Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 15:1-39

15  Nígbà náà ni àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wá sọ́dọ̀ Jésù láti Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n wí pé:  “Èé ṣe tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ fi ń tẹ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn ènìyàn ìgbà àtijọ́ lójú? Fún àpẹẹrẹ, wọn kì í wẹ ọwọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹ oúnjẹ.”+  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ̀yin pẹ̀lú fi ń tẹ àṣẹ Ọlọ́run lójú nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín?+  Fún àpẹẹrẹ, Ọlọ́run wí pé, ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’;+ àti pé, ‘Ẹni tí ó bá kẹ́gàn baba tàbí ìyá, kíkú ni kí ó kú.’+  Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Ẹnì yòówù tí ó sọ fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé: “Ohun yòówù tí mo ní nípa èyí tí o fi lè jẹ àǹfààní lára mi jẹ́ ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run,” 6  kò gbọ́dọ̀ bọlá fún baba rẹ̀ rárá.’+ Àti nípa bẹ́ẹ̀ ẹ ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ nítorí òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yín.+  Ẹ̀yin alágàbàgebè,+ Aísáyà+ sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa yín, nígbà tí ó wí pé,  ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè [wọn] bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọ́n jìnnà réré sí mi.+  Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.’”+ 10  Pẹ̀lú ìyẹn, ó pe ogunlọ́gọ̀ náà sún mọ́ tòsí, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, kí òye rẹ̀ sì yé yín:+ 11  Kì í ṣe ohun tí ó wọ ẹnu ni ó ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; ṣùgbọ́n ohun tí ó jáde wá láti ẹnu ni ó ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”+ 12  Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá, wọ́n sì wí fún un pé: “Ìwọ ha mọ̀ pé àwọn Farisí kọsẹ̀ ní gbígbọ́ ohun tí o sọ?”+ 13  Ní ìfèsìpadà, ó wí pé: “Gbogbo ọ̀gbìn tí Baba mi ọ̀run kò gbìn ni a óò hú tegbòtegbò.+ 14  Ẹ jọ̀wọ́ wọn. Afọ́jú afinimọ̀nà ni wọ́n. Bí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò.”+ 15  Ní ìdáhùnpadà, Pétérù wí fún un pé: “Mú àpèjúwe náà ṣe kedere sí wa.”+ 16  Látàrí èyí, ó wí pé: “Ẹ̀yin pẹ̀lú ha ṣì wà láìní òye síbẹ̀?+ 17  Ṣé ẹ kò mọ̀ pé ohun gbogbo tí ń wọ ẹnu a máa kọjá lọ sínú ìfun, a ó sì yà á dànù sínú ihò ẹ̀gbin? 18  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ohun tí ń jáde láti ẹnu ń jáde láti inú ọkàn-àyà, ohun wọnnì sì ni ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.+ 19  Fún àpẹẹrẹ, láti inú ọkàn-àyà ni àwọn èrò burúkú+ ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì.+ 20  Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin; ṣùgbọ́n láti fi ọwọ́ tí a kò wẹ̀ jẹun kì í sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”+ 21  Ní kíkúrò níbẹ̀, Jésù wá fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí àwọn apá Tírè àti Sídónì.+ 22  Sì wò ó! obìnrin ará Foníṣíà+ kan láti àwọn ẹkùn ilẹ̀ wọnnì jáde wá, ó sì ké sókè, pé: “Ṣàánú fún mi,+ Olúwa, Ọmọkùnrin Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù gbé ọmọbìnrin mi dè burúkú-burúkú.” 23  Ṣùgbọ́n kò sọ ọ̀rọ̀ kan ní ìdáhùn fún un. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún un pé: “Rán an lọ; nítorí pé ó ń ké jáde tẹ̀ lé wa lẹ́yìn ṣáá.” 24  Ní ìdáhùn, ó wí pé: “A kò rán mi jáde sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù.”+ 25  Nígbà tí obìnrin náà wá, ó bẹ̀rẹ̀ sí wárí fún un, ó ń sọ pé: “Olúwa, ràn mí lọ́wọ́!”+ 26  Ní ìdáhùn, ó wí pé: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.” 27  Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.”+ 28  Jésù wá sọ ní ìfèsìpadà fún un pé: “Ìwọ obìnrin yìí, títóbi ni ìgbàgbọ́ rẹ; kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.” A sì mú ọmọbìnrin rẹ̀ lára dá láti wákàtí yẹn lọ.+ 29  Ní líla ìgbèríko kọjá láti ibẹ̀, lẹ́yìn náà Jésù dé itòsí òkun Gálílì,+ àti pé, lẹ́yìn gígun òkè ńlá lọ,+ ó jókòó síbẹ̀. 30  Nígbà náà ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tọ̀ ọ́ wá, tí wọ́n mú àwọn ènìyàn tí wọ́n yarọ, aláàbọ̀ ara, afọ́jú, odi, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn wá pẹ̀lú wọn, wọ́n sì rọra gbé wọn kalẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn;+ 31  tó bẹ́ẹ̀ tí ogunlọ́gọ̀ náà fi ṣe kàyéfì bí wọ́n ti rí tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn arọ sì ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran, wọ́n sì yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.+ 32  Ṣùgbọ́n Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì wí pé:+ “Àánú ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí,+ nítorí pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí wọ́n ti wà pẹ̀lú mi, wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ; èmi kò sì fẹ́ rán wọn lọ ní gbígbààwẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí okun wọ́n tán ní ojú ọ̀nà.” 33  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: “Níbo ni àwa, ní ibi tí ó dá yìí, yóò tí rí àwọn ìṣù búrẹ́dì tí ó pọ̀ tó láti yó ogunlọ́gọ̀ tí ó pọ̀ tó báyìí?”+ 34  Látàrí èyí, Jésù wí fún wọn pé: “Ìṣù búrẹ́dì mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n wí pé: “Méje, àti ìwọ̀nba àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.” 35  Nítorí náà, lẹ́yìn fífún ogunlọ́gọ̀ náà ní ìtọ́ni láti rọ̀gbọ̀kú sórí ilẹ̀, 36  ó mú ìṣù búrẹ́dì méje àti àwọn ẹja náà àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́, ó bù wọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pín in fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀wẹ̀ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.+ 37  Gbogbo wọ́n sì jẹ, wọ́n sì yó, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ́kùsílẹ̀ àwọn èébù, wọ́n kó ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ìpèsè méje jọ.+ 38  Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn tí wọ́n jẹun jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké. 39  Níkẹyìn, lẹ́yìn rírán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, ó wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì wá sí àwọn ẹkùn ilẹ̀ Mágádánì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé