Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Mátíù 13:1-58

13  Ní ọjọ́ yẹn, lẹ́yìn tí Jésù ti fi ilé sílẹ̀, ó jókòó lẹ́bàá òkun; 2  àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ ọkọ̀ ojú omi kan, ó sì jókòó,+ gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà sì dúró ní etíkun.  Nígbà náà ni ó fi àwọn àpèjúwe sọ ohun púpọ̀ fún wọn, ó wí pé: “Wò ó! Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fúnrúgbìn;+  bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà wọ́n jẹ.+  Àwọn mìíràn bọ́ sórí àwọn ibi àpáta níbi tí wọn kò ti ní erùpẹ̀ púpọ̀, ní kíá wọ́n sì rú yọ nítorí ṣíṣàìní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀.+  Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn là, ó jó wọn gbẹ, àti nítorí ṣíṣàìní gbòǹgbò, wọ́n rọ.+  Àwọn mìíràn, pẹ̀lú, bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà sì yọ, wọ́n sì fún wọn pa.+  Síbẹ̀ àwọn mìíràn bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí so èso, eléyìí ìlọ́po ọgọ́rùn-ún, èyíinì ọgọ́ta, òmíràn ọgbọ̀n.+  Kí ẹni tí ó bá ní etí fetí sílẹ̀.”+ 10  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá, wọ́n sì wí fún un pé: “Èé ṣe tí o fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe?”+ 11  Ní ìfèsìpadà, ó wí pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀+ ti ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún.+ 12  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá ní, a óò fún un ní púpọ̀ sí i, a ó sì mú kí ó ní púpọ̀ gidigidi;+ ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí kò bá ní, àní ohun tí ó ní pàápàá ni a ó gbà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 13  Ìdí nìyí tí mo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe, nítorí pé, ní wíwò, wọ́n ń wò lásán, àti ní gbígbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni òye rẹ̀ kò yé wọn;+ 14  àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sì ń ní ìmúṣẹ sí wọn, èyí tí ó wí pé, ‘Ní gbígbọ́, ẹ óò gbọ́ ṣùgbọ́n òye rẹ̀ kì yóò yé yín lọ́nàkọnà; àti pé, ní wíwò, ẹ ó wò ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí lọ́nàkọnà.+ 15  Nítorí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí láé, kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́, kí òye rẹ̀ sì yé wọn nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má sì yí padà, kí n má sì mú wọn lára dá.’+ 16  “Bí ó ti wù kí ó rí, aláyọ̀ ni ojú+ yín nítorí pé wọ́n rí, àti etí yín nítorí pé wọ́n gbọ́. 17  Nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì+ àti àwọn olódodo ní ìfẹ́-ọkàn láti rí àwọn ohun tí ẹ ń rí, wọn kò sì rí wọn,+ àti láti gbọ́ àwọn ohun tí ẹ ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.+ 18  “Nígbà náà, ẹ fetí sí àpèjúwe ọkùnrin tí ó fúnrúgbìn.+ 19  Níbi tí ẹnì kan bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìjọba náà ṣùgbọ́n tí òye rẹ̀ kò yé e, ẹni burúkú náà+ a wá, a sì já ohun tí a ti gbìn sínú ọkàn-àyà rẹ̀ gbà lọ; èyí ni ọ̀kan tí a fún sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà. 20  Ní ti èyí tí a fún sórí àwọn ibi àpáta, èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí ó sì tẹ́wọ́ gbà á ní kíá pẹ̀lú ìdùnnú.+ 21  Síbẹ̀, kò ní gbòǹgbò nínú ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ fún àkókò kan, lẹ́yìn tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni sì ti dìde ní tìtorí ọ̀rọ̀ náà, a mú un kọsẹ̀ ní kíá.+ 22  Ní ti èyí tí a fún sáàárín àwọn ẹ̀gún, èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí+ àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.+ 23  Ní ti èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà, èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí òye rẹ̀ sì ń yé e, ẹni tí ń so èso ní ti gidi, tí ó sì ń mú èso jáde, eléyìí ìlọ́po ọgọ́rùn-ún, èyíinì ọgọ́ta, òmíràn ọgbọ̀n.”+ 24  Àpèjúwe mìíràn ni ó gbé kalẹ̀ níwájú wọn, pé: “Ìjọba ọ̀run wá dà bí ọkùnrin kan tí ó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀.+ 25  Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì tún fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà, ó sì lọ. 26  Nígbà tí ewé ọ̀gbìn náà rú jáde, tí ó sì mú èso jáde, nígbà náà ni àwọn èpò fara hàn pẹ̀lú. 27  Nítorí náà, àwọn ẹrú baálé ilé náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, ‘Ọ̀gá, kì í ha ṣe irúgbìn àtàtà ni ìwọ fún sínú pápá rẹ?+ Nígbà náà, báwo ni ó ṣe wá ní àwọn èpò?’+ 28  Ó wí fún wọn pé, ‘Ọ̀tá kan, ọkùnrin kan, ni ó ṣe èyí.’+ Wọ́n wí fún un pé, ‘Ìwọ ha fẹ́ kí àwa, nígbà náà, jáde lọ kí a sì kó wọn jọ?’ 29  Ó wí pé, ‘Ó tì o; kí ó má bàa jẹ́ pé nípa èèṣì, nígbà tí ẹ bá ń kó àwọn èpò jọ, ẹ óò hú àlìkámà pẹ̀lú wọn. 30  Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè; ní àsìkò ìkórè, ṣe ni èmi yóò sì sọ fún àwọn akárúgbìn pé, Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀ láti sun wọ́n,+ lẹ́yìn náà ẹ lọ kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi.’”+ 31  Àpèjúwe mìíràn ni ó gbé kalẹ̀ níwájú wọn,+ pé: “Ìjọba ọ̀run rí bí hóró músítádì kan,+ tí ọkùnrin kan mú tí ó sì gbìn sínú pápá rẹ̀; 32  ní ti tòótọ́, èyí tí ó jẹ́ tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn, ṣùgbọ́n nígbà tí ó ti dàgbà, òun ni ó tóbi jù lọ nínú àwọn ọ̀gbìn oko, ó sì di igi kan, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run+ fi wá, tí wọ́n sì rí ibùwọ̀ láàárín àwọn ẹ̀ka rẹ̀.”+ 33  Àpèjúwe mìíràn ni ó sọ fún wọn pé: “Ìjọba ọ̀run dà bí ìwúkàrà,+ èyí tí obìnrin kan mú, tí ó sì fi pa mọ́ sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ńlá mẹ́ta, títí gbogbo ìṣùpọ̀ náà fi di wíwú.” 34  Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni Jésù fi àwọn àpèjúwe sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà. Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe;+ 35  kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà bàa lè ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: “Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi pẹ̀lú àwọn àpèjúwe, èmi yóò kéde àwọn ohun tí a fi pa mọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní gbangba.”+ 36  Nígbà náà, lẹ́yìn tí ó ti rán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, ó wọnú ilé lọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sí wá bá a, wọ́n sì wí pé: “Ṣàlàyé àpèjúwe àwọn èpò inú pápá fún wa.” 37  Ní ìdáhùnpadà, ó wí pé: “Afúnrúgbìn tí ó fún irúgbìn àtàtà náà ni Ọmọ ènìyàn; 38  pápá náà ni ayé;+ ní ti irúgbìn àtàtà, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ìjọba náà; ṣùgbọ́n àwọn èpò ni àwọn ọmọ ẹni burúkú+ náà, 39  ọ̀tá tí ó sì fún wọn ni Èṣù.+ Ìkórè+ ni ìparí ètò àwọn nǹkan,+ àwọn áńgẹ́lì sì ni akárúgbìn. 40  Nítorí náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kó àwọn èpò jọ, tí a sì fi iná sun wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan.+ 41  Ọmọ ènìyàn yóò rán àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tí ń fa ìkọ̀sẹ̀ jáde kúrò nínú ìjọba rẹ̀+ àti àwọn ènìyàn tí ń hu ìwà àìlófin, 42  wọn yóò sì gbé wọn sọ sínú ìléru oníná.+ Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.+ 43  Ní àkókò yẹn, àwọn olódodo yóò máa tàn+ yòò bí oòrùn+ nínú ìjọba Baba wọn. Kí ẹni tí ó bá ní etí fetí sílẹ̀.+ 44  “Ìjọba ọ̀run dà bí ìṣúra tí a fi pa mọ́ sínú pápá, èyí tí ọkùnrin kan rí, tí ó sì fi pa mọ́; àti nítorí ìdùnnú tí ó ní, ó lọ, ó sì ta+ àwọn ohun tí ó ní, ó sì ra pápá yẹn.+ 45  “Ìjọba ọ̀run tún dà bí olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà. 46  Nígbà tí ó rí péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga,+ ó jáde lọ, ó sì ta gbogbo ohun tí ó ní ní kánmọ́kánmọ́, ó sì rà á.+ 47  “Ìjọba ọ̀run tún dà bí àwọ̀n ńlá kan, tí a jù sínú òkun, tí ó sì kó ẹja onírúurú jọ.+ 48  Nígbà tí ó kún, wọ́n fà á gòkè sí etíkun àti pé, ní jíjókòó, wọ́n kó àwọn èyí àtàtà+ sínú àwọn ohun èlò, ṣùgbọ́n àwọn tí kò yẹ+ ni wọ́n dànù. 49  Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan: àwọn áńgẹ́lì yóò jáde lọ, wọn yóò sì ya àwọn ẹni burúkú+ sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn olódodo,+ 50  wọn yóò sì jù wọ́n sínú ìléru oníná. Níbẹ̀ ni ẹkún wọn àti ìpayínkeke wọn yóò wà.+ 51  “Òye gbogbo nǹkan wọ̀nyí ha yé yín bí?” Wọ́n wí fún un pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 52  Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí, olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba, nígbà tí a bá ti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọba ọ̀run,+ dà bí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ń mú àwọn ohun tuntun àti ògbólógbòó jáde láti inú ibi ìtọ́jú ìṣúra pa mọ́ rẹ̀.”+ 53  Wàyí o, nígbà tí Jésù ti parí àwọn àpèjúwe wọ̀nyí, ó la ìgbèríko kọjá láti ibẹ̀. 54  Lẹ́yìn tí ó sì ti dé sí ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀,+ ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn nínú sínágọ́gù wọn,+ tó bẹ́ẹ̀ tí háà fi ṣe wọ́n, wọ́n sì wí pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára wọ̀nyí? 55  Èyí ha kọ́ ni ọmọkùnrin káfíńtà náà?+ Kì í ha ṣe ìyá rẹ̀ ni a ń pè ní Màríà, àti àwọn arákùnrin rẹ̀ Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Símónì àti Júdásì? 56  Àti àwọn arábìnrin rẹ̀, gbogbo wọn kò ha wà pẹ̀lú wa?+ Níbo wá ni ọkùnrin yìí ti rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí?”+ 57  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọsẹ̀ lára rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé: “A kì í ṣàìbọlá fún wòlíì kan àyàfi ní ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”+ 58  Kò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára níbẹ̀ ní tìtorí àìnígbàgbọ́ wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé