọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́, ó sì fẹ̀sọ̀ wádìí dájú lọ́wọ́ wọn àkókò tí ìràwọ̀ náà fara hàn;  nígbà tí ó sì ń rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó wí pé: “Ẹ lọ fẹ̀sọ̀ wá ọmọ kékeré náà káàkiri, nígbà tí ẹ bá sì ti rí i, kí ẹ padà ròyìn fún mi, kí èmi náà lè lọ, kí n sì wárí fún un.”+  Nígbà tí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ; sì wò ó! ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí nígbà tí wọ́n wà ní ìlà-oòrùn+ ń lọ níwájú wọn, títí ó wá fi dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré náà wà. 10  Nígbà tí wọ́n rí ìràwọ̀ náà, wọ́n yọ̀ gidigidi ní tòótọ́. 11  Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, ní wíwólẹ̀, wọ́n wárí fún un. Wọ́n ṣí àwọn ìṣúra wọn pẹ̀lú, wọ́n sì fún un ní àwọn ẹ̀bùn, wúrà àti oje igi tùràrí àti òjíá. 12  Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí a fún wọn ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá+ nínú àlá láti má padà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀ gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ilẹ̀ wọn. 13  Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà+ fara han Jósẹ́fù nínú àlá, ó wí pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì, kí o sì dúró níbẹ̀ títí èmi yóò fi bá ọ sọ̀rọ̀; nítorí Hẹ́rọ́dù ti fẹ́ máa wá ọmọ kékeré náà káàkiri láti pa á run.” 14  Bẹ́ẹ̀ ni ó dìde, ó sì mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ ní òru, ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Íjíbítì, 15  ó sì dúró níbẹ̀ títí di ìgbà tí Hẹ́rọ́dù di olóògbé, kí a lè mú èyíinì tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ ṣẹ,+ pé: “Láti Íjíbítì+ ni mo ti pe ọmọkùnrin mi.” 16  Nígbà náà Hẹ́rọ́dù, ní rírí i pé àwọn awòràwọ̀ náà ti gbọ́n já òun, kún fún ìhónú ńláǹlà, ó sì ránṣẹ́ jáde, ó sì mú kí a pa gbogbo ọmọdékùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo àgbègbè rẹ̀, láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú àkókò tí ó ti fẹ̀sọ̀ wádìí dájú lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ náà.+ 17  Nígbà náà ni a mú èyíinì ṣẹ tí a sọ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì, pé: 18  “A gbọ́ ohùn kan ní Rámà,+ ẹkún àti ohùn réré ẹkún púpọ̀; Rákélì+ ni ó ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀, kò sì fẹ́ láti gba ìtùnú, nítorí pé wọn kò sí mọ́.” 19  Nígbà tí Hẹ́rọ́dù ti di olóògbé, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù nínú àlá+ ní Íjíbítì, 20  ó sì wí pé: “Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n lọ sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì, nítorí àwọn tí wọ́n ń wá ọkàn ọmọ kékeré náà ti kú.” 21  Bẹ́ẹ̀ ni ó dìde, ó sì mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, ó sì wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì. 22  Ṣùgbọ́n ní gbígbọ́ pé Ákíláọ́sì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba Jùdíà ní ipò baba rẹ̀ Hẹ́rọ́dù, àyà fò ó láti lọ sí ibẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí a fún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nínú àlá,+ ó fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ Gálílì,+ 23  ó sì wá, ó sì ń gbé ní ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Násárétì,+ kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì ṣẹ pé: “A ó pè é ní ará Násárétì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé