Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 16:1-28

16  Níhìn-ín, àwọn Farisí+ àti àwọn Sadusí tọ̀ ọ́ wá, láti dẹ ẹ́ wò, wọ́n sì ní kí ó fi àmì kan hàn wọ́n láti ọ̀run.+  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “[[Nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́, ó ti di àṣà yín láti máa sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ yóò dára, nítorí sánmà pupa bí iná’; 3  àti ní òwúrọ̀, ‘Ojú ọjọ́ olótùútù, tí ó kún fún òjò yóò wà lónìí, nítorí sánmà pupa bí iná, ṣùgbọ́n ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ̀ bí a ṣe ń túmọ̀ ìrísí sánmà, ṣùgbọ́n àwọn àmì àkókò ni ẹ kò lè túmọ̀.]]+  Ìran burúkú àti panṣágà ń bá a nìṣó ní wíwá àmì kan, ṣùgbọ́n a kì yóò fi àmì kankan fún un+ àyàfi àmì Jónà.”+ Pẹ̀lú ìyẹn, ó lọ kúrò, ó fi wọ́n sílẹ̀ sẹ́yìn.+  Wàyí o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọdá sí ìhà kejì, wọ́n sì gbàgbé láti kó ìṣù búrẹ́dì dání.+  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fèrò wérò láàárín ara wọn, ní wíwí pé: “Àwa kò mú ìṣù búrẹ́dì kankan lọ́wọ́.”  Ní mímọ èyí, Jésù wí pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣe ìfèròwérò yìí láàárín ara yín, nítorí pé ẹ kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan, ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ kíkéré?+  Ṣé ẹ kò tíì rí kókó náà síbẹ̀, tàbí ẹ kò ha rántí ìṣù búrẹ́dì márùn-ún nínú ọ̀ràn ti ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti iye àwọn apẹ̀rẹ̀ tí ẹ kó jọ?+ 10  Tàbí ìṣù búrẹ́dì méje nínú ọ̀ràn ti ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti iye apẹ̀rẹ̀ ìpèsè tí ẹ kó jọ?+ 11  Èé ti rí tí ẹ kò fi òye mọ̀ pé èmi kò bá yín sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣù búrẹ́dì? Ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 12  Nígbà náà ni wọ́n mòye pé ó sọ pé kí wọ́n ṣọ́ra, kì í ṣe fún ìwúkàrà àwọn ìṣù búrẹ́dì, bí kò ṣe fún ẹ̀kọ́+ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí. 13  Wàyí o, nígbà tí ó ti wá sí àwọn apá Kesaréà ti Fílípì, Jésù wá ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé Ọmọ ènìyàn jẹ́?”+ 14  Wọ́n sọ pé: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Oníbatisí,+ àwọn mìíràn Èlíjà,+ síbẹ̀ àwọn mìíràn Jeremáyà tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.” 15  Ó sọ fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?”+ 16  Ní ìdáhùn, Símónì Pétérù sọ pé: “Ìwọ ni Kristi náà,+ Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”+ 17  Ní ìdáhùnpadà, Jésù sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ìwọ, Símónì ọmọkùnrin Jónà, nítorí pé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ni ó ṣí i payá fún ọ, ṣùgbọ́n Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni ó ṣe bẹ́ẹ̀.+ 18  Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo sọ fún ọ, Ìwọ ni Pétérù,+ orí àpáta ràbàtà+ yìí sì ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi sí dájúdájú, àwọn ibodè Hédíìsì+ kì yóò sì borí rẹ̀.+ 19  Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba ọ̀run, ohun yòówù tí ìwọ bá sì dè lórí ilẹ̀ ayé ni yóò jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run, ohun yòówù tí ìwọ bá sì tú lórí ilẹ̀ ayé ni yóò jẹ́ ohun tí a ti tú ní ọ̀run.”+ 20  Nígbà náà ni ó pàṣẹ kíkankíkan fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Kristi náà.+ 21  Láti ìgbà yẹn lọ, Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ sí fi han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun sì jìyà ohun púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì gbé òun dìde ní ọjọ́ kẹta.+ 22  Látàrí èyí, Pétérù mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.”+ 23  Ṣùgbọ́n, ní yíyí ẹ̀yìn rẹ̀ padà, ó wí fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì!+ Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò,+ bí kò ṣe ti ènìyàn.” 24  Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.+ 25  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí mi yóò rí i.+ 26  Nítorí àǹfààní wo ni yóò jẹ́ fún ènìyàn kan bí ó bá jèrè gbogbo ayé ṣùgbọ́n tí ó pàdánù ọkàn rẹ̀?+ tàbí kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀+ fún ọkàn rẹ̀? 27  Nítorí a ti yan Ọmọ ènìyàn tẹ́lẹ̀ láti wá nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san èrè iṣẹ́ fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí rẹ̀.+ 28  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé