Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mátíù 12:1-50

12  Ní àsìkò yẹn, Jésù la àwọn pápá ọkà kọjá ní sábáàtì.+ Ebi ń pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ya àwọn erín ọkà jẹ.+  Ní rírí èyí, àwọn Farisí sọ fún un pé:+ “Wò ó! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bófin mu láti ṣe ní sábáàtì.”+  Ó wí fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì ka ohun tí Dáfídì ṣe nígbà tí ebi ń pa òun àti àwọn ọkùnrin tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀?+  Bí ó ṣe wọ ilé Ọlọ́run, tí wọ́n sì jẹ àwọn ìṣù búrẹ́dì àgbékawájú,+ ohun tí kò bófin mu fún un láti jẹ,+ tàbí fún àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan?+  Tàbí, ẹ kò ha ti kà nínú Òfin+ pé ní àwọn sábáàtì àwọn àlùfáà inú tẹ́ńpìlì ṣe sábáàtì bí èyí tí kì í ṣe ọlọ́wọ̀, wọ́n sì ń bá a lọ láìjẹ̀bi?+  Ṣùgbọ́n mo sọ fún yín pé ohun kan tí ó tóbi ju tẹ́ńpìlì+ lọ wà níhìn-ín.  Bí ó ti wù kí ó rí, bí ẹ bá ti lóye ohun tí èyí túmọ̀ sí pé, ‘Àánú+ ni èmi ń fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ,’+ ẹ kì bá ti dá àwọn aláìjẹ̀bi lẹ́bi.  Nítorí Olúwa sábáàtì+ ni Ọmọ ènìyàn jẹ́.”+  Lẹ́yìn jíjáde kúrò ní ibẹ̀, ó lọ sínú sínágọ́gù wọn; 10  sì wò ó! ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ!+ Nítorí náà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ó ha bófin mu láti ṣe ìwòsàn ní sábáàtì bí?” kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án.+ 11  Ó wí fún wọn pé: “Ta ni yóò jẹ́ ẹni náà láàárín yín, tí ó ní àgùntàn kan, bí èyí bá sì já sínú kòtò+ ní sábáàtì, tí kì yóò dì í mú, kí ó sì gbé e jáde?+ 12  Bí a bá gbé gbogbo rẹ̀ yẹ̀ wò, mélòómélòó ni ènìyàn fi ṣeyebíye ju àgùntàn lọ!+ Nítorí náà, ó bófin mu láti ṣe ohun tí ó dára púpọ̀ ní sábáàtì.” 13  Nígbà náà, ó wí fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì nà án, a sì mú un padà bọ̀ sípò ní yíyèkooro bí ọwọ́ kejì.+ 14  Ṣùgbọ́n àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ lòdì sí i, kí wọ́n lè pa á run.+ 15  Bí ó ti wá mọ èyí, Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tẹ̀ lé e pẹ̀lú, ó sì wo gbogbo wọn sàn,+ 16  ṣùgbọ́n ó fi àìyẹhùn pàṣẹ fún wọn láti má ṣe fi òun hàn kedere;+ 17  kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: 18  “Wò ó! Ìránṣẹ́+ mi tí mo yàn, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n,+ ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà! Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí mi sórí rẹ̀,+ ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ni yóò sì mú ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè. 19  Kì yóò ṣàríyànjiyàn aláriwo,+ tàbí kí ó ké sókè, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà fífẹ̀. 20  Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí yóò tẹ̀ fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí yóò fẹ́ pa,+ títí yóò fi rán ìdájọ́ òdodo+ jáde pẹ̀lú àṣeyọrí sí rere. 21  Ní tòótọ́, nínú orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ní ìrètí.”+ 22  Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tí ẹ̀mí èṣù ti sọ di òǹdè, tí ó fọ́jú, tí ó sì yadi, wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì wò ó sàn, tí ó fi jẹ́ pé ọkùnrin odi náà sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23  Tóò, ó ká gbogbo ogunlọ́gọ̀ náà lára gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé:+ “Ó ha lè jẹ́ pé Ọmọkùnrin Dáfídì náà kọ́ ni èyí?”+ 24  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn Farisí wí pé: “Àwé yìí kò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde bí kò ṣe nípasẹ̀ Béélísébúbù, olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”+ 25  Ní mímọ ìrònú wọn,+ ó wí fún wọn pé: “Gbogbo ìjọba tí ó bá pínyà sí ara rẹ̀ a máa wá sí ìsọdahoro,+ gbogbo ìlú ńlá tàbí ilé tí ó bá sì pínyà sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26  Ní ọ̀nà kan náà, bí Sátánì bá ń lé Sátánì jáde, ó ti pínyà sí ara rẹ̀; báwo wá ni ìjọba rẹ̀ yóò ṣe dúró? 27  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí mó bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípasẹ̀ Béélísébúbù,+ ta ni àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde? Ìdí nìyí tí wọn yóò fi jẹ́ onídàájọ́ yín. 28  Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ni mo fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín lójijì ní ti tòótọ́.+ 29  Tàbí báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbógun ti ilé ọkùnrin alágbára, kí ó sì fi ipá gba àwọn ẹrù rẹ̀ tí ó ṣeé gbé, láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà? Lẹ́yìn náà, yóò sì piyẹ́ ilé rẹ̀.+ 30  Ẹni tí kò bá sí ní ìhà ọ̀dọ̀ mi lòdì sí mi, ẹni tí kò bá sì kó jọ pẹ̀lú mi ń tú ká.+ 31  “Ní tìtorí èyí, mo wí fún yín pé, Gbogbo onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a óò dárí ji àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí ni a kì yóò dárí jini.+ 32  Fún àpẹẹrẹ, ẹnì yòówù tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ kan lòdì sí Ọmọ ènìyàn, a óò dárí rẹ̀ jì í;+ ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá sọ̀rọ̀ lòdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í, bẹ́ẹ̀ kọ́, kì í ṣe nínú ètò àwọn nǹkan yìí tàbí nínú èyí tí ń bọ̀.+ 33  “Yálà kí ẹ sọ igi di àtàtà, kí èso rẹ̀ sì di àtàtà tàbí kí ẹ sọ igi di jíjẹrà kí èso rẹ̀ sì di jíjẹrà; nítorí nípasẹ̀ èso rẹ̀ ni a fi ń mọ igi.+ 34  Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀,+ báwo ni ẹ ṣe lè sọ àwọn ohun rere, nígbà tí ẹ jẹ́ ẹni burúkú?+ Nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.+ 35  Ènìyàn rere láti inú ìṣúra rere rẹ̀ ń mú àwọn ohun rere jáde,+ nígbà tí ó jẹ́ pé ènìyàn burúkú láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀ ń mú àwọn ohun burúkú jáde.+ 36  Mo sọ fún yín pé gbogbo àsọjáde aláìlérè tí àwọn ènìyàn ń sọ, ni wọn yóò jíhìn+ nípa rẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́; 37  nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni a ó polongo rẹ ní olódodo, nípa àwọn ọ̀rọ̀ rẹ sì ni a óò dá ọ lẹ́bi.”+ 38  Nígbà náà, ní ìdáhùn fún un, àwọn kan lára àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí wí pé: “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí àmì kan láti ọ̀dọ̀ rẹ.”+ 39  Ní ìfèsìpadà, ó wí fún wọn pé: “Ìran burúkú àti panṣágà+ tẹra mọ́ wíwá àmì, ṣùgbọ́n a kì yóò fi àmì kankan fún un àyàfi àmì Jónà wòlíì.+ 40  Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí Jónà+ ti wà ní ikùn ẹja mùmùrara náà fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ènìyàn+ yóò wà ní àárín ilẹ̀ ayé+ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.+ 41  Àwọn ènìyàn Nínéfè yóò dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí,+ wọn yóò sì dá a lẹ́bi;+ nítorí pé wọ́n ronú pìwà dà lórí ohun tí Jónà+ wàásù, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju Jónà lọ wà níhìn-ín. 42  A óò gbé ọbabìnrin gúúsù+ dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí pé ó wá láti àwọn òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.+ 43  “Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ kan bá jáde kúrò nínú ẹnì kan, a kọjá gba àwọn ibi gbígbẹ hán-ún hán-ún ní wíwá ibi ìsinmi káàkiri, kò sì rí ìkankan.+ 44  Nígbà náà ni a wí pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò padà lọ sí ilé mi láti inú èyí tí mo ti ṣí kúrò’; nígbà tí ó sì dé, ó rí i pé ó wà lófo, ṣùgbọ́n tí a gbá a mọ́, tí a sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́. 45  Nígbà náà ni ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì mú ẹ̀mí méje mìíràn dání pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ,+ àti pé, lẹ́yìn wíwọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀; àwọn ipò ẹni yẹn ní ìgbẹ̀yìn sì wá burú ju ti ìṣáájú.+ Bẹ́ẹ̀ ni yóò rí pẹ̀lú fún ìran burúkú yìí.”+ 46  Nígbà tí ó ṣì ń bá àwọn ogunlọ́gọ̀ náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ìyá àti àwọn arákùnrin+ rẹ̀ dúró ní ibi kan lóde, wọ́n ń wá ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀. 47  Nítorí náà, ẹnì kan wí fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọ́n ń wá ọ̀nà láti bá ọ sọ̀rọ̀.” 48  Ní dídáhùn, ó wí fún ẹni tí ń sọ fún un pé: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?”+ 49  Àti ní nína ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé: “Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+ 50  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun kan náà ni arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá mi.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé