Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 19:1-30

19  Wàyí o, nígbà tí Jésù parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó kúrò ní Gálílì, ó sì wá sí ààlà ilẹ̀ Jùdíà ní òdì-kejì Jọ́dánì.+  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e, ó sì wò wọ́n sàn níbẹ̀.+  Àwọn Farisí sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n dójú lé dídẹ ẹ́ wò, wọ́n sì wí pé: “Ó ha bófin mu fún ọkùnrin láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ lórí onírúurú ìdí gbogbo?”+  Ní ìfèsìpadà, ó wí pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo,+  ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀,+ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’?+  Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”+  Wọ́n wí fún un pé: “Èé ṣe tí Mósè fi wá lànà sílẹ̀ fún fífún un ní ìwé ẹ̀rí ìlélọ, kí a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?”+  Ó wí fún wọn pé: “Ní tìtorí líle-ọkàn yín,+ Mósè yọ̀ǹda fún yín bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ láti kọ aya yín sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.+  Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”+ 10  Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn ọkùnrin rí pẹ̀lú aya rẹ̀, kò bọ́gbọ́n mu láti gbéyàwó.”+ 11  Ó wí fún wọn pé: “Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ń wá àyè fún àsọjáde náà, bí kò ṣe kìkì àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn náà.+ 12  Nítorí àwọn ìwẹ̀fà wà tí a bí bẹ́ẹ̀ láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá wọn,+ àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí àwọn ènìyàn sọ di ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà ní tìtorí ìjọba ọ̀run. Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”+ 13  Nígbà náà ni a mú àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, kí ó sì gba àdúrà; ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn bá wọn wí kíkankíkan.+ 14  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ àwọn ọmọ kéékèèké jẹ́ẹ́, ẹ sì dẹ́kun dídí wọn lọ́wọ́ wíwá sọ́dọ̀ mi, nítorí ìjọba ọ̀run jẹ́ ti irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.”+ 15  Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, ó sì lọ láti ibẹ̀.+ 16  Wàyí o, wò ó! ẹnì kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 17  Ó wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi ń béèrè lọ́wọ́ mi nípa ohun tí ó jẹ́ rere? Ẹni rere kan ni ó wà.+ Àmọ́ ṣá o, bí ìwọ bá fẹ́ wọ inú ìyè, máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.”+ 18  Ó wí fún un pé: “Àwọn wo?”+ Jésù wí pé: “Họ́wù, Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè,+ Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ 19  Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ,+ àti pé, Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”+ 20  Ọ̀dọ́kùnrin náà wí fún un pé: “Mo ti pa gbogbo ìwọ̀nyí mọ́; kí ni mo ṣaláìní síbẹ̀?” 21  Jésù wí fún un pé: “Bí ìwọ bá fẹ́ jẹ́ pípé, lọ ta àwọn nǹkan ìní rẹ, kí o sì fi fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run,+ sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 22  Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà gbọ́ àsọjáde yìí, ó lọ kúrò pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn, nítorí ó ní ohun ìní púpọ̀.+ 23  Ṣùgbọ́n Jésù wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé yóò jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba ọ̀run.+ 24  Mo tún wí fún yín pé, Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run.”+ 25  Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn gbọ́ ìyẹn, wọ́n fi ìyàlẹ́nu ńláǹlà hàn, wọ́n wí pé: “Ta ni a lè gbà là ní ti tòótọ́?”+ 26  Ní wíwò wọ́n lójú, Jésù wí fún wọn pé: “Lọ́dọ̀ ènìyàn, èyí kò ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”+ 27  Nígbà náà ni Pétérù sọ fún un ní ìfèsìpadà pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?”+ 28  Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.+ 29  Àti pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.+ 30  “Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ẹni ìkẹyìn yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé